ÌGBÀGBỌ́ TO NDÀGBÀ
ÌGBÀGBỌ́ TO NDÀGBÀ lati ọwọ́ ọ ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI ÌGBÀGBỌ́ TÓ NDÀGBÀ - ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI (c) Ògúndáre Olúsẹ́gun Olúfẹ́mi (2011) Instagram: www.instagram.com/segundare111 Twitter: twitter.com/segundare111 Email: segundare111@gmail.com Cellular: +2348025301717 ISBN: ÌKÌLỌ̀ PÀTÀKÌ Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ se àtúntẹ̀ tabi da ohunkohun kọ ninu iwe yi yàtọ̀ fun ìlò arã rẹ nikan tabi fun sise iwadi láìgba àsẹ lati se bẹ́ẹ̀ lati ọ̀dọ̀ onkọwe. Ofin yi ko yọ ẹnikẹni silẹ, yala latari sise iwé ọlọ́rọ̀-geere yi i lori itage, lori ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì, lori fíìmù, ẹrọ amóhùn-maworan tabi intanẹti. Ikilọ pataki ni o, o si ti dòfin. Ilé Isẹ́ to tẹ iwe yi jade ni: ÌBÀ Mo sèbà Oluwa Ọlọrun Eledumare Ẹnito ran Ọmọ Rẹ Kansoso, Jesu Kristi wâ sinu aiye lati wá fi ara rẹ se ètùtù fun ẹsẹ gbogbo aiye, nipa Rẹ ni ìgbàgbọ́ se de ọdọ awa keferi...lati le jẹ́ àjùmọ̀jogún ìjọba Ọlọrun. ÌMỌ RÍRÌ Mo dupẹ pupọ lọwọ awọn obi mi nipa ti ara, Alagba ati ologbe Diakoni obinrin, Ogundare Ayodele,...