Posts

Showing posts from December, 2020

Orin Kan: Ìfẹ To Gaju

Image
( “Ni ij ọ keji Johannu ri Jesu mbọ wa sọdọ rẹ; o si wipe, wo o ọdọ agutan Ọlọrun, ẹniti o ko ẹsẹ aiye lọ! ” (Jhn 1:29)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Boruk ọ Jesu ti dun to Ogo ni fun orukọ rẹ O tan banujẹ at’ọgbẹ Ogo ni fun orukọ rẹ Ègbè Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ Ogo f’orukọ Oluwa Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ Ogo f’orukọ Oluwa Ẹniti o Kọrin Yi:   Orin Titun na Nìyí 1. Ìfẹ to ga julọ laiye lọrun Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia Ọmọ bibi kansoso t’Ọlọrun Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia Ègbè Ọmọ Ọlọrun, Ọmọ Ọlọrun Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun Ọmọ Ọlọrun, Ọmọ Ọlọrun Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun   2. Ẹbun ọfẹ to ga ju laiye lọrun Ni Jesu t’Ọlọrun f’enia Ọmọ kan soso lok

Orin Kan: Ẹbùn Ọlọrun To Ga Julọ

Image
( “Yio si bi ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pe orukọ rẹ: nitori on ni yio gba awọn enia rẹ la kuro ninu ẹsẹ wọn” (Matteu 1:21)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Ẹ jẹ ka finu didun Yin Oluwa Olore Anu rẹ o wa titi Lododo dajudaju Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Ẹbun Ọlọrun faraiye Jẹ ‘fẹ rẹ to ga julọ To fi ‘han npa fifun wa Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso   2. Ọlọrun nifẹ araiye O si fun wa lẹbun nla To fi ‘han npa fifun wa Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso   3. Ohunt’eniyan ko le fun ni L’Ọlọrun fi f’eniyan ni To fi ‘han npa fifun wa Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso   4. Ọfẹ lo fun wa lẹbun yi Ẹbun aiyeraiye ni To fi ‘han npa fifun wa Ni Jesu ‘mọ Rẹ kansoso

Orin Kan: Lasiko Ìyàn O Wà Pẹlu Rẹ

Image
( “Iw ọ ma bẹru: nitori mo wa pẹlu rẹ; ma foya; nitori emi ni Ọlọrun rẹ: Emi o fun Ọ ni okun: nitotọ, emi o ran ọ lọwọ: nitotọ emi o fi ọwọ ọtun ododo mi gbe ọ soke”  (Isaiah 41:10)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Mase foya ohunkohun Ọlọrun y’O tọ ọ Ma gbe ibi ikọkọ Rẹ Ọlọrun y’O tọ ọ Ègbè Ọlọrun y’O tọ ọ Lojojum ọ l’ọna gbogbo On y’O ma tọju rẹ Ọlọrun y’O tọ ọ Ẹniti o Kọrin Yi:  Civilla D. Martin (1904) Orin Titun na Nìyí 1. ‘Gbati o wa ninu ‘soro Jesu wa pẹlu rẹ Tiwọ ko le s’ohun to fẹ Jesu wa pẹlu rẹ Ègbè Jesu wa pẹlu rẹ Nikorita y’owu ko jẹ Iwọ mase bẹru Jesu wa pẹlu rẹ   2. ‘Gbati ‘wọ wa ninu ide Jesu wa pẹlu rẹ Tile aiye yi si su ẹ Jesu wa pẹlu rẹ Ègbè   3. ‘Gbati ọta npọn ẹ loju Jesu wa

Orin Kan: Ẹ Ma Gba Nkan Wọnyi Ro

Image
( “Li akotan, ara, ohunkohun ti ise ot ọ, ohunkohun ti ise ọwọ, ohunkohun ti ise titọ, ohunkohun ti ise mimọ, ohunkohun ti ise fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi iwa titọ kan ba wa, bi iyin kan ba si wa, ẹ ma gba nkan wọnyi ro” (Fil. 4:8)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Ìgbagbọ mi duro l’ori Ẹ jẹ at’ododo Jesu, Nko jẹ gbẹkẹle ohun kan Lẹhin orukọ nla Jesu Ègbè Mo duro le Kristi Apata Ilẹ miran, iyanrin ni” Ẹniti o Kọrin Yi: Edward Mote (1834) Orin Titun na Nìyí 1. Ohunkohun ti ‘se otọ Ohunkohun ti ‘se ọwọ Ohunkohun ti ‘se titọ At’ohungbogbo ti ‘se mimọ Ègbè Ẹ ma gba ‘wọn nkan wọnyi ro Ẹnyin ara mi n’nu Oluwa   2. B’ohunkohun ba jẹ fifẹ At’oh

Orin Kan: Nwọn Nsun Fun Ibanujẹ

Image
( “Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si t ọ awọn ọmọ ẹhin rẹ wa, o ba wọn, nwọn nsun fun ibanujẹ” (Luku 22:45)) Rotimi and Ronke Ogundare Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Mo fẹran iwe ọrọ rẹ O f’imọlẹ at’ayọ fun Ọkan okun on ‘banujẹ! Ọrọ rẹ t’ọna mi wiwọ Ẹru rẹ ko jẹki nsirin ‘Leri rẹ m’ọkan mi sinmi ” Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. ‘Gbati ‘banujẹ b’ọkan mi Temi kosi nireti mọ Temi ko si le gbadura Ti emi nsun fun ‘banujẹ Ọrọ rẹ lo jẹ ‘reti mi ‘Gbati gbogbo ‘reti mi pin   2. ‘Gbati nko jamọ ohun kan Nigbati a kọ mi silẹ Ti mo di ‘tanu lawujọ Tamu ‘le aiye yi sumi Iwọ Jesu ninu ifẹ Fi ọwọ rẹ fami mọra   3. ‘Gbat’ ẹni ti mo f

Orin Kan: Ẹniti a Bukunfun

Image
( “Ìbukun ni fun ọkọnrin na ti ko rin ni imọ awọn eniyan buburu, ti ko duro li ọna awọn ẹlẹsẹ, ati ti ko si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgan” (Orin Daf. 1:1)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “ Ko tọ kawọn mimọ bẹru Ki nwọn sọ ‘reti nu ‘Gba wọn ko ‘reti ‘ranwọ rẹ Olugbala yio de ” Ẹniti o Kọrin Yi: William Cowper Orin Titun na Nìyí 1. Oluwa fun wa lọrọ rẹ Ki awa le ma pa mọ Ki awa ba le mọ fẹ rẹ Ki awa ma ba segbe   2. Bi a se le d’ẹni ‘bukun Wa ninu ọrọ rẹ Ohun to yẹ kawa ko se ni Ka ma fiye sọrọ rẹ   3. B’aba fẹ di ẹni ‘bukun Nipasẹ ọrọ rẹ A ko ni lati ma rin papọ Ninu imọ ‘wọn ẹni ‘bi             4. Lati le di ẹni ‘bukun A o gbọdọ duro lọna