Orin Kan: Ohun To Sowọn Lati Se
( “Nitori o s ọwọn ki ẹnikan ki o to ku fun Olododo: sugbọn fun enia rere boya ẹlomiran tilẹ le daba ati ku” (Romu 5:7)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Mura ẹbẹ ọkan mi Jesu nfẹ gb’ adura rẹ O ti pe k’o gbadura Nitorina yio gbọ Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Ọlọrun fifẹ rẹ han ‘Fẹ to ga ju lo fihan ‘Gbato ran ‘mọ re waiye Lati wa ku f’ẹsẹ wa 2. O sọwọn ki a to ri Ẹnit’ yo gba lati ku Fun olododo enia Ti o mbẹ ni awujọ 3. Sugbọn fun ẹni rere Boya a le r’ẹnikan Ti yo daba lati fi Ẹmi rẹ lele f’oun 4. ‘Gbata ko le rẹnikan Lati ku f’olododo Tab’ ẹni rere aiye Melomelo awa ẹlẹsẹ 5. Nin’eyi ni ati ri Ifẹ ailẹ