Posts

Showing posts from August, 2020

Orin Kan: Bi Ẹnyin Ba Bere Ohunkohun Ni Orukọ Mi, Emi O Se E

Image
( “Bi ẹnyin ba bere ohunkohun ni orukọ mi, emi o se e.” (Joh. 14:14))   Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “’Gbati ipe Oluwa ba dun, t’aye y’o si fo lọ Ti imọlẹ ọjọ titun y’o si de Nigbati awọn ọmọ igbala ba pejọ l’oke T’a ba si p’orukọ nibẹ, un o wa m’bẹ   Ègbè ‘Gbat’a ba p’orukọ lọhun/3x ‘Gbat’a ba p’orukọ lọhun, un o wa mbẹ Ẹniti o Kọrin Yi:   Orin Titun na Nìyí 1. Lotọ ati lododo ni ohun temi nwi fun nyin Isẹ tie mi nse lawọn to gbami yo se Ani ‘sẹ to tobi juyilọ nisẹ ti wọn yo se ‘Tori Emi npada lọ s’ọdọ Baba Ègbè Gbogb’ ohun t’ẹnyin ba bere/3x Gbogb’ ohun t’ẹnyin ba bere lorukọ mi lem’o se   2. Ki a ba le yin baba logo ani ninu Ọmọ Bi ẹnyin ber

Orin Kan: Ìfẹ Lo Tobi Ju

Image
( “Njẹ nisisiyi igbagbọ, ireti ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: sugbọn eyiti o tobi ju ninu wọn ni ifẹ” (1 Kor 13:13))   Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Párádísè, Párádísè Tani ko fẹ ‘sinmi Tani ko fẹ le ayọ na Ile alabukun Ègbè Ni b’awọn olotọ Wa lae ninu ‘mọlẹ Wọn nyọ nigbagbogbo Niwaju Ọlọrun Ẹniti o Kọrin Yi:   Orin Titun na Nìyí 1. Ìfẹ ni o tobi julọ Ninu aye ti a ngbe Torifẹ ki ‘se ilara Ki ‘sọrọ gberaga Ègbè ‘Gbagbọ ‘reti at’ ifẹ ‘Wọn mẹta yi lo wa Sugbọn eyi to tobi ju Ohun na ni ifẹ   2. Ìfẹ ni o tobi julọ Ninu aye ti a ngbe Torifẹ ki huwa aitọ Bẹni ki ifẹ rara Ègbè   3. Ìfẹ ni o tobi julọ Ninu aye ti a ngbe Torifẹ ki wohun

Orin Kan: Ti Ko Ba Si Ìfẹ, Asán Ni

Image
( “Bi mo si ni ẹbùn ìsọtẹlẹ, ti mo si ni oye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo imọ: bi mo si ni gbogbo ìgbàgbọ, tobẹ ti mo le si awọn oke nla nipo, tie mi ko si ni ifẹ, emi ko jẹ nkan” (1 Kor 13:2))   Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:        Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Párádísè, Párádísè Tani ko fẹ ‘sinmi Tani ko fẹ le ayọ na Ile alabukun Ègbè Ni b’awọn olotọ Wa lae ninu ‘mọlẹ Wọn nyọ nigbagbogbo Niwaju Ọlọrun Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Kóda bi o ba jẹ wipe Mo nf’ọniruru ede Ati ti awọn angẹli Temi ko ni ifẹ Ègbè Ohun yow u ti mba ni Ohun yo wu ti mba jẹ Bikoba tis i ifẹ Asan ni gbogbo rẹ   2. Bi emi ko ba ni ifẹ Èdèkédè yio wu Ti emi iba le ma sọ Idẹ l

Orin Kan: Oluwa, O Tó Àkoko fun Ọ Lati Sisẹ

Image
( “Oluwa, o tó àkoko fun Ọ lati sisẹ; nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo” (Psa. 119:126))   Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:        Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Ọkan mi yin Oluwa logo Ọba iyanu t’O wa mi ri Un o l’agogo iyin y’aye ka Un o si t’ifẹ Atobiju mi han Ègbè Oluwa, Ọpẹ ni fun Ọ Fun ore-ọfẹ t’O fi yan mi Jọwọ dimimu titi d’opin Ki nle jọba pẹlu Rẹ loke   Orin Titun na Nìyí 1. Nkan ko rib o ti se yẹ mọ Kaluku ya sipa ọna rẹ ‘Tori a o tete mu idajọ sẹ Ọkan enia gbilẹ ni ibi Ègbè Oluwa o ti to akoko Fun Ọ lati se isẹ ‘Tori ọpọ enia ‘nu aiye Ti wọn ti sọ ofin rẹ d’ofo   2. ‘Gba ‘wọ Oluwa poju rẹ mọ Kuro lara mi ati ‘sẹ mi, Ẹnu awọn ọta mi nyọ mi Wọn mbere ‘bi

Orin Kan: Kò Ni Si Àjàkálẹ Àrùn Níbẹ

Image
( “Ọlọrun yio si nu omije gbogbo nù kúrò li ojú wọn; ki yio si si iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹni ko ni si ìrora mọ; nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ” (Ifi. 21:4))   Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:        Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Ọrẹ bi Jesu ko si laye yi Oun nikan l'ọrẹ otitọ Ọrẹ aye yi le ko wa silẹ Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe wa Ègbè Ah! Ko je gbagbe wa/ 2ce Sugbon Jesu ko je gbagbe wa Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Mo r’itẹ funfun nla kan L’or’ eyi t’ẹnikan jokole Niwaju rẹ aye on ọrun fo lọ A ko sir i aye fun wọn mọ Ègbè A o n’omije wa nu/2x Oruk’ awa to wa n’nu ‘we ‘ye   2. Mo r’awọn oku t’ewe t’agba Ti wọn duro niwaju itẹ Lati gba ‘dajọ gbogb’ ohun w

Orin Kan: Ọrẹ Mi Ni Ẹnyin Jẹ

Image
( “Ọrẹ mi ni ẹnyin jẹ, bi ẹ ba se ohun ti emi palasẹ fun nyin” (Joh. 15:14))   Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:        Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Mo ti ni Jesu lọrẹ O j'ohun gbogbo fun mi Oun nikan larẹwa ti ọkan mi fẹ Oun nitanna ipado Oun ni Ẹnikan naa To le wẹ mi nu kuro nin'ẹsẹ mi Olutunu mi lo jẹ ni gbogbo wahala Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori Oun n'Itanna Ipado Irawọ Owurọ Oun nikan l'Arẹwa ti ọkan mi fẹ Ègbè Olutunu mi lo jẹ ni gbogbo wahala Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori Oun n'Itanna Ipado Irawọ Owurọ Oun nikan l'Arẹwa ti ọkan mi fẹ” Ẹniti o Kọrin Yi: William Charles Fry May 30, 1838- August 24, 1882 Orin Titun na Nìyí 1. ‘Sinyi

Orin Kan: Ìrètí Sì Wà Fun Ẹ

Image
  ( “Nitoripe àbá wà fun igi, bi a bá ke lulẹ, pe yio si tún sọ ati pe ẹka rẹ titun, ki yio da” (Job. 14:7)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:        Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Ọkan aarẹ ile kan mbẹ L’ọna jinjin s’aiye ẹsẹ Ile t’ayida ko le de, Tani ko fẹ sinmi nibẹ Ègbè Duro, rọju duro, mase kun/2x Duro, Duro (sa) rọju duro mase kun”   Orin Titun na Nìyí 1. Ẹ ma jẹ k’ọkan yin daru Ẹnyin tẹ gba Ọlọrun gbọ Ti gbagbọ nyin wa n‘nu Kristi ‘Tor’ O ni ‘pinnu rere fun nyin Ègbè Ireti si wa fun ọ, ọrẹ/2x Ireti wa, ireti wa fun ọ ọrẹ   2. Ma se sọkun mọ ‘wọ ọrẹ Nu omije oju rẹ kuro ‘Tori isẹ rẹ ni ere Eyi l’ohun t’Olugbala sọ Ègbè   3. Fun ‘wọ ẹnit’ a kọ silẹ T’ọpọ enia

Orin Kan: Wò Mi Sàn, Oluwa

Image
  ( “Wò mi san, Oluwa, emi o si san! Gbamila, emi o si la, nitori iwọ ni iyin mi” (Jer. 17:14)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:        Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.   Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Jesu ọkan na ni titi Bi o ti wa nigbani Lasan li ọrun apadi Ndojukọ agbara rẹ L’ọkan awọn eniyan rẹ O njọba titi d’oni Tirẹ ni gbogbo agbara O nfa ide ẹsẹ ja” Ẹniti o Kọrin Yi: Orin Titun na Nìyí 1. Wo mi san, emi o si san Gbamila emi yio la ‘Tori ‘wọ nikansoso ni Ọna ‘ye at’ otitọ Mo ke pe Ọ ‘wọ Oluwa mi Nin’ aisan at’ ailera mi F’ọwọ iwosan rẹ kan mi Botise f’ana Simon’   2. Wo mi san, emi o si san Gbamila emi yio la Nitori aisedede wa Ni a se pa Ọ lara Bẹni ‘na Alafia wa Si wa ni ara rẹ Ati nip