Posts

Showing posts from November, 2020

Orin Kan: Sọtẹlẹ Ni Ìgbàgbọ

Image
( “O tun wi fun mi pe, s ọtẹlẹsori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ ọrọ Oluwa”  (Esek. 37:4)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “ Ọrẹ bi Jesu ko si laye yi Oun nikan l’ọrẹ otitọ Ọrẹ aye yi y’o fiwa silẹ Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe wa Ègbè Ah! Ko jẹ gbagbe wa/2x Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe wa ” Orin Titun na Nìyí 1. Ọwọ Oluwa wa lara Esekiel’ O mu jade ninu ẹmi Rẹ Lọ s’arin afonifoji to kun Fun orisirisi egungung Ègbè ‘Gungun wọnyi yo ye/2x Bo ba s’ọtẹlẹ s’ wọn ni ‘gbagbọ   2. Oluwa mu ko sir in yi  wọn ka Oun si ri pe wọn gbẹ pupọ Oluwa bi lere bi wọn le ye O dahun p’Oluwa lo le mọ Ègbè   3. Oluwa wi pe ki o sọtẹlẹ S

Orin Kan: Ma Yọ Mi, Iwọ Ọta Mi: Nigbati Mo Ba Subu, Emi O Dide

Image
( “Ma yọ mi, iwọ ọta mi: nigbati mo ba subu, emi o dide; nigbati mob a joko li okunkun, Oluwa yuio jẹ imọlẹ fun mi.” (Mika. 7:8))   Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “ Wa nigbati Kristi npe ọ Wa, ma rin ‘na ẹsẹ mọ Wa tu gbogb’ ohun t’o de ọ Wa bẹrẹ ‘re ‘je tọrun Ègbè O npe ọ, nisiyi Gbọ b’olugbala tin pe O npe ọ, nisiyi Gbọ b’olugbala ti npe ” Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. ‘Gba temi nrin lọ lokunkun An’ afonifoji iku To dab’ ẹnipe imọlẹ K’yo tan mọ fun mi Ègbè Ma yọ mi ‘wọ ọta mi ‘Gba mob a subu ngo dide ‘Gba mo joko lokunkun Oluwa o jẹ ‘mọlẹ mi   2. ‘Gba ti mow a ni aginju Ti ko s’ounjẹ mo le jẹ Ti ko tun somi lati mu Tile aiye

Orin Kan: Ma Gba Ọrẹ Kan Gbọ

Image
( “Ẹ ma gba ọrẹ kan gbọ, ẹma si gbẹkẹle amọna kna: pa ilẹkun ẹnu rẹ mọ fun ẹniti o sun ni okan-aiya rẹ.” (Mika. 7:5))   Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “ ’Yo dahun gbogb’ adura Ileri ati ‘fẹ rẹ Ko sa ti yi pada ri Ogo f’okọ rẹ ” Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Ma se gbẹkẹl’ ẹnikan Ninu aiye ta wa yi T’or’ ọkan enia le Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ   2. Ẹ ma gba ọrẹ kan gbọ Ẹ ma gbẹkẹl’ amọna kan T’or’ ọkan enia jin Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ   3. Pa ‘lẹkun ẹnu rẹ mọ Ko da f’ẹnit’o gbori Rẹ le okan aiya rẹ Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ   4. Mase gb’ ẹnikẹni gbọ ‘Tor’ awọn ọmọkunrin Le sai nani baba wọn Gbẹkẹ l’Oluwa rẹ   5. Lasan ni gbẹkẹle enia ‘Tor’ awọn ọm