ÌGBÀGBỌ́ TO NDÀGBÀ

ÌGBÀGBỌ́ TO NDÀGBÀ 

lati ọwọ́ ọ 

ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI





ÌGBÀGBỌ́ TÓ NDÀGBÀ

- ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI

(c) Ògúndáre Olúsẹ́gun Olúfẹ́mi (2011)

Instagram: www.instagram.com/segundare111

Twitter: twitter.com/segundare111

Email: segundare111@gmail.com

Cellular: +2348025301717

ISBN:

ÌKÌLỌ̀ PÀTÀKÌ

Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ se àtúntẹ̀ tabi da ohunkohun kọ ninu iwe yi yàtọ̀ fun ìlò arã rẹ nikan tabi fun sise iwadi láìgba àsẹ lati se bẹ́ẹ̀ lati ọ̀dọ̀ onkọwe.

Ofin yi ko yọ ẹnikẹni silẹ, yala latari sise iwé ọlọ́rọ̀-geere yi i lori itage, lori ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì, lori fíìmù, ẹrọ amóhùn-maworan tabi intanẹti. Ikilọ pataki ni o, o si ti dòfin.

Ilé Isẹ́ to tẹ iwe yi jade ni:

ÌBÀ

Mo sèbà Oluwa Ọlọrun Eledumare Ẹnito ran Ọmọ Rẹ Kansoso, Jesu Kristi wâ sinu aiye lati wá fi ara rẹ se ètùtù fun ẹsẹ gbogbo aiye, nipa Rẹ ni ìgbàgbọ́ se de ọdọ awa keferi...lati le jẹ́ àjùmọ̀jogún ìjọba Ọlọrun.

ÌMỌ RÍRÌ

Mo dupẹ pupọ lọwọ awọn obi mi nipa ti ara, Alagba ati ologbe Diakoni obinrin, Ogundare Ayodele, fun atilẹhin wọn nigbagbogbo.

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun olukọ mi nipa ti ẹmi, Ologbe Olusọagutan Adegunlẹ E. S, fun amọran wọn, adura wọn nigbati wọn fi wa ninu ara ati Mama Adegunlẹ E.

Awọn aburo mi: Kemi, Pamilerin, Tola, Rotimi ati IfeOluwa.

Awọn omo mi ninu ẹmi: Julius Ohiare (ọmọ ko le jọ baba ki a ma binu rẹ), Fatoyinbo Taiwo, Solomoni Idowu (ẹniti a ro wipe o ti kù sugbọn to tun sọjí pada), Kayode S. Sẹgun, Onisegun Eyibo ati Aya re, (Dr. & Mrs.) Ofakunrin Gbenga, Iyafin Maria Fasogbon, Olusegun Odedokun.

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun awọn enia wọnyi: Dr. Gbemi-Henry, Amofin (Barrister) Ojelade Kayode, Dr. (PhD) Ajao Seyi, Dr. Adeleke Elisa (PhD), Gboyega Oke, Ogunrinde Ariyo, Peleyeju Kunle, Tokunbo Akinbuwa, Ejide Isaaki, Adegunle Ayo, Ologbe Peteru Adetimole, Ogunleye Supọ, Ibiwoye Oluwaferanmi, Adeyemo Adeyink (Amerika), Adeyemi Anjorin (Canada), Olushola Fagbemi, Emmanuel Adaramoye.

Gbogbo awọn ti aye kùnà funmi lati kọ orukọ wọn sinnu iwe yi ni mo mọ riri wọn, Ọlọrun yio jẹ ki a ma ri ohun rere ba ara wa se lorukọ Jesu. Amin.

Fun gbogbo ẹyin ti ẹ nra iwe wa, lati igbati a ti nkọ iwe pelebe-pélébé ti a npe ni "ÌMỌ́LẸ̀ ÒTÍTỌ́" jade ti ẹ si tun nfunmi ni ìwúrí ati atilẹhin lati tun kọ iwe nla bi iru eleyi jade, mo dupẹ lọwọ yin o. Owó kò ní tan lọwọ yin. Ohun rere ni a o si ma ri ba ara wa se lorukọ Jesu. Amin...atipe nikẹhin, a o jọ de ijọba ọrun ni lorukọ Jesu. Amin. Ẹ se o...

Ọ̀RỌ̀ ÀSỌSÍWÁJÚ

O rọrùn fun awa onigbagbọ lode oni lati ma kọrin tabi sọ wipe, "ibukun Abrahamu na jẹ tiwa..." sugbọn lati la irufẹ ohun ti Abrahamu la kọja ninu Ọlọrun nitori igbagbọ to ni ko rọrun. Iru igbagbọ ti baba igbagbọ Abrahamu ni na ni a npe ni igbagbọ to ndagba si i (II Kọr 10:15).

Ìgbàgbọ to ndagba kì íse ohun to nwa lọjọkan bikose ohun ti yio la oniruru nkan kọjá, sugbọn sibẹ ti kò ni yingin, bùkù, díkù tabi lọ sẹhin bikosepe ki o mã pọ̀ sí i.

Iru igbagbọ yi ni Ọlọrun pè wá si gẹgẹ bi ọmọ Rẹ ati ọmọlẹhin Rẹ.

Bi iwọ nã se nka iwe yi, mo gbadura wipe Ọlọrun yio sọ ẹ di alabukunfun lọpọlọpọ nipa ọrọ inu iwe yi ni orukọ Jesu Kristi Oluwa. Amin.

-Sẹgun.

ÌTỌKA

-Ojú ewé akọ́lé

-Ìbà

-Ìdúpẹ́

-Àsọsíwájú

-Ìtọka

-Ọrọ nipa ìwé yi

-Ori Kinni

-Ori Keji

-Ori Kẹta

-Ori Kẹrin

-Ori Karun

-Ori Kẹfa

-Ori Keje

Ọ̀RỌ̀ LÉRÈFÉ NIPA IWE YI

Abrahamu jẹ apẹrẹ ati baba igbagbọ nitoriti o gba Ọlọrun gbọ bi o tilẹ jẹ wipe awọn ohun to nri, awọn ohun to nsẹlẹ̀ si lasiko na kò sí ni ìbámu pẹlu awọn ohun ti Ọlọrun mbã sọ (Gen. 15:6; Rm 4:3).

Ìgbẹ́kẹ̀lé àìyingin ninu ọrọ Ọlọrun yi ni Baba igbagbọ ti n dàgbà titi ti igbagbọ na fi gbilẹ̀ gidigidi tobẹ to di eleyi to kari ilé, to si kari oko gẹgẹbi o ti se hàn loni yi.

Ninu iwe yi ni iwọ nã yio ti ri ohun ti igbagbọ to ndagba jẹ eleyi ti yio si ran ọ lọwọ lati sún mọ́ Ọlọrun sí i....

Yio dara ki o ra iwe yi fun ẹlomiran pẹlu ki o ba le jẹ adun ọrọ ihinrere Kristi Jesu nã.

-Ajinhinrere Stefanu Julius.

07038202875

ORÍ KINNI


IGBÀGBỌ́ GẸGẸBI IDANILOJU

II Tessalonika 1:3

"Isẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ nitoripe igbagbọ nyin NDÀGBÀ gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ".

I) KINI IGBAGBỌ?

Igbagbọ jẹ igbẹ́kẹ̀le to le (tabi to lagbara) ninu nkankan tabi eniyan kan. Eleyi ni itumọ ti iwe to ntumọ ede ni gẹsi (dictionary) fun igbagbọ.

Itumọ ti bibeli fun igbagbọ ni a rí ninu iwe Heberu ori kokanla ẹsẹ kinni ti o wipe,

"Njẹ igbagbọ ni ÌDÁNILÓJÚ ohun ti a nreti, ÌJẸRI ohun ti a ko rí".

À wa oluka bibeli yio ri wipe ọrọ ti o wa ni ori kokanla yi ni àjùmọ̀jọsepọ pẹlu ọrọ ti o wa ni ori kẹwa.... Ẹ jẹ ki a wo itumọ ti bibeli fun igbagbọ yi kínní-kínní.

1. ÌDÁNILÓJÚ: 

Bibeli kọkọ wipe, igbagbọ jẹ ÌDANILÓJÚ Ohun ti a nreti. Ẹ jẹ ki nsalaye ọrọ yi.

Nigbati woli Elija nipasẹ ọrọ Ọlọrun pe idajọ wa sori Israeli niti wipe ọrun sé, ti òjò ko si rọ fun ọdun mẹta ati osu mẹfa, a ri wipe lẹhin ọdun wọnyi, o tun lọ farahan ọba Ahabu, ti o si se idajọ fun awọn woli Baali nipa pipa wọn run, lẹhin eleyi, o wa ngbadura ki òjò le rọ....

Bi woli Elija se ngbadura lori oke bẹ na lo nran ọmọ rẹ lo í wo awọsanma lọna ìhà okun, ọmọ na lọ nigba akọkọ́ sugbọn ko ri nkankan, bayi lo se lọ nigba mẹfa láì ri nkankan, mo woye wipe yio ti sú ọmọ isẹ woli Elija na, sugbon nitoripe ọga rẹ ni, yio ma fi ara da nitoripe o nkọsẹ woli ni. Sùgbọn nigbati o di ẹlẹkeje ti ọmọ na jade lọ lati lọ wo awọsanma na, ọmọ na wipe oun ri awọsanmọ kekere kan to dide lati inu okun gẹgẹbi ọwọ́ eniyan.... 

Ni asiko yi òjò kò ì tí ì sú, sugbọn, gẹgẹ bi aladura ti o ni igbagbọ, ohun ti ọmọ na ri na fihan wipe òjò yio rọ̀, ohun ti ọmọ ọdọ Woli Elija na ri jẹ idaniloju wipe ìró ọpọlọpọ òjò mbọ lori ilẹ (I A. Ọba 18).

Nigbati Noa fi nkan ọkọ̀, ti o si nwasu wipe òjò mbọ wa rọ lati pa aiye rẹ, ko si ẹnito gbagbọ nitoripe ojo kò rọ rí, sugbọn ẹniti oun, Noa, mba lò ntọ́ ọ sọna, titọ sọna ti o nri nipa ti ẹmi yi ni ìdániloju wipe ohun na yio sẹlẹ. (II Pet. 2:5; Lk. 17)

Tamárì fẹ ọmọ Juda, sugbọn nigbati aburo ọkọ rẹ to sú u lopo kú, Juda kò fẹ fi abigbẹhin rẹ fun Tamari mọ, nitoripe o rò wipe olori pọkọjẹ-pọkọjẹ ni, nitorina, ó da ọgbọn sí i. Sugbọn nigbati o jẹ wipe obinrin na jẹ ẹnito npa ara rẹ mọ, obinrin na jẹ ẹnito bẹru Olorun ati ilana ati àsà ilẹ wọn, kò ba ara rẹ jẹ, o nduro de asiko ti baba ọkọ rẹ yio ransẹ pe oun ki oun wa fẹ àbígbẹ̀hìn ọmọ oun, nitori ọrọ àjọsọ to ti wà larin wọn. 

Sugbọn baba rẹ ko se eleyi. Ọpọlọpọ wa na ni a kì í le tẹle ọrọ àjọsọ, a kì í lè é duro ti ọrọ wa. Orin Dafidi 15:4d wipe 

"ẹniti o bura si ibi ara rẹ̀ ti ko si yipada".

Awọn kan nigbati wọn ba sọrọ ti wọn ba ti ri wipe ọrọ wọn na ma ni ipalara fun wọn wọn ko ni le duro ti ọrọ na mọ, wọn a yẹhùn, wọn a yi ohun pada. 

Iru eleyi na lo sẹlẹ si Juda nihinyi, nitoripe nigbati o woye wipe o dabi ẹni wipe Tamari ko fẹ mu ori ọkọ waiye, nigbati o ro wipe ègún mba Tamari jà, eleyi to nmu ikú àìtọjọ wa fun awọn ọmọ oun, o nfi ọgbọn-ọgbọn sa fun Tamari, o ngbe ọmọ rẹ sa, se wọn ni ọgbọn-ọgbọn ni agbalagba fi nsa fun malu, eleyi na ni Juda nse, o ndabo bo ọmọ rẹ, kò rò wipe ẹ̀bi le wa lọwọ awọn ọmọ oun, o ti ro wipe awọn ọmọ oun mọ wipe Tamari ni alaimọ, ẹlẹgbin to nfi tirẹ ko ba awọn ọmọ oun. 

Bi baba ọkọ Tamari, to njẹ Juda se nlo arekereke fun Tamari, bẹna ni Tamari nfi arekereke ba baba ọkọ rẹ lo nigbato ti mọ wipe ohun to nse niyi. Ọrọ awon mejeji wa dabi owe awọn agba to wipe, àáyá gbọn, Ogungbe nã gbọ́n, bi àáyá ba ntiro, Ogungbe na a si mã bẹrẹ. Iru ayò ti awọn mejeji nta fun ara wọn ni eleyi. 

Sugbọn nigbatose, Juda bọ si ọwọ Tamari, o si ba Tamari lo pọ. Sugbọn ki wọn o to pari ibalopọ wọn, Tamari si wi fun Juda wipe ko fun oun ni nkan ti awon enia yio fi mọ wipe oun ni. Juda si fun ni awọn nkankan. 

"O si wipe, emi o ran ọmọ ewurẹ kan si ọ lati inu agbo wá. Oun si wipe iwọ ki o fi ògo fun mi titi iwọ o fi ran-an wa? 

"O si bi i pe, ògo kinni emi o fi fun ọ? Oun si wipe, edidi rẹ, ati okùn rẹ, ati ọpa re ti o wa ni ọwọ rẹ; o si fi wọn fun un, o si wọle tọ̀ ọ lọ, oun si ti ipa ọdọ rẹ loyun" (Gen. 38:17-18). 

Bi Tamari se gba edidi, okùn ati ọpà to wa lọwọ Juda niyi fun ami. Ami yi ni idaniloju fun Tamari, ati fun Juda nipa isẹlẹ na. Lehin eleyi, Tamari loyun, sugbọn ohun to wa lọwọ rẹ fun ami na ni lati fihan awon eniyan wipe ẹni toni awon nkan wonyi ni oun ni oyun fun, ati wipe eni na yio wa gba ọmọ rẹ. Awon ami na nfihan wipe oun, Tamari ko se pansaga. (Gen 38) 

Ni nkan bi ọdun mẹdọgbọn sẹhin, arakọnrin kan ti ilu eyibo wa lati wa fẹ iyawo ni Ilọrin, o se igbeyawo na, ó dùn o si larin-rin, lẹhin igbeyawo yi, ọkunrin na pada si ilu eyibo lai mu iyawo rẹ dani, o si wipe oun yio pada wa mú u.... Obinrin na duro titi de ọkọ rẹ ko si ní ẹlomiran nitoripe o ti se igbeyawo pẹlu ọkunrin yi, ó ní oruka igbeyawo, iwe ẹri igbeyawo eleyi ti wọn gba nile ijọsin wa lọwọ obinrin na nitorina, o nfi se ami wipe oun ti lọkọ ati wipe ọkọ oun mbọ wa mu oun….

Nigbati Jesu na n mura ati pada lọ si ọdọ Baba rẹ, o se ileri Ẹmi Mimọ fun wa,

"Sugbọn otitọ ni emi nsọ fun nyin; anfani ni yio jẹ fun yin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu ki yio tọ yin wa; sugbọn bi mo ba lọ, emi o ran-an si yin" (Jhn 16:7). 

Ileri Ẹmi Mimọ yi fi arahan nigbati awọn aposteli fi wa ni yara oke. (I Apo. 2) Lati igbana ni Ẹmi Mimọ ti nfi ara han laiye awa onigbagbọ titi di asiko yi. 

Nipase Ẹmi Mimọ yi ni awa na se le jẹri wipe Jesu mbọ lati wa ko awa ayanfẹ lọ, nitoripe ami to fi fun wa farahan.... 

Lati inu awọn apẹrẹ diẹ wọnyi, ni a ti ri itumọ ohun to njẹ idaniloju ohun ti a nreti, idaniloju ohun ti a nfọkan si, idaniloju wipe ohun ti a nwọna fun na yio si farahan. Eleyi ntumọ si wipe, ohun ti a nreti ko i ti fi ara han, nitoripe a ò le mã reti ohun ti o ti farahan.... 

Ki oro yi ba le ye wa si, a mọ wipe ọmọ ile iwe to se idanwo yio ni awọn ohun ìdánimọ wipe oun se idanwo na dani, nipa ìdánimọ yi ni yio fi le wo esi idanwo na nigbati o ba ya, nigbati esi idanwo na ba jade... Sugbọn ẹniti ko ni idanimọ yi ko le sọ wipe oun se idanwo na, nitorina iru enia bẹ ko le sọ wipe oun nduro de èsì (idanwo) kankan...

Ẹniti kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkunrin tabi obinrin kankan ri ko le sọ wipe oun nreti ati loyun tabi wipe oun yio bimọ, ki a ma tilẹ wa wipe iru ẹni na yio ma bẹru wipe boya oun le ko àrùn ko gbogun kankan eleyi to le ti ipasẹ ìbálòpọ waiye. 

Nigbati woli to wá lati Juda (ẹniti ọpọ ma npe ni woli Kekere) nsọrọ lori ohun ti yio sẹlẹ si Samaria fun ọba Jeroboamu ninu iwe Awọn Ọba kinni ori kẹtala, a ó ri wipe ó fi ami han, o fi apẹrẹ han, eleyi to fi sọ fun gbogbo eniyan wipe ohun ti oun nsọ na ko ni se alaisẹ dandan. 

Ẹnito farahan Manoa ati iyawo rẹ lati sọ fun wọn wipe wọn yio bi ọmọkunrin kan niwoyi amọdun na fi ami han awọn tọkọ-taya na lati fi dawọnloju wipe ohun ti oun nsọ na yio sẹ (Onidajọ 13). 

Angẹli Gabrieli to farahan fun Sekariah na fi ami idaniloju kalẹ, eleyi to sọ fun awọn lọkọ-laya na, ani Sekariah ati Elisabeti wipe, Ọlọrun ti bojú wo wọn, ati wipe Ọlọrun ti ranti wọn. Lẹhin eleyi ni tọkọ-taya na mọ ara wọn, ti Elisabeti si fi inu soyun. Ọrọ ti angẹli na sọ tosi farahan laiye Sekariah ọkọ Elisabẹti. (Luku 1) 

Lati inu awọn apẹrẹ wọnyi ni a ti ri wipe, Idaniloju jẹ àmì tí eniyan ma nri, amì to ma nfarahan wipe ohun ti a nreti na, tabi ohun ti Olọrun báwa sọ nã yio sẹ dandan. 

Ohun ti Ọlọrun sọ nã le è pẹ, sugbọn ohun to daju ni wipe yio sẹ dandan, yio wa si ifarahan ni àkókò o rẹ gege bi a ti ri ninu awọn apẹrẹ ati awọn akọsilẹ oke wonyi.

"Nitori iran na jẹ ti igba kan ti a yàn, sugbọn nigbẹhin yio sọrọ, ki yio si sèké; bi o tilẹ̀ pẹ, duro dè é, nitori ni dide yio de, ki yio pẹ" (Hab. 2:3). 

Awọn kan ma npe iru nkan bayi ni majẹmu, a jẹ́ wipe àmì yi jẹ majẹmu to wà larin eniyan ati eniyan tabi larin eniyan ati awọn ẹmi kan, yálà ẹmi Olọrun ni tabi awọn ẹmi esu. 

Ọlọrun ni irú majemu yi pelu enia nipasẹ Noa nigbati o wipe, Oun, Ọlọrun, ko ni fi omi pa aiyẹ rẹ mọ, ti o si fi osumare silẹ loju ọrun.

"Emi o si ba nyin da majẹmu mi; a ki yio si fi kikun-omi gé gbogbo ẹda kuro mọ́; bẹni kikun-omi ki yio si mọ, lati pa aiye run.

"Ọlọrun si wipe, eyiyi ni àmì majẹmu mi ti mo na nyin da, ati gbogbo ẹdá alãyè ti o wà pẹlu yin, fun atirandiran: 

"Mo fi osumare mi si awọsanma, oun ni yio si ma se àmì majẹmu mi ti mo ba aiye dá. 

"Yio si se, nigbati mo ba mu awọsanma wá si ori ilẹ, a o si ma ri òsùmàrè nã ni awọsanma: 

"Emi o si ranti majẹmu mi, ti o wà lãrin emi ati ẹyin, ati gbogbo ọkan alãye ni gbogbo ẹda; omi ki yio si di kikun mọ lati pa gbogbo ẹda run. 

"Osumare nã yio si wa ni awọsanma; emi o si ma wò ó, ki emi le ma ranti majẹmu laelae ti o wa pẹlu Ọlọrun ati gbogbo ọkàn alãye ti o wa, ninu gbogbo ẹda ti o wa ni aiye. 

"Ọlọrun si wi fun Noa pe, eyiyi ni àmi majẹmu na ti mo ba ara mi ati ẹda gbogbo ti o wà lori ilẹ dá." (Gen. 9:11-17) 

Ami osumare yi nsapẹrẹ nkan wọnyi: 

1. Wipe Ọlọrun si ma pa aiye rẹ, sugbọn nkan miran ni yio lo lati fi pa aiye rẹ, 

2. Wipe Oun, Ọlọrun, ko ni lo omi lati fi pa aiye rẹ mọ, 

3. Wipe ó sese ki enia tun mu Ọlọrun binu, ki ibinu rẹ si fàru lati fẹ pa aiye rẹ, sugbon yio ranti majẹmu rẹ nigbato ba ri osumare na, ti yio fi fa ọwọ rẹ sẹhin lati ma fi omi pa aiye rẹ mọ, 

4. Wipe Ọlọrun ba eniyan ati ara rẹ da majẹmu. 

Lati inu ọrọ oke yi, ni a ti ri wipe, Ọlọrun ko ni se alaipa aiye ati ohun gbogbo to wa ninu rẹ rẹ lojọ iwaju. 

"Oluwa ko fi ileri rẹ jafara, bi awọn ẹlomiran í ti ka ijafara; sugbọn o nmu suru fun yin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o segbe, bikose ki gbogbo eniyan ki o wa si ironupiwada. 

"Sugbọn ọjọ Oluwa mbọ̀wá bi ole ni oru; ninu eyiti awọn ọrun yio kọja lọ ti awọn ti ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yio si ti inu oru gbigbona gidigidi di yiyọ, aiye ati awọn isẹ ti o wà ninu rẹ yio si jóná lúlú.

"Njẹ bi gbogbo nkan wọnyi yio ti yọ́ ni, irú u eniyan wo ni ẹyin ìbá jẹ́ ninu iwa mimọ gbogbo ati iwa-bi-Olọrun, 

"Ki ẹ si ma reti, ki ẹ si mã mura giri de dide ọjọ Ọlọrun, nitori eyiti awọn ọrun yio gbina, ti wọn yio di yíyọ́, ti awọn imọlẹ rẹ̀ yio si ti inu ooru gbigbona gidigidi di yiyọ?" (II Pet. 3:9-12) 

Ninu iwe Ifihan 21:1 Bibeli wipe, 

"Mo si ri ọrun titun kan ati aiye titun kan: nitoripe ọrun ti isaju ati aiye isaju ti kọja lọ; okun ko si si mọ". 

Awọn ọrọ wọnyi nsọ fun wa wipe aiye ati ọrun isinsinyi ni Ọlọrun yio si parẹ, nitorina Ọlọrun nfẹ ki gbogbo eniyan ko kuro labẹ iparun to mbọ yi ki wọn o si di titun ninu ero wọn, eleyi ni wipe Ọlọrun nfẹ ki gbogbo eniyan o di ẹni igbala ki enia o ba le bọ labẹ wahala to mbọ na, gẹgẹ bi Noa ati gbogbo awọn to wa ninu ọkọ tise bọ nigbati ìkún omi de nigba aiye tiwọn.

"Ti ko si dá aiye igbãni si, sugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwa-bi-Ọlọrun" (II Pet. 3:5) 

Ni aiye isinsinyi, majẹmu titun ti Ọlọrun ba eniyan da lo wa nipasẹ Jesu nitori a ti kọ ọ́ ninu bibeli wipe, 

"Nitori eyi ni ẹjẹ̀ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọpọ eniyan fun imukuro ẹsẹ̀" (Mt. 26:28) 

Ẹ̀jẹ̀ Jesu ni Ọlọrun fi ba eniyan wọ inu majẹmu titun. Bi o tilẹ jẹ wipe majẹmu ti Ọlọrun ba gbogbo iran eniyan da lati ipasẹ woli Noa duro, sibẹ, Ọlọrun tun wa se eto majẹmu titun pẹlu ẹnikọkan wa. Majẹmu yi ni enia

Majẹmu yi ni eniyan le ri gbà lati ipasẹ Jesu Kristi ani lati ipasẹ gbigba Jesu Kristi gbọ sinu aiye eniyan gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala eniyan. Njẹ o ha ti gba Jesu gbọ bi ki o ba le bọ lọwọ iparun to mbọ? Njẹ o ha ti gba Jesu gbọ bi, ki o ba le wọ inu majẹmu didara ati majẹmu aiyeraiye lọ pelu re? 

Gẹgẹ bi Ọlọrun tise ba aiye da majẹmu ti o si fi ami osumare kalẹ, bẹna ni Ọlọrun tun mba awọn ti o ba gba Jesu gbọ da majẹmu loni nipa Jesu Kristi ọmọ rẹ. Ẹjẹ Jesu Kristi yi ni Ọlọrun fi silẹ gẹgẹ bi ami majẹmu to ba awọn eniyan tirẹ da ninu aiye nisinsinyi. Eleyi ni wipe, nigbakugba ti Ọlọrun ba ti ri ẹjẹ Jesu, yio ranti majẹmu igbala rẹ pẹlu awọn ti wọn gba A gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala wọn. Bi esu ba si nfẹ se wọn ni ibi kan tabi omiran, bi idamu kan tabi omiran ba nfẹ wa si oju ọna wọn, riri ti Ọlọrun ba ti ri ẹjẹ na, riri ti satani ba ti ri ẹjẹ̀ na, ibi ati wahala na ni iru eniyan bẹ yio ni isẹgun le lori. 

"Wọn si sẹgun rẹ̀ nitori ẹjẹ̀ Ọdọ́-Agutan nã, ati nitori ọrọ̀ ẹri wọn, wọn ko si fẹran ẹmi wọn ani titi de iku" (Ifi. 12:11). 

Mo rò wipe itumọ yi ye wa diẹ? Lati inu ọrọ oke yi, mo le wipe igbagbọ jẹ majẹmu ti Ọlọrun ba wa da nipa ẹmí lati mã fihan wa wipe ohun ti Oun bá wa sọ wọnni yio wa si ìmúsẹ, o le pẹ o, sugbọn ohun to daju ni wipe yio wa si imuse. Ẹlomiran yio wipe, Ọlọrun ko ba oun sọrọ ri, nitorina, Oun ko si ninu majẹmu kankan pẹlu Ọlọrun. Gẹgẹ bi a ti sọ loke yi wipe, nipasẹ ẹmi ni Ọlorun fi ba wa da majẹmu na, nitorina, nipasẹ ẹmi na ni Ọlọrun yio fi ba wa sọrọ. Nipasẹ ẹmi ni a fi mba Ọlọrun rin, nitoripe a ò ri Ọlọrun soju ri. Nipasẹ ẹmi na ni a fi n ni igbala. Nipasẹ ẹmi kanna ni a fi n ni igbagbọ. 

BAWO NI ỌLỌRUN TISE MBA ENIYAN SỌRỌ? 

Ohun to daju ni wipe, awọn kan wa ti wọn ri ore-ọfẹ to tayọ gbà lati ọdọ Ọlọrun lati ma gbọ nkan ijinlẹ, lati ma ri nkan ijinlẹ ju awọn miran lọ, sugbọn, sibẹ, ohun to daju miran na tun ni wipe ko si ẹni to wa ninu aiye ti Ọlọrun fi silẹ lai ma ba sọrọ. Ohun to wa nibẹ wa ni wipe, ọpọ awa eniyan ni a kì í fiyesi awọn ọna wọnyi, tabi ki n wipe, awa eniyan la ma nro wipe awọn ọna na ti Ọlọrun ngba bawa sọrọ na kere, wipe oni lati tun ni ọna miran ti Ọlọrun yio ma gba ba won sọrọ ju eleyi lọ. 



Diẹ lara awọn ọna na ti Ọlọrun ma ngba ba eniyan sọrọ niwonyi: 

1. Nipa àlá: 

"O si wipe, ẹ gbọ ọrọ mi nisinsinyi: bi woli Oluwa ba mbẹ ninu nyin, emi Oluwa yio farahan fun-un ni ojuran, emi o si ba sọrọ ni oju-ala" (Num 12:6) 

Àlá jẹ ohun to ma nsẹlẹ lẹhin igbati eniyan ba ti sùn ti eniyan si ti di ojú rẹ mejeji.

Àlá a mã waiye nigbati eniyan ba di ojú rẹ tó sùn, lasiko yi ni eniyan mã nri oniruru nkan. Irúfẹ àlá ti mo nsọ wipe Ọlọrun ma fi mba eniyan sọrọ yi ma nyàtọ̀ si àwọn àlá gbogbo ti eniyan ti nlá tẹ́lẹ̀ ri, nitoripe àlá na ma nduro lori sónsó ọkàn eniyan, àlá na yio mã da ọkan eniyan lamu lati wá ìtumọ̀ sí i bi eniyan kò ba mọ itumọ rẹ. Tí óbá si jẹ eleyi ti eniyan mọ itumọ rẹ ni, yio wà lọkan eniyan ti eniyan yio ma ronú lori rẹ gidigidi. Nipa ríronú lori rẹ yi lo ma nmú ki eniyan sọ fun ẹlomiran tabi ẹnikeji rẹ tabi awọn eniti ohun ti eniyan ri nã kàn lati gbọ. 

ORISUN AWỌN ÀLÁ: 

Orisun mẹta pàtàkì ni àlá lílá ni gẹgẹbi a ti ri ka ninu bibeli. 

1) ỌLỌRUN: Nigbati Ọlọrun ba fẹ ba eniyan sọro nipa arã rẹ, nipa ẹlomiran, nipa ilu, ijọba orilẹ ede abbl, Ọlọrun le lo àlá lati fi ba ẹni na sọrọ. Irufẹ eleyi sẹlẹ si Josefu, Farao, Nebukadnessari abbl. 

2) ÈSÙ: Èsù pẹlu a mã mu ki awọn eniyan rí ati pẹlu a mã mu ki wọn o mọ ohun ijinlẹ nipa aiye, ijọba inu aiye, ara ẹni, ilu, orilẹ ede abbl. A ò ni gbàgbé wipe satani nã ni agbara, awọn agbara tó ni wọnni ki ise wipe Ọlọrun gbàá kuro lọwọ rẹ nigbati Ọlọrun fi lé e kuro ninu ìgbimọ isejọba rẹ látàrí asemọse rẹ ti Ọlọrun si lé e jù si òde aiye. 

"Lati là wọn ni oju, ki wọn ki o lè yipada kuro ninu okunkun si imọlẹ, ati kuro lọ́wọ́ AGBARA SATANI si Ọlọrun, ki wọn ki o le gba idariji ẹ̀sẹ̀, ati ogun pẹlu awọn ti a sọ di mimọ nipa igbagbọ ninu mi" (I. Apo. 26:18) 

Aposteli Paulu lo nsọrọ nihinyi niwaju Agrippa ọba (I. Apo. 25:26) bi Ọlọrun ti se ba Oun pàdé lójú ọna si Damasku nigbati ó fi ngbógun ti ihinrere Kristi Jesu ati bi Ọlọrun ti se ran oun nisẹ. Lara ọrọ tó ni Jesu ba oun sọ ni lati yi awọn eniyan padà kúrò lọ́wọ́ agbara satani (tabi esu) si agbara Olọrun. Eleyi nfihan wipe satani na si lagbara, sùgbọn agbara rẹ kò tó ti Ọlọrun, agbara rẹ wẹ́ si agbara Ọlọrun. Ọlọrun mọ̀-ọ́-mọ̀ ma gba agbara to fi fun-un kuro lọ́wọ rẹ ni ko ba le fihan satani wipe ohun ti Oun fi fun gẹgẹ bi agbara nigbana tó fi nsògo, tó fi nrò wipe òun jẹ nkan, kò tó ki a tẹ orí ìka eniyan bọ òkun ninu awọn ohun ati agbara ti Oun, Ọlọrun, ni. 

Nitori, mo wòye wipe ìgbéraga wọnu aiye satani lasiko na nitori o nro wipe kínni Ọlọrun tún ni ti Oun kò ni? Satani nro wipe kinni Ọlọrun tun le se ti Oun ko le se? Satani lasiko to fi fẹ dìtẹ̀ gba ìjọba lọwọ Ọlọrun nro wipe Oun ti mọ ọpọ asiri Ọlọrun, nitorina, O ro wipe pẹlu awọn asiri ti Oun ti ni, ati pẹlu awọn agbara ti Oun ti ni, bi oun ba dìtẹ̀ gba ijọba lọwọ Ọlọrun nã kò i tí ì buru jù, eleyi nã lo sì se pẹlu. Sugbọn satani ti gbagbe wipe, kekere ni lagbaja fi jù mí lọ kò se fi ọ̀bẹ bù danu, ati wipe ẹnito junilọ ó le è juni nù. 

Awọn agbara ti Ọlọrun fi fun satani yi, Ọlọrun ko gbã kuro lọwọ rẹ, ọlọrun fi silẹ fun, nigbati Ọlọrun tun wá gba ọ̀nà awamaridi miran jade sí i. Nipa awọn agbara ti Ọlọrun fi fun sugbọn ti Ọlọrun kò gbà kúrò lọwọ rẹ yi ni o fi mã n ni anfani lati mọ nipa ọjọ ọla eniyan tabi ilu, tabi orilẹ ede abbl. Nipasẹ eleyi na lo fi ma nmọ nipa awọn ohun tó ti kọja nã pẹlu.

Gbogbo àwa olùka bibeli ni a ó ranti ọrọ̀ tí a kọ nipa Jobu ninu iwe Jobu lori kinni ati ori keji. A ri wipe bibeli wipe satani farahan niwaji Ọlọrun nigbati awọn ọmọ Ọlọrun pé niwaju Ọlọrun. 

"Njẹ, o di ọjọ kan, nigbati awọn ọmo Ọlọrun wá ípé niwaju Oluwa, satani si wà pẹlu wọn" (Jb 1:6; 2:1) 

Anfani to rí gbà yi lati mã pé niwaju Oluwa lati ipasẹ wipe a ò gba awọn ohun ti a ti fi fun nisaju kuro lọwọ rẹ nã lo fi nri, to si fi nmọ díẹ̀díẹ̀ nipa ọjọ iwaju eniyan, ilu tabi ati orilẹ ede. Lati ipasẹ eleyi na lo si fi mã nfi ẹtan ati arekereke mu eniyan, ilu, orilẹ ede nipa fifi ọgbọ́n arekereke tàn wọ́n ati ki o si fa eniyan si ọdọ arã rẹ. Nipasẹ eleyi ni yio fi pa ara rẹ dà si angẹli imọlẹ niwaju eniyan, ki eniyan o bã le gbãgbọ.

"Ki ise ohun iyanu; nitori satani tikararẹ npa ara rẹ da di angẹli imọlẹ. "Nitorina ki ise ohun nla bi awọn iransẹ rẹ pẹlu ba pa ara wọn da bi awọn iransẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ́ bi ise wọn" (II Kor 11:14-15) 

Nipasẹ ọna yi, àní yiyọju siwaju Oluwa lori ọrọ eniyan, ilu, idile, orilẹ-ede, ẹgbẹ, ajọsepọ, ọrẹ abbl lo fi ma nmọ diẹ nipa ohun ti Ọlọrun ni fun enia, ẹgbẹ, ọrẹ, idile, afẹsọna abbl. Nigbati ó bá si ti mọ eleyi o le fi han fun eniyan nipa àlá lilá. 

Nipasẹ ọna yi kanna lo fi mã nfi eniyan sùn niwaju Ọlọrun nigbagbogbo, gẹgẹ bi o ti se lori ọrọ̀ Jobu. 

"A sì le dragoni nla na jade, ejo laelae ni, ti a npe ni Esu, ati satani, ti ntan gbogbo aiye jẹ: a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ jade pẹlu rẹ. 

"Mo si gbọ ohun rara ni ọrun, wipe, nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati agbara ti Kristi rẹ; nitori a ti le olufisun awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sun niwaju Ọlọrun wa lọsan ati loru" (Ifi 12:9-10) 

Olọrun tó mu ki Johannu olufẹ ati aposteli rẹ ri ohun to sẹlẹ lọrun lọpọ̀lọpọ̀ ọdun sẹhin, ati nipasẹ eleyi ti satani fi ri ejo kó si ninu nitoripe awọn agbara ti Ọlọrun fi fun si wa pẹlu rẹ, nipasẹ eleyi to fi tan awọn baba ati iya nla wa, Adamu ati Efa, ninu ọgba Edeni. Nigbati o si fi ẹtan mu ..mu wọn yi, lo ti bẹrẹ sini ni ipa to buru ati eleyi to lagbara ninu aiye ati lori olugbe inu aiye pẹlu. Nipasẹ eleyi na lo se mu ki eniyan o la àlá lati ri ohunkan tabi ohun miran nipa ara enia, ilu, orilẹ ede, ẹgbẹ abbl. 

3) ARA: Ọ̀nà míràn ti enia tun fi ma nla ala ni nipasẹ ero ara, nipasẹ èrò tó ti gba ọkan enia kan. 

"Nitoripe nipa ọpọlọpọ isẹ ni ala ti nwa" (Onws 5:3) 

Nigbati ọkan enia bá kun fún èrò kan, nigbati ọkan enia ba kun isẹ kan, yálà isẹ na nda enia lamu ni tabi eniyan ngbadun isẹ nã, enia a mã la ala ri iru ohun tabi isẹ ti enia nse na. Ere idi ti eleyi se ma nsẹlẹ kò sẹhìn wipe nigbati iru ero isẹ nã ba ti gba ọkan enia kan, èrò nã yio tilẹkun mọ àjọsepọ to mbẹ larin eniyan ati Ọlọrun nipasẹ eleyi ti Ọlọrun fi le mu ohun ijinlẹ wá. 

Gẹgẹbi ọpọ awa eniyan sì ti mọ wipe, Ọlọrun kì í fi tulasi mu enia se ohunkohun tabi rí ohunkohun, tabi gbọ ohunkohun nitorina, Ọlọrun yio se gafara fun ẹni na lori ọrọ nã, ati ni asiko na, eleyi lo ma nfa ti ọpọlọpọ ero ẹni nã látàrí isẹ tó nse yio fi gbilẹ̀ lọkan ẹni na ti yio si fi ohun na lá àlá.

Ti ẹni na ba jẹ omọ Ọlọrun, eleyi kò túmọ̀ si wipe ẹni na ti pada ninu igbagbọ, bikose wipe nse ni Ọlọrun fi silẹ, o fi aye silẹ fun ki o ri ohun to wa lọkan rẹ ki o ba le mu ki ọkan rẹ o fúyẹ́, ati pe ki ọkãn rẹ o bã tun le wa ni irẹpọ ati isọkan pẹlu Oun ki o ba tun le mã gba ohun ijinlẹ siwaju sí i lati ọdọ Ọlọrun. 

Fun ẹniti ki ise ọmọ Ọlọrun tẹlẹ, ani fun awọn ti a ò mã ti ọwọ́ Ẹmi Mimọ se amọnà fun, nipasẹ ẹran ara na ni wọn fi nla àlá ni ọpọlọpọ igba. 

"Nitori iye awọn ti a nse amọnà fun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun wá, awọn ni ise ọmọ Ọlọrun" (Rm 8:14) 

Nipasẹ awọn ọna mẹta wọnyi ni eniyan ma fi nlá àlá. Ohun to han gbangba ni wipe, nipasẹ àlá ni enia fi ma nmọ̀ ohun ijinlẹ nipa arã rẹ, nipa enia miran, ilu tabi orilẹ ede abbl. Ọ̀nà yí, àlá lílá jẹ ọna to wọpọ ti enia ma ngba mọ nkan nipa ara rẹ, isẹ rẹ, idile rẹ abbl. Ọlọrun mã ngba ọna yi gidigidi, bẹna ni ẹmi esu ati ẹran ara. 

Ere idi niyi ti a se ma ngba ọpọ eniyan niyanju lati ri daju wipe awọn nfi iyè si ala wọn daradara, ati wipe fun awọn ti wọn ti nla ala nigbakan ti wọn kò la ala mọ, a ma nwoye wipe ó lè sese ko jẹ wipe esu nfẹ gbógun ti ẹni na, nitorina yio mu ki ẹni na o ma ma ranti ohun to ba lá ni àlá mọ, gẹgẹ bi ọba Nebukadnessari na kò se ranti ala tó lá mọ (Dan. 2). 

Nì ọna miran esu kò tilẹ ni jẹ́ ki ẹlomiran ó rí ohunkohun rara, yio di oju ẹmi nã, eleyi ti yio mu ki ohun buburu ti esu ati awọn ọmọ-ogun rẹ npete lori ẹni na ó dé ba lojiji.

Fun idi eleyi, iru awọn ti wọn ba nla ala ti wọn ngbagbe tabi fun ẹniti kò la ala kankan mọ rara, irufẹ ẹni nã ti wà ninu ìdè ati igbekun ọta, iru ẹni na nilo adura gidigidi, o si nilo itusilẹ kuro ninu ide ti okunkun fi si. 

Ohun miran nipa àlá ni wipe, gbogbo ẹda eniyan to wa ninu aiye ni Ọlọrun nmu kó jẹ iru anfani ati ore-ọfẹ yi. Fun apẹrẹ, ọba Farao ti Egipti ninu iwe Genesisi 41, Ọlọrun mú u la ala ki o le ri nkan ti yio sẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwaju, ki o ba le mu ileri rẹ sẹ, ki o ba le mu ala ti Josefu la sẹ. Nitori ki Ọlọrun bà á le fi agbara rẹ han ni ilẹ Babiloni, Ọlorun mu ki Nebukadnessari la ala (Danieli 2) sugbọn ó gbàgbé, tobẹ to fi fẹ pa awọn alagbara ati awọn onimó nipa àlá ninu ilẹ Babiloni. 

Sugbọn nitoripe Olorun nfẹ fi titobi rẹ han, o mu ki ọmọ Rẹ Danieli mọ ala na, o si tun fun ni itumọ rẹ. Awọn ọba mejeji wọnyi, a ó ri wipe alaigbagbọ niwọn, sugbọn, sibẹ Ọlọrun bá wọn sọrọ nipasẹ àlá nipa ohun ti ko le se alai sẹlẹ̀. Genesisi 20:3-7. Nihinyi ni a ti ri wipe Abimeleki ọba Gerari la ala niti ọran Sara aya Abrahamu tó gbà, ti o si mu aya Abrahamu pada fun. 

ẸNITI YIO LA ÀLÁ TI ỌLỌRUN 

Irufẹ ẹniti yio mã la ala ti Ọlọrun yio jẹ ẹnito ti fi aye rẹ fun Jesu patapata, yio jẹ ẹnito ti kọ ẹsẹ̀ rẹ silẹ tó si ntẹle Jesu lẹhin, 

Iru ẹniyi na ni ẹniti a sọ wipe, Ẹmi Mimọ Ọlọrun yio mã gbe inu rẹ, ẹni nã ni Ẹmi Ọlọrun yio ma se amọna rẹ tọ̀sán tòru

"Nitori iye awọn ti a nse amọna fun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun wa, awọn ni ise ọmọ Ọlọrun" (Rm 8:14) 

Iru ẹni yi yio jẹ ẹnito npa ọrọ Ọlọrun mọ lókan aiya rẹ tọsan-toru, ninu okunkun, ninu imọlẹ, ọrọ Ọlọrun yio jẹ ẹni na lógún

"Ọrọ rẹ ni mo pamọ ni ọkan mi, ki emi ki o ma ba sẹ̀ si ọ" (Ps 119:11) (ẹ tun ka 2 A. Ọba 3:3-5; Mt 1:19-20) 

Iru ẹniyi yio jẹ ẹnito fi ara rẹ fun adura gbígbà, 

"Ẹ má a gbadura ni aisinmi" (I Tess 5:17) 

Iru ẹniyi yio mã gba awẹ na pẹlu 

"Sugbọn iru eyi kì í jáde lọ (tabi iru eyi ki i sẹlẹ) bikose nipa adura ati awẹ" (Mt 17:21)

Nipasẹ awẹ, ọkan, ara, ẹ̀jẹ̀ ati omi ara enia a ma wá si itẹriba, nipasẹ eleyi ti ọkan na yio fi so pọ̀ mọ awọn ohun ti ọrun, nigbati eleyi bá sẹlẹ ati ri ohun ijinlẹ ọrun nipa ọjọ́ iwaju ẹni, nipa awọn asiko tó ti kọja, nipa ohun to nsẹlẹ lọwọlọwọ kò ní soro fun ẹni na. 


OHUN TI KÌ Í MU KI ENIA FIYESI ALÁ TO LÁ 

- Nigbati enia ba ti nlá oniruru alá sugbọn to dabi ẹnipe kò nitumọ si eniyan, enia ko ni fiyesi ala nã, 

- Nigbati enia ba nla ala, eleyi to dabi ẹnipe enia mọ itumọ rẹ, sugbọn to jẹ wipe awọn ala na kò wá si imusẹ, 

- Ti enia ba nla alá sugbọn tó jẹ wipe nse lo ndaru mọ enia lori, eleyi le ..eleyi lè mú kị enia sé ọkãn rẹ le tíkò si ni fẹ fiyesi awọn àlá miran mọ, 

Ọ̀NÀ LATI MỌ ÀLÁ TO LAPẸRẸ/LAGBÁRA:

Nigbati ó bá pẹ́ ti èniyan ti nla àlá sugbọn to ndabi ẹni wipe awọn ala wọnyi kò ni itumọ si eniyan, tabi kó wa si ìmúsẹ, enia le mã rò ó lọ́pọ̀ igba wipe nse ló dabi ẹnipe ẹran ara lo mba òun sọrọ tabi wipe lati ipasẹ ẹran ara ni oun fi nla awọn ala wọnni. Sugbọn awọn ala kan wa eleyi ti ki ise ẹran ara tabi esu lo mu ala wọnyi wa, bikose lati ọdọ Ọlọrun funra Rẹ.

Irú awọn ala wọnyi, ma nyatọ pátápátá si awọn oniruru ala ti enia ti ma nla saju asiko nã, ere idi ni wipe nigbati enia ba la àlá na tán ti enia bá si jí saiye, awọn nkan ti mo kọ sisalẹ wọnyi ma nsẹlẹ si eniyan: 

(1) Ọkàn enia kò ní ní ìsinmi, ọkan enia yio dàrú tabi kó yọ̀ yàtọ̀ lori ala na ti ó lá 

"O si se ni òwúrọ̀, ti ọkan rẹ kò lélẹ̀; o si ransẹ, o si pe gbogbo awọn amoye Egipti, ati gbogbo awọm ọmọran ibẹ̀ wa: Farao si rọ́ àlá rẹ fun wọn sugbọn kò si ẹnikan ti o le tumọ́ wọn fun Farao" (Gen 41:8) 

Iwe Genesisi 40:5-6 tun wipe,

"Awọn mejeji si lá ala kan, olukuluku la àlá tirẹ̀ ni oru kanna, olukuluku bi itumọ ala tirẹ, agbọti ati alase ọba Egipti, ti a dè sinu tubú na. 

"Josẹfu si wọle tọ̀ wọn lọ ni owurọ, o si wò wọn, si kiyesi i, wọn fajuro". 

Àlá yi yio wà lọkan ẹni na tobẹ ti ọkan ẹni na yio wúwo, ẹni na yio si fẹ mọ itumọ ala nã. 

(2) Kinikan yio ma sọ fun ẹni na nínú u rẹ̀ lọhun wipe àlá yi yàtọ̀ si gbogbo eleyi tó ti nla to npatì 

(3) Eniyan yio ranti ala nã yégéyégé 

"Nigbati Josefu dide ninu orun rẹ, o se bi angẹli Oluwa ti wi fun un, o si mu aya rẹ si ọdọ̀" (Mt. 1:24) 

Gbogbo oluka bibeli lo mọ nipa itan ti a kọ sihinyi, Maria to jẹ afẹsọna Josefu ni Josefu ri wipe o loyun, nigbato jẹ wipe ko i ti ba lò pọ̀ rí, ati gẹgẹ bi eleyi ti jẹ ohun ti ko ba ilana awọn Júù mu, Josefu wa fẹ kọ Maria silẹ, Josẹfu nwipe oun kò fẹ jẹ ajẹku, njẹ bi o ti nro eleyi, angẹli fi arahan loju ala lati sọ fun wipe ko ma se gbe igbesẹ to fẹ gbe ati wipe Maria kò ba ara rẹ jẹ́, nitorina, bi o ti lajú si aiye, o ranti àlá na, o si pada lọ ba aya afẹsọna rẹ, Maria, o si mu sọdọ, o fi se aya. (ẹ tun ka Mt 2:13,19) 

(4) Eniyan le è ma ranti ala na, gẹgẹ bi ti Nebukadnessari, sugbọn nitoripe àlá na jẹ eleyi to lapẹrẹ, nitoripe àlá na jẹ eleyi ti Ọlọrun nfẹ ki enia ó mọ̀ nkan nipa rẹ, ọkan enia yio wúwo, ọkan enia kò ni balẹ lori ala nã. 

"Ati ni ọdun keji ijọba Nebukadnessari, Nebukadnessari la àlá nipa eyiti ọkan rẹ kò fi lélẹ̀ ninu rẹ̀, ti oorun rẹ si dá loju rẹ. 

"Nigbana ni ọba pasẹ pe, ki a pe awọn alalupayida ati aworawọ, ati awọn oso ati awọn Kaldea wa, lati fi ala ọba na han fun un. Bẹni wọn si duro niwaju ọba. 

"Ọba si wi fun un pe, mo la ala kan, ọkàn mi kò si le lile lati mọ ala na" (Dan. 2:1-3)

Àlá le è wa lẹmeji 

"Nitorina ni ala na se papọ ni meji fun Farao; nitoripe lati ọdọ Ọlọrun ni a ti fi idi ọràn na mulẹ, Ọlọrun yio si mú u sẹ kankan" (Gen 41:32)

Lati ipasẹ awọn ọna wọnyi ni eniyan yio ti se mọ wipe ala ti oun la yi ki ise ojú lasán, ala to lapẹrẹ ni, ala to nise pẹlu oun ni tabi ẹnito súnmọ́ oun tabi eleyi to nise pẹlu ọjọ iwaju oun. Nitorina, Ọlọrun npe akiyesi ẹni na si ohun nã, Ọlọrun nfẹ ki ẹni na o fi ohun na sọkan gidigidi ki ẹni na sile ranti nigbati awọn nkan na ba nwa si imusẹ wipe Oun ti bá a sọ nkan na saju asiko na.

ÀWỌN OHUN TI ENIYAN YIO FI MỌ ALA TI ỌLỌRUN YÀTỌ̀ SI TI ESU TABI ẸRAN-ARA

Ala ti Olọrun ma nyatọ sí tí esu tabi sí ti ẹran-ara niti wipe, 

(1) Yio wà ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun

"Eyi ni ẹ o fi mọ Ẹmi Ọlọrun: gbogbo ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wa ninu ara, ti Ọlọrun ni: 

"Gbogbo ẹ̀mí ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ki ise ti Ọlọrun; eyi si ni ẹ̀mí Asodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ pe o mbọ, ati nisinsinyi o si ti de sinu aiye" (I Jhn 4:2-3)

(2) Yio fi ogo Olorun han 

"Oun o ma yin mi logo: nitoriti yio gba ninu ti emi, yio ma sọ ọ fun yin" (Jhn 16:4) 

(3) Yio fi ẹtan ati arekereke satani han 

"Ti esu baba yin ni ẹyin ise, ifẹkufẹ baba yin ni ẹ si nfẹ se. Apaniyan ni oun ise lati atetekọse, ko si duro ni otitọ; nitoriti ko si otitọ ninu rẹ. Nigbati o ba nseke, ninu ohun tirẹ ni o nsọ, nitori eke ni ati baba eke" (Jhn 8:44)  

(4) Yio sọ nipa ti Ọlọrun, nitoripe Oun lo ni aiye ati ohun gbogbo to mbẹ bibu rẹ 

"Ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkun rẹ; aiye ati awọn ti o tẹdo sinu rẹ" (Ps. 24:1)  

(5) Yio dójúti ẹran-ara, nitoripe ohun to lòdì si ti Ẹmi ni ẹran ara ma nse nigbagbogbo  

"Njẹ mo ni, ẹ mã rìn nipa ti Ẹmi, ẹnyin ki yio si mu ifẹkufẹ ti ara sẹ  "Nitori ara nse ifẹkufẹ lodi si Ẹmi, Ẹmi lodi si ara: awọn wọnyi si lodi si ara wọn; ki ẹ ma ba le se ohun ti ẹnyin nfẹ" (Gal 5:16-17) 

(6) Yio fi otitọ han, nitoripe Otitọ ni Ọlọrun 

"Sugbọn nitori ti emi sọ otitọ fun nyin, ẹ kò si gbami gbọ́" (Jhn 8:45) 

"Sugbọn nigbati Oun, ani Ẹmi Otitọ ni ba de, yio tọ yin si ọna otitọ gbogbo; nitori ki yio sọ ti ara rẹ; sugbọn ohunkohun ti o ba gbọ Oun ni yio ma sọ; yio si sọ ohun ti mbọ fun nyin" (Jhn 16:13)  

"Jesu wi fun un pe, Emi ni ọna ati iye: ko si ẹnikẹni ti o le wa sọdọ̀ Baba, bikose nipasẹ mi" (Jhn 14:6)

Àlá ti eniyan lá ti eniyan ri wipe oun njalè; alá ti eniyan la ti eniyan ri wipe oun nparọ́ lẹhin eleyi ni ẹni na wa ri wipe oun dé ipò giga; àlá ti eniyan la ti eniyan ri wipe oun kọ iyawo oun silẹ ti oun sì lọ fẹ ẹlomiran loju ala na...iru awọn ala wọnyi kò sọ nipa ti Ọlọrun, o nsọ nipa ti esu, ere idi niyi ti eniyan se nilati ma kiyesi ohun to ba lá daradara, ere idi niyi ti eniyan se nilati kún fún ìmọ̀ Ọrọ Ọlọrun, ki enia ba le mọ ìyàtọ̀ larin ohun tabi ala ti ise ti Ọlọrun ati awọn eleyi tó wa lati ọdọ satani tabi awọn to ti ipa ẹran ara wa.

Ọ̀NÀ LATI MỌ ALA TI ỌLỌRUN

"Olufẹ, ẹ mase gba gbogbo ẹmi gbọ sugbọn ẹ dán awọn ẹmi wò bi wọn ba se ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ ti jade lọ sinu aiye" (I Jhn 4:1)

Latinu awọn ohun diẹ ti mo kọ soke ti enia le è fi mọ ala ti Ọlọrun yàtọ si awọn ala yoku wọnyi na ni ati ri wipe lẹhin igbati enia ba la ala wọnyi tan tósì ránti ala nã, nse ni enia nilati dan ala na wo ki o ba le mọ boya ti Ọlọrun ni tabi ki ise ti Ọlọrun.

Ere idi niyi ti ó se se pataki fun enia lati ni ìmọ̀ nipa ti ỌRỌ ỌLỌRUN daradara.

Nigbato jẹ wipe gbogbo enia inu aiye ni Ọlọrun ma nti ipasẹ ala ba sọrọ, ohun to se koko ni fun iwọ oluka iwe yi ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun lati mojuto irufẹ ẹbun yi. Ohun ti yio dara ni ki o mase gba ẹsẹ laye ki o sunmọ́ Ọlọrun gírígírí ki o ba le ma ti ipasẹ rẹ ba ẹ sọrọ daradara, ati pẹlu wipe kí o ba le mọ ala to jẹ ti Ọlọrun yatọ si awọn yoku nigbati o bá lã tan.

(II) ÌRAN: Iran tun ni ọna miran ti Ọlọrun ma ngba ba enia sọrọ.

Ìran rírí a ma waiye nigbati enia kò sùn, eleyi ni wipe kò jẹ dandan ki enia di ojú rẹ kótó di wipe o riran, nse lo ma ndabi ìgbà ti a pa enia lójú dà, tabi bi igbati a gbe ẹrọ amóhunmáwòrán siwaju eniyan ti eniyan si nworan ohun to nsẹlẹ̀.

ORÍSI ÌRAN TÓ WÀ

Orisi meji ni iran to wa, awọn na ni: iran ti a sí tabi ìran ti a padé.

IRAN TI A SÍ (OPEN VISION): Eleyi a ma waye nigbati eniyan ba laju silẹ kedere ti o si nri awọn nkan to nsẹlẹ ninu ẹmi tabi awọn ohun ti kò ni se alai sẹlẹ̀ laipẹ tabi lọkọ iwaju, tabi awọn ohun to ti sẹlẹ kọja.

Ẹnito ba niru ẹbun yi, nigbati ó bá wà larin ọja tabi nibiti èrò bá pọ̀ si, a le sí i loju lati ri oniruru nkan to nsẹlẹ.

Irúfẹ eleyi lo sẹlẹ ninu iwe woli Daniẹli ori karun nibiti ọba Belsassari ti nse ase nla fun awọn ẹgbẹrun ijoye rẹ to si wa bẹrẹ sini lo ohun elo ti Oluwa nidi orisa rẹ. Inu bi Ọlọrun gidigidi tobẹ to fi ran ìka kan jade lati kọwe sara ogiri wipe ọba na ti gun igi rékọja ewe

"Ni wakati kanna ni awọn ika ọwọ eniyan kan jade wa, a si kọwe sara ẹfun ogiri niwaju ọpa fitila ni ààfin ọba: ọba si ri ọwọ́ ti o kọwe na" (Dan 5:5)

Irufẹ iran sisi yi na ni alagba Stefanu ri nigbati o mba awọn ọmọ Israeli sọrọ Ọlọrun ninu iwe Ise A. Apo 7.

"Sugbọn oun (Stefanu) kún fun Ẹmi Mimọ, o tẹjumọ ọrun, o si ri ogo Ọlọrun, ati Jesu nduro ni ọwọ́ ọtun Ọlọrun.

"O si wipe, wò ó, mo ri ọrun si silẹ, ati ọmọ èniyan nduro ni ọwọ́ ọtun Ọlọrun" (I. Apo 7:55-56)

IRAN TI PADÉ (CLOSED VISION):

Eleyi a ma waiye nigbati a bá pa eniyan loju dé fẹ́ẹ́rẹ́, eleyi ni wipe ki ise wipe enia sùn, sugbọn bi enia ti joko tabi duro ti enia nsọrọ tabi ti enia ngbọrọ lọ, a ó si dédé pa ẹni na lojudé lati ri awon nkan ijinlẹ.

"Ni ijọ keji bi wọn ti nlọ ni ọna ajo wọn, ti wọn si súnmọ́ ilu na, Peteru gun oke ile lọ gbadura niwọn wakati kẹfa ọjọ:

"Ebi si paá gidigidi, oun iba si jẹun; sugbọn nigbati wọn npese, ó bọ́ si ojuran:

"O si ri ọrun si, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin rẹ sọkalẹ si ilẹ" (I. Apo 10:9-11)




III) OHÙN GBÍGBỌ́: Eleyi ni gbígbọ wipe ẹnikan mba enia sọrọ gẹgẹ bi igbati enia kan ati ẹlomiran tise jọ nsọrọ lójúkoju. Ohun gbigbọ yi na le wáyé nigbati enia ba sùn ti enia si nlala tabi nigbati enia ko sun.

Ohun to sa daju ni wipe, ẹniti a mba sọrọ yi yio gbọ (ohun) ọrọ na ni etí rẹ ketekete ọrọ ti ẹni na yio gbọ ni eleyi ti ẹnito mba sọro yio sọ sí i ni ede to gbọ, bi a bá lo ede ti ẹni na ko gbọ, olutumọ̀ yio ti wà nitosi lati tumọ ọrọ na fun ẹni na.

Saulu ni a rí kà ninu iwe mimọ wipe o nse inunibini si ihinrere, sise inunibini yi lo ngbe lọ si Damasku nigbati Ọlọrun pade rẹ ti Ọlọrun si bá a sọrọ.

"O si se, bi o ti nlọ, o si sunmọ Damasku: lojiji lati ọrun wá, imọlẹ si mọlẹ yí i ka:

"Ó sì subu lulẹ, ó gbọ ohun ti o nfọ̀ sí i pe, Saulu, Saulu, èése ti iwọ fi nse inunibini si mi" (I. Apó 9:3-4)

A o ri wipe Saulu gbọ ọrọ yi si eti rẹ ketekete ni.

O le se ninu iran tabi ninu ala ni eniyan yio ti gbọ ohùn yi.

"Ọkunrin kan si wà ni Kesarea ti a npe ni Kọrneliu balogun ọrun ti ẹgbẹ ọmọ-ogun ti a npe ni ti Itali.

"Niwọn wakati kẹsan ọjọ, o ri ninu iran kedere angẹli Ọlọrun kan wọle tọ̀ ọ́ wa, o si wi fun pe Korniliu,

"Nigbati o si tẹjumọ ọ, ti ẹru si bàá, ó ní, kinni Oluwa? O si wi fun pe, adura rẹ, ati ọrẹ-ãnu rẹ ti goke lọ iwaju Ọlọrun fun iranti" (I. Apo 10:134)

Awọn amoye ti wọn lọ ki Jesu ni Ọlọrun kilọ fun loju ala wipe ki wọn o mase pada si ọdọ Herọdu ọba mọ, nitorina wọn gba ọna miran pada si ibiti wọn ti wa.

"Bi Ọlọrun ti kilọ fun wọn ni oju ala pe, ki wọn ki o mase pada tọ Herodu lọ mọ, wọn gba ọna miran lọ si ilu wọn" (Mt. 2:12):)

(IV) OHÙN TI ẸMI: Eyi ma nsẹlẹ nigbati ẹmi Ọlọrun to mbẹ ninu wa ba mba ẹmi wa ati ọkan wa sọrọ wipe ohun kan dara tabi wipe ohun kan jẹ otitọ tabi irọ́. Nipasẹ ohùn ti ẹmi yi ni ọpọ eniyan fi ma n ni igbala. Nipasẹ irú ohun yi ni ọpọ eniyan fi ma nmọ̀ wipe nkankan je ẹsẹ ati wipe kò dara. Nipasẹ iru ohùn ẹmi yi ni awọn baba nla wa fi gbé inu aiye, ti wọn si fi nse ìyàtọ̀ larin rere ati buburu.

"Ẹmi tikararẹ ni o mba ẹmi wa jẹri pe, ọmọ Ọlọrun ni awa nse" (Rm 8:16)

Ọpọlọpọ awọn woli ati awọn iranse Ọlọrun lo ma nlo iru ẹbun yi lati fi sọrọ fun awọn eniyan.

(V) NIPA IWÉ MIMỌ KÍKÀ: Nigbati enia ba nka iwe mimo, eleyi ti ise ọrọ Ọlọrun, Ọlọrun a ma ba enia sọrọ latinu ọrọ na wa nigbati ọrọ na ba fi ọwọ́ tọ́ ọkan eniyan gidigidi. Nigbati woli Danieli nka ọrọ Ọlọrun ti a ti ẹnu woli Jeremiah kọ silẹ, ni ọrọ na fi ọwọ́ kàn-án tósì pinnu lati bẹrẹ sini ba Ọlọrun sọrọ lori awọn enia rẹ to wa ni igbekun pe ki Ọlọrun ma se woran mọ. (Dan 9:2)

Ìwé ofin ti awọn ọmọ Israeli tikọ̀ silẹ nitori iwa ẹsẹ wọn ni wọn ni ẹnikan tun ri tosi wá kà leti Josiah ọba. Gbigbọ ti Josiah ọba gbọ ọrọ yi, ọkàn rẹ gbọgbẹ de inu, eleyi to mu iyipada nla bã ati ilu na nitoripe Ọlọrun tipasẹ iwe na báà sọrọ. (II A. Ọba 22)

Nipasẹ awọn iwe ọrọ Ọlọrun, Ọlọrun a ma ba enia sọrọ lode òni.



(VI) IWASU: Nigbati eniyan ba ngbọ iwasu Ọlọrun a ma ba eniyan sọrọ pẹlu. Ohun ti eniyan ti ngbiyanju lati wa ọ̀nà abayọ si lati igba pipẹ, ninu ọrọ Ọlọrun gbígbọ́ Ọlọrun a mã sọ ọna abayọ fun ẹni na.

"O rán ọrọ rẹ, ó si mu wọn lara da, o si gba wọn kuro ninu iparun wọn" (Ps 107:20)

Nigbati enia ba ngbọ ọrọ Ọlọrun, enia a mã mọ boya ki oun gbe igbesẹ kan tabi ki oun ma gbe igbesẹ na.

(VII) Ọ̀RỌ̀ SISỌ: Nigbati a bá mba ara wa sọrọ ninu ile, nibi isẹ, ninu ọkọ̀ abbl, enia a ma ri ẹ̀kọ́ kan tabi omiran kọ̀. Ninu awọn ọrọ wọnyi, Ọlọrun nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ to mbẹ ninu enia a ma lu enia ni oókan aiya lati sọ fun enia wipe oun ni ọrọ na mba wi, tabi wipe ọrọ na wúlò fun-un.

Ninu iwe ihinrere ti Luku ori kẹrinlelogun ni a ti kà nipa ajinde Kristi Jesu kuro ninu oku. Lẹhin igbati Kristi Jesu jinde tan, ọpọ idamu lo de ba awọn ọmọ-ẹhin niti wipe wọn nse iyemeji nipa isẹlẹ na. Méjì ninu awọn ọmọ-ẹhin gbéra lati ma lọ si Emausi, ìlú to jinna si Jerusalẹmu niwọn ọgọta furlọngi, bi wọn ti nrin lọ ti wọn mba ara wọn sọrọ bẹna ni ẹnikan darapọ mọ wọn ninu irin na ti wọn si jijọ mba ara wọn sọrọ lọ. Lati ipasẹ ọrọ ti wọn jijọ nsọ ni Ọlọrun ti fi ọwọ kan awọn ọmọ ẹhin meji yi.

Kí awọn ọmọ Israeli o to de Jeriko, Josua ran awọn enia meji lati lọ se amí ilu Jeriko wa nigbati awọn enia wọnyi de Jeriko, nipa ọrọ sisọ ni wọn se mọ wipe Ọlọrun ti fi Jeriko le awọn lọwọ.

"O si wi fun ọkunrin na pe, emi mọ pe Oluwa ti fun yin ni ilẹ yi, ati pe ẹru yin ba ni, ati pe ọkan gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin" (Jos 2:9)



(VIII) ADURA: Ninu adura gbigba, Ọlọrun a ma ba awọn enia sọrọ (II Kron 20)

"Bi wọn si ti njọsin fun Oluwa, ti wọn si ngbawẹ, Ẹmi Mimọ wipe, ẹ ya Barnaba oun Saulu sọtọ̀ fun mi fun isẹ ti mo ti pe wọn si" (I Apo 13:2)


(IX) NIPA AWỌN WOLI: Oniruru ọna ni Ọlọrun ma ngba lati bá awọn woli sọrọ, sugbọn, ọ̀nà kan tabi ẹbun kan le wa nipasẹ eleyi ti Ọlọrun yio ma fi fi ara han awọn woli yi jùlọ. Lẹhin igbati Ọlọrun bá wa ti bá wọn sọrọ tan, wọn yio wa sọ ohun na di mímọ̀ fun ẹni na gẹgẹ bi a bá se dari wọn (I A. Ọba 19:14; 20:35-43; II A. Oba 3:15)

"Ati nipa woli kan ni Oluwa mu Israeli jade lati Egipti: ati nipa woli kan ni a si pa á mọ" (Hos 12:13) 

(X) NIPA IFARAHAN AWỌN ANGẸLI (TABI AWỌN ABÀMÌ ẸDA): Ọlọrun a ma ran awọn angẹli rẹ lati lọ ba enia sọrọ yala loju orun tabi lojukoju ki o le tọ́ enia sọna, tabi ki o mu enia lọkan le niti ohun ti ẹni na fẹ se, tabi niti ohun to mbẹ niwaju ẹni na.

Nigbati a mú aposteli Paulu gẹgẹ bi onde, ti a si ran si Romu, nigbati wọ́n de erekusu Yíyanjú aposteli Paulu gbà wọn niyanju wipe ki wọn o ma ti gbera kuro nibiti wọn wa na, sugbọn balogun to ndari wọn lọ kò gba imọran na wọle, eleyi to di wahala nla si ọrun gbogbo wọn. Lẹhin igbati wọn ti padánù ohun pupọ, ti awọn enia na si ti nro wipe kò daju wipe awọn yio làá, angẹli Oluwa farahan aposteli Paulu lati tù ú ninu, lati fi í lọkan balẹ wipe gbogbo wọn ni yio yọ ninu ewu na.

"Njẹ nisinsinyi mo gba yin niyanju, ki ẹ tujuka: nitori ki yio si ofo ẹmi ninu yin, bikose ti ọkọ̀…

"Nitoriti angẹli Ọlọrun, ti ẹniti emi ise, ati ẹniti emi nsin, o duro timi ni oru ana,

"O wipe, ma bẹru, Paulu; iwọ kò le saima duro niwaju Kesari: si wò ó, Ọlọrun ti fi gbogbo awọn ti o ba ọ wọkọ̀ pọ̀ fun ọ" (I. Apo 27:22-24)

Ni igba aiye majẹmu laelae, ohun to dájú ni wipe awọn woli lo sábà ma njẹ anfani isẹ iransẹ awọn angẹli, sugbọn ni aiye ti majẹmu titun, Ọlọrun si ilẹkun ore-ọfẹ na fun gbogbo awa ayanfẹ rẹ, o nfẹ ki awọn ayanfẹ rẹ o ma jẹ anfani nla na, nitori ko fẹ ki ẹnikẹni ó wà ninu okunkun titi ti ọjọ ibi yio fi de. 

"Sugbọn ẹyin ará, ko si ninu okunkun, ti ọjọ na yio fi de ba nyin bi olè" (I Tess 5:4)

Nitoripe Ọlọrun fẹ awa ayanfẹ Rẹ bi ẹyin ojú, gẹgẹ bi enia ti ndabobo oju rẹ lọwọ àwọn ìdọ̀tì ati ohun ẹgbin gbogbo, bẹna ni Ọlọrun tise nfẹ ki awa ayanfẹ rẹ o wa ni ipamọ patapata kuro lọwọ ibi gbogbo 

"...Nitori ẹniti o tọ yin, o tọ ẹyin oju Rẹ" Sek 2:8)

Ko si ẹnito nfẹ ki nkankan ó se ẹyin oju oun, nitorina ni gbogbo eniyan se ma ndabo bò ó. Onkọwe Psalmu wa gbadura wipe,

"pamimọ bi ẹyin oju" (Ps 17:8a)

nitori a ti mã pa wá mọ bi ẹyin ojú nitorina lo se se awọn angẹli Rẹ ni ẹmi ati iransẹ lati le ma jísẹ́ fun awa ọmọ Rẹ lati le mã sọ ohun ti yio sẹlẹ fun wa, tabi lati kó wa yọ kuro ninu ibi gbogbo.

"Ati niti awọn angẹli, o wipe, ẹniti o da awọn angẹli Rẹ ni ẹmi, ati awọn iransẹ rẹ ni ọ̀wọ́ ina:

"Ẹmi ti njisẹ ki gbogbo wọn nse, tí a nrán lọ lati má a jọ́sìn nitori awọn ti yio jogun igbala" (Heb 1:7,14)

Awọn angẹli wọnyi ni Ọlọrun se ni ẹmi ati ọ̀wọ́ iná lati le mã jisẹ fun awọn ayanfẹ Rẹ. Sugbọn ohun ibanujẹ lo jẹ wipe awọn kan kò mọ bi awọn angẹli wọnyi se jẹ si wọn nitorina, wọn a ma foribalẹ fun wọn, nitorina wọn a ma sìn wọn, nitorina wọn a ma gbadura si wọn bi igbati enia ba ngbadura si Ọlọrun. Sugbọn kò yẹ ki awa ayanfẹ, àni awa ti a ti gba Jesu gbọ ma se eleyi, ohun to yẹ ki a ma se ni ki a ma ran wọn nisẹ lorukọ Jesu, àní ki a ma pàsẹ fun wọn lorukọ Jesu lati se nkankan fun wa. 

Ohun ti awọn onigbagbọ míràn kò mọ̀ ni wipe, a nipò lọdọ Ọlọrun ju awọn ẹ̀dá wọnyi lọ. Gbogbo wa ni a si mọ wipe bi awọn enia meji bá wà lọ́dọ̀ ọ̀gá kan ti wọn nkọsẹ, ẹnito ba jẹ agba lẹnu ẹ̀kọ́sẹ́ na lẹtọ lati ran awon to wà labẹ rẹ nísẹ́. Bẹna ni ọrọ awa ayanfẹ Kristi ati awọn angẹli tise ri, a lẹtọ lati ma ran wọn nisẹ.

Ohun ti mo nsọ ni wipe yàtọ̀ si wipe Ọlọrun nran awọn angẹli si wa, awa pẹlu lẹtọ gẹgẹ bi òye ọrọ Ọlọrun lati ma ran wọn nisẹ. Ibere mi si iwọ oluka iwe yi wa ni wipe, bawo lóse ngbadun isẹ iransẹ awọn angẹli si? Bawo lo se nran awọn angẹli nisẹ si?

Awọn ọna diẹ ti Ọlọrun ma ngbã bá eniyan sọrọ niyi. Lati inu awọn ọna wọnyi ti ó bá ni eyikeyi ọrọ ti o ti gbọ́ ti ọkàn rẹ si ti lù fun, ti ọkan rẹ ti wa ni àìsinmi nitori rẹ, ó yẹ ki o mọ wipe nse ni Ọlọrun mba ẹ sọrọ lori awon ohun na. 

Njẹ tó bá wá jẹ wipe ohun to nise pẹlu aye rẹ ni ohun na ti Ọlọrun bá ẹ sọ, fun apẹrẹ, bóyá o rí ara rẹ wipe o jẹ ọba tabi olori gẹgẹ bi Josefu ti se ri ara rẹ ninu alã rẹ (Gen 37), a jẹ wipe eleyi ti di majẹmu ti Ọlọrun bá ẹ dá ninu ẹ̀mí gẹgẹ bi itumọ ìgbàgbọ́ ti a nwò lọ, ó sì ti wa daju wipe Ọlọrun yio mu ọrọ ileri to ba ẹ sọ ninu ẹmi na sẹ bópẹ́ bóyá. Ohun ti o ni lati se ni lati duro ti ọrọ rẹ ki o si mã sa fun gbogbo ifarahan ẹsẹ ati ibi gbogbo gẹgẹ bi Josẹfu ti se sá fun ifarahan ẹsẹ ati ibi gbogbo nigbato wà laiye, eleyi tó wá fun lanfani lati ri ileri na gbà.

"Ẹ ma takete si ohun gbogbo ti o jọ ibi" (I Tess 5:22)

"Má a sá fun ifẹkufẹ ewe" (II Tim 2:22)

Aposteli Paulu ninu episteli rẹ si awọn ara Tesalonika wipe "ẹ ma takete si ohun gbogbo tó jọ ibi" (I Tess 5:22), nigbati o sọ fun ọmọ Rẹ Timoteu wipe ko mã sa fun ifẹkufẹ ewe. 

Gbolohun mejeji yi nfihan wipe awọn nkan wọnyi kò ni sá fun enia, bikose wipe wọn yio ma le enia kiri lati mú eniyan, sugbọn, eniyan ni yio takete si wọn, enia ni yio sa fun wọn, enia ni yio jinna si wọn ki enia bã le ri ileri ti Ọlọrun ti ba ẹni na da ninu ẹmi gbà gẹgẹ bi o ti se wa sẹlẹ si Josefu. Awọn agbagba Yoruba bọ̀ wọn wipe, "oniyangi ma ba tèmí jẹ, epo ni mo rù", eleyi ni wipe ohun gbogbo to ba fẹ sọ enia di "dà bí mo ti dà, gẹgẹ bi baálẹ̀ atiro ti se nfẹ ki gbogbo enia o dà bí i tòun", nse leniyan yio se gafara fun ohun tabi awọn ohun nã.

Gbogbo awọn ọrọ majẹmu na, gbogbo awọn àlá ileri nã, gbogbo awọn asọtẹlẹ nã ti Ọlọrun ti fi ba wa sọrọ ni Ọlọrun yio musẹ fun wa nigbati awa na ba ti se ojuse wa, nigbati awa na ba ti pa ọrọ ati ofin ati ilana rẹ mọ patapata. Nitorina, igbagbọ jẹ majẹmu, tabi ileri tòhun tìbúra ti Ọlọrun bá wa dá nipa ẹ̀mí lati mã fihan wa wipe ohun ti Oun ti bá wa sọ wọ̀nyẹn yala ninu àlá, iran, ohun gbigbọ abbl yio wa si ìmúsẹ bópẹ́ bóyá.

Ẹ jẹ ká wo ìpín tabi ohun keji ti onkọ̀we iwe Heberu pè ni ìgbàgbọ́ gẹgẹ bi a ti se kọ ọ́ ninu iwe na ni ori kọkanla, ẹsẹ kinni, ipin keji.

"Njẹ igbagbọ ni..., ijẹri ohun ti a kò ri". 

Ohun ti a fẹ wo nisinsinyi na ni igbagbọ gẹgẹbi ijẹri ohun ti a kò ri. 


CHAPTER II (ORI KEJÌ)

ÌJẸ́RI OHUN ÀÌRÍ

Gbogbo wa ni a ma ngbọ nipa ijẹri...Ijẹri...Ijẹri...si agbara Ọlọrun tabi si agbara okunkun. O tilẹ seése ki àwa gan-an ti jẹri ri, yálà ninu ijọ tabi nibomiran. Ohun to hàn gbangba ni wipe gbogbo enia lo ti se é ri nigbakan tabi omiran. A le è jẹri láìmọ̀ wipe ijẹri ni a nse, nigbati o ba jẹ wipe larin awọn enia wa tabi larin idile wa, tabi boya nigbati a nba ọkọ wa tabi aya wa tabi afẹsọna wa tabi awọn ọrẹ wa sọrọ lori ohun kan ti a ti sọ ireti nu le lori sugbọn to jẹ wipe lọna kan tabi omiran, tabi nitoripe ohun kan sẹlẹ si ekeji ti ohun na si tun wa bọ si fun wa. Nitoripe ohun na bọsi fun wa lọna iyanu, lọna ti a ò fọkansi ati boya lasiko ti a ò fọkansi, a o fẹ sọ nipa rẹ fun awọn eniyan wa.

Tabi bóyá a lọ si irin ajo, irin ajo na si kún fun ọpọlọpọ ewu, a ó fẹ sọ ọ fun awọn enia wa bi Ọlọrun ti se kó wa yọ, tabi to ba jẹ wipe ẹniti (tabi awọn ti) wọn kò ni igbagbọ ninu Ọlọrun ni, wọn yio sọ bí orí ti se ko wọn yọ ninu ìrìn àjò nã...bi ẹnikẹni ba se eleyi, o njẹri ni.

Ẹniti o sẹ̀sẹ̀ gbeyawo tabi ti o sẹ̀sẹ̀ lọ́kọ ti wọn ni kó sọrọ ìdúpẹ to wa nbu omi loju tabi to nsọkun gidigidi, lẹhin igbati o sọkun na tan, ti awọn enia wa bere èrèdí ẹkún-un rẹ to wa wipe, oun kò mọ wipe oun le è lọ́kọ tabi niyawo mọ laiye nitoripe òun ti dãmu gidigidi lori ati lọkọ tabi ati láya ti gbogbo rẹ mbọ si ikorita kanna, ati wipe ti tẹni ti òun fẹ ẹ̀ yi, oun kò tilẹ ro wipe awọn le è fẹ ara awọn mọ, àfi ti nkan sì yí bírí to si wipe oun yio fẹ oun, ati wipe titi di ìrọ̀lẹ́ àná ti oun fẹ lọ sùn, oun nro wipe yio wa sọ fun oun wipe oun kò se mọ nitoripe irú rẹ ti sẹlẹ si oun ri, eleyi lo fa ti oun fi bú sẹkun nitoripe oun ko le è pa ayọ oun mọ ara ni.... Ohun ti ẹni yi nse yi, ijẹri ni a npèé.

Lati inu awọn ọrọ akawe diẹ to wa loke yi ni a ó ti ri wipe ijẹri jẹ sísọ tabi kíkọ nipa ohun ti enia ti là kọja yala rere tabi buburu, ti agbara kan (tabi ohun kan) sì kó enia yọ tabi la ọ̀nà abayọ fun enia nigbati enia ko tilẹ ro wipe oun le è ri ọna abayọ si ohun na mọ tabi ti ẹni na ti ro tabi mọ wipe kò si ohun to le mu ki ohun na bọ si mọ fun oun sugbọn ti ohun na tun wa bọ si fun ẹni na tabi ti ohun na wa tẹ ẹni na lọwọ.

Awọn anfani diẹ wa ninu ijẹri fun awọn olugbọ tabi awọn oluka ọrọ ẹni na.... Gẹgẹ bi anfani ti se wa nã ni ìrírí tun ti fihan wa wipe, awọn ewu diẹ na tun wa ninu ẹ̀rí jíjẹ nigbamiran. Ẹ jẹ ka wo mejeji.

ÀNFÀNÍ TÓ WÀ NINU JIJẸRI.

1) Awọn miran yio le kọ ẹ̀kọ́,

2) Awọn ti igbagbọ wọn kò duro tẹlẹ yio tun le mu igbagbọ wọn duro sí i,

3) Yio ru igbagbọ, igboya, igbẹkẹle ẹlomiran soke,

4) Yio mu ki awọn miran sún mọ́ Ọlọrun sí i (Ise. Apo 5),

5) Yio mu ẹlẹ́yà-mẹyà kuro ninu ijọ. Fun apere, Ijẹri aposteli Peteru lori Korneliu ati ile rẹ to gbagbọ (Ise. Apo 15:1-20),

6) 11 Nkan wọnyi si ṣe si wọn bi apẹrẹ fun wa: a si kọwe wọn fun ikilọ̀ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá. (I Kọr 10:11,)

7) Yio mu ki òkìkí ijọ tabi ẹniti Ọlọrun nlo pọ sí i (Mt 8);

8) Yio mu ki ijọ gbòòrò sí i,

9) Yio mu ki ihinrere gbilẹ̀ sí i,

10) Yio mu ki o wu awọn ará lati sọ ọrọ Jesu na fun enia gbogbo ati ẹnito ni, ati alaini, ati ẹnito gbédè ati ẹniti kò gbéde,

11) A mã mu ibukun wá (I. Apo 28:10) Aposteli Paulu ati awọn ti wọn jìjọ wa ninu ọkọ̀ oju omi ti padanu ohun pupọ nitori ijì to dide si wọn loju omi nã, sugbọn lẹhin igbati wọn de erekusu yi ti isẹ àkànse si ti ọwọ́ aposteli Paulu se si ara awọn eniyan ilu nã, nigbati wọn nfẹ gbéra lati ma lọ, awọn ohun rere ti wọn ti padanu wọnni ni Ọlọrun tun tipasẹ ijẹri to tẹle isẹ iyanu aposteli Paulu pese fun wọn ni eleyi tó tó lati gbé wọn de ilu wọn abbl.

ÀWỌN EWU DÍẸ̀ TO MBẸ NINU ẸRI JÍJẸ

1) Ọ̀tá tun le è gbe ogun dide yálà si ẹniyẹn tabi si idile rẹ (Jhn 9; Nah 1: 9),

2) Igberaga le è wọle (Num 16);

3) Wọ́n le è dìtẹ̀ ati fẹ pa ẹni na (I. Apo 23:12)

4) Wọn le e (fẹ́) le jade ninu ijọ tabi ẹgbẹ (Jhn 9),

5) Awọn miran le è fẹ se é lati wa ojurere awọn olori gẹgẹ bi Anania ati Safira ti se ninu iwe Ise Awọn Aposteli ori karun, lẹhin igbati wọn ri ohun ti Barnaba se (I. Apo 4:36-37);

6) Ìlàra le wọ inu ijọ (I. Apo 6; Gen 37). O sese kó jẹ wipe ilara awọn ẹgbọn Josẹfu bẹrẹ nigbati wọn ti ri wipe ààyò ọmọ ni Josẹfu jẹ lọ́wọ́ Jakọbu pẹlu asọ aláràbarà, asọ oloro nla ti Jakọbu ra fun-un.... Bi Josefu se nfi eleyi han awọn ẹgbọn rẹ, ati bi o ti se tun njẹri nipa ohun ti ọjọ ọla rẹ yio jẹ fun awọn ẹgbọn rẹ, ilara de, wọn bẹrẹ sini pinnu lati gbe subu, wọn bẹrẹ sini pinnu, wọn npete bi erongba ati àlá na ko se ni wa si ìmúsẹ.

Njẹ iwọ na ha mọ ohun to nfa èdè àìyedè wa sarin iwọ ati ololufẹ rẹ, iwọ ati afẹsọna rẹ, iwọ ati idile rẹ, iwọ ati oluranlọwọ rẹ? Ó le è jẹ nitoriwipe iwọ na njẹri, iwọ na nsọ nipa ohun to nsẹlẹ larin iwọ ati ololufẹ rẹ, nisoju awọn enia buburu, nisoju awọn afi ẹ̀jẹ̀ sínú tu itọ funfun sita, nigbati awọn eniyan wọnyi si ti gbọ nipa bi o se ndun, bi o se ndán mọ́rán larin yin, awọn pẹlu ti bẹrẹ sini gbógun níkọ̀kọ̀, awọn enia wọnyi si ti nta ọfà sinu idile yin lati da ile yin ru, wọn nransẹ buburu lati da omi alafia yin to ntòrò rú. A ò ni gbagbe ọrọ aposteli Peteru to wipe,

"...ẹ fi ìwà rere kun igbagbọ, ati imọ kun iwa rere" (II Pet. 1:5)

A nilati mã fi imọ bá awọn eniyan sọrọ nibi gbogbo, nitoripe ọpọ alãmu lo da ikùn delẹ, a ò si mọ eleyi ti inu nrun lara wọn si wa, bibeli pẹlu wipe, latin awọn enia mi lati ri enia ibi.

"Nitori lãrin eniyan mi ni a ti ri eniyan ìkà: wọn wò kakiri, bi biba ẹniti ndẹ ẹiyẹ, wọ́n dẹ okùn, wọn mu eniyan" (Jer 5:26)

Nitorina, a nilati fi ọgbọ́n ati igbagbọ kun irin ajo aye wa ki a ma ba wu ewu àìnidi lati ọdọ awọn eniyan.

7) O le fa iyapa sinu ijọ, pãpã ijọ ti wọn kò wa ni isọkan tẹlẹ, ijọ ti kò si ni ifẹ, nitori awọn kan yio mã sọ wipe awọn niti Paulu nigbati awọn miran le mã sọ wipe awọn ni ti Appollo,

8) O le è mu ki ẹniti ko ni iriri dàbí nkan ninu ihinrere na sọ wipe oun fẹ lọ da ijọ toun silẹ,

9) O le è mu ki awọn ọmọ ijọ gbe ẹbùn lékè ọrọ Ọlọrun, ati adura gbigba, eleyi ti yio mu ki awọn ọmọ ijọ na jẹ alaini imọ ati oye nipa ọrọ Ọlọrun, ati Jesu nã, eleyi ti yio si yọri si iparun bópẹ́ bóyá.

"A gé awọn enia mi kuro nitori àìní imọ: nitori iwọ ti kọ imọ silẹ, emi o si kọ̀ ọ́, ti iwọ ki yio se alufa mi mọ; niwọn bi iwọ ti gbàgbé ofin Ọlọrun rẹ, emi pẹlu o gbagbe awọn ọmọ Rẹ.

"Bi a ti mu wọn pọ̀ si i to, bẹna ni wọn si dẹsẹ simi to: nitorina emi o yi ogo wọn pada si itiju" (Hos 4:6-7)

Nitori ẹbun ni awọn enia ati ọmọ ijọ na fi pọ̀ gidigidi sugbọn wọn kò ni imọ ọrọ̀ na, eleyi lo fa ti Ọlọrun se gbagbe wọn ti Ọlọrun si se ta wọ́n nù. Bẹna lo nsẹlẹ ni ọpọ ijọ loni, ẹbun ni wọn gbéga, ẹbun lo mu ki ijọ na lokiki, sugbọn, imọ nipa ọrọ Ọlọrun keré púpọ̀, eleyi to fa idamu fun wọn, eleyi to fa wahala nla wọnu ìhìnrere.

10) O le fa ìkùnsinu (I. Apo 6:1) abbl

Bi ohun ti a nwo lọ, ìtumọ̀ ìgbàgbọ ti a nwo lọ, eleyi ti olukọ iwe Heberu ori kọkanla ẹsẹ kinni tun wi ni ila keji rẹ wipe, ó jẹ́ "ìjẹri ohun ti a kò ri".

Pẹlu awọn ọrọ ti a fi túmọ̀ jijẹri sókè, ohun tó hàn gbangba ni wipe, jíjẹ́ri jẹ sisọ tabi kíkọ nipa ohun ti enia ti là kọja ri, kì í se ohun ti enia kò ì tí ì là kọja rí. Sugbọn ninu iwe Heberu ori kọkanla yi, onkọ bibeli yi wipe, igbagbọ jẹ jijẹri si ohun ti enia ko ri, sisọ tabi kikọ nipa ohun ti enia kò ì tí ì ri. Eleyi ni wipe, sisọ tabi kikọ nipa ohun ti enia kò ì tí ì la kọja ri, sisọ tabi kikọ nipa ohun ti enia kò ni ìrírí i rẹ ri.

A o ri wipe ọ̀rọ̀ yi tako ọrọ imọ ijinlẹ aiye, ọrọ yi tako imọ ijinlẹ sayẹnsi, ọrọ yi tako ọrọ awọn enia to wipe, "iriri ni àgbà olukọ́". Lati ihinyi ni a ó ti ri wipe, ọrọ igbala, ọrọ agbelebu, ọrọ Jesu mã ntako gbogbo imọ ijinlẹ aiye, nitorina ni olukọ iwe Kọrinti kinni ori kinni ẹsẹ kejindinlogun se wipe, 

"nitoripe wère li ọrọ agbelebu si awọn ti o nsegbe; sugbọn si awa ti a ngbala, agbara Ọlọrun ni" ori keji ẹsẹ kẹrinla iwe kanna tun wipe, 

"sugbọn enia nipa ti ara ko gba ohun ti Ẹmi Ọlọrun wọnni: nitoripe were ni nwọn jasi fun u: on ko se le mọ wọn, nitori nipa ti Ẹmi li a fi nwadi wọn".

Onkọwe Heberu yi wipe, "njẹ igbagbọ ni ijẹri ohun ti a kò ri" (Heb 11:1b). 

Eleyi ni ede miran nsọ gẹgẹ bi awọn itumọ gbogbo ti a ti kọ soke wipe, "igbẹkẹle tó le, tabi to lagbara ti enia ni ninu ohun kan ti enia fi nsọ nipa ohun nã". 

Ẹ jẹ ka wo awọn apẹrẹ diẹ lati salaye ọrọ yi, "igbẹkẹle to le ninu ohun tabi Oun àìrí ti enia fi nsọ nipa ohun (Oun) na".

Abramu ninu Genesisi 14 sọ nipa ti Ọlọrun bi o tilẹ jẹ wipe ko ri Ọlọrun lojukoju nigbana, sugbọn o nsọ nipa ohun ti ko le se alaisẹlẹ si Oun lọjọ iwaju, o nsọ bi o ti se dã lójú tó wipe Ọlọrun yio sọ oun di ẹni ibukun ati ẹni nla gidigidi fun ọba Sodomu, nitori wipe awọn ohun iyanu to ti sẹlẹ sí i, eleyi mu ko fi ọwọ Ọlọrun gbáyà to si fi kọ ẹbun ọba Sodomu.

"Abramu si wi fun ọba Sodomu pe, mo ti gbe ọwọ mi soke si Oluwa, Ọlọrun Ọga-Ogo, ti o ni ọrun ohun aiye, 

"Pe, emi ki yio mu lati fánrán òwú titi de okun bata, ati pe, emi ki yio mu ohun kan ti ise tirẹ, ki iwọ ki o ma ba wipe, mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀;

"Bikose kiki eyiti awọn ọdọmọkunrin ti jẹ ati ipin ti awọn ọkunrin ti o ba mi lọ; Ameri; Eskoli, ati Mamre; jẹ ki wọn ki o mu ipin ti wọn" (Gen 14:22-23)

Awọn ibalopọ, ajumọjọsepọ, iriri ti Abramu ti ni pẹlu Ọlọrun nisaju, eleyi mu ki o da Abramu loju wipe olotitọ ati olododo ni ẹniti o se ileri fun Oun wipe yio mu ileri rẹ sẹ si oun ati idile oun lara nipa sisọ oun di ẹni ibukun gidigidi. Igbẹkẹle to le yi, ani igbagbọ yi, nmú kó sọ nipa ti ọjọ ọla ti ko i ti farahan fun-un.

Lásìkò ti Abramu nfi ọwọ Oluwa Ọlọrun sọ̀yà yi, Abramu ti lé ni àrùndínlọgọrin ọdun, bẹni kò sì tí ì bimọ laiye, sugbọn sibẹ o nfi ọwọ́ Ọlọrun, Ẹlẹda sọ̀yà nipa ọjọ ọla rẹ, njẹ a ò ha ri iru igbagbọ nla yi?

Njẹ awa na ha le ni iru igbagbọ yi bi? Njẹ a ha le ni ìgbẹ́kẹ̀le líle ninu Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ ti a o fi mã sọ nipa ọjọ ọla didara ti Ọlọrun ti se ileri fun wa bí ó tilẹ̀ jẹ wipe ni ikorita ti a wa nã, ohun gbogbo kò ì tí ì yípadà.

"Nitori emi mọ èrò ti mo rò si nyin ni Oluwa wi, àní ero alafia, ki si ise fun ibi, lati fun nyin ni ìgbà ikẹhin ati ireti" (Jer 29:11)

Njẹ a ha le ni iru igbẹkele àìlẹgbẹ́ bi iru ti Abramu yi nigbati a ri ọna lati di ọlọrọ, a ri ọna lati di olokiki, a ri ọna lati di ìlú-mọmika sugbọn ti a ó si kọ ọna na silẹ lati faramọ́ ati lati duro de Ọlọrun. Njẹ a ò ri ninu isẹlẹ yi wipe ohun ti ọba Sodomu nsọ pe ki Abramu ó se, ohun ti Abramu lẹtọ si ni, ki ise wipe ó se ojú kòkòrò rẹ, ki ise wipe ó gba ọ̀nà èrú tabi ọna àgálámọ̀sà kọ́, ki ise wipe o fẹ yan eniyan jẹ ni, gẹgẹ bi iru eleyi ti awọn eniyan ma nse loni, wọn a ni ẹnito ri ẹsẹ were ti kò bù ú ọlọgbọ́n wo ni yio ha gbé tirẹ kalẹ̀? Awọn eniyan a wipe bi awọn "aiye" ti ma nse ni eleyi, nitorina, awọn ohun ti ko dara wọn yio mã se é, wọn yio mã yan awọn eniyan jẹ.

Sugbọn. Eleyi kò ribẹ fun Abramu, bi o tilẹ jẹ wipe o lẹtọ si ìkógun nã, sugbọn sibẹ ó yàn lati duro de ibukun Oluwa, o yan lati gba ileri Ọlọrun gbọ, nipasẹ eleyi tó se sọ pe oun kò ni gba ohunkohun ninu ìkógun na. Nitoripe Abramu mọ wipe igbakugba ni Ọlọrun lè dé, igbakugba ni ibukun nã le farahan, Abramu mọ wipe Ọlọrun kò dà bi awọn alasẹ aiye ti wọn yio ni awọn ọlọpa ti wọn ti mã fun kàkàkí tabi ferè lati sọ wipe wọn mbọ nibikan, wọn ko ri bi awọn alasẹ aiye ti wọn yio lọ sọrọ lori afẹ́fẹ́ pe awọn se ohun bayi fun lagbaja, ire Ọlọrun ko nilo ipolongo nigbati ó bá fẹ farahan eleyi ni Abramu mọ̀ to si duro ti, eleyi lo fi í lọkanbalẹ, tó sì fun ni igbẹkẹle nla tóbẹ́ẹ̀ to fi nsọ wipe oun ko ni gba ojunkohun. Ẹ̀ẹ̀wẹ̀, Abramu mọ wipe, ó le jẹ lẹhin igbati oun ba gba awọn ohun na tan lọwọ ọba Sodomu lawọn ohun ti oun ni yio wa di púpọ̀ gidigidi, ti ọba Sodomu yio si wa mã wipe ti ki iba se tòun, ti ki iba ise ti ogun ti oun mu Abramu lọ jà kì bá ti da ohun to da bayi, kì bá ti lọ́lá to bayi, ki bá ti lokiki to bayi. Nitori ki Abramu le fihan enia gbogbo wipe nitotọ ati lododo ni wipe 

"Ibukun Oluwa ni imu ni ilà, ki isi ifi lãla pẹlu rẹ" (Owe 10:22)

eleyi lo fa ti Abramu se yàn lati duro ti ileri Oluwa. Abramu nkọ wa lati mọ̀ wipe ki ise gbogbo ohun ti enia lẹtọ si nã leniyan ma ngba, pãpã ti enia ba ti ri wipe iru awọn ohun na ti eniyan lẹtọ si le è mu ẹrẹ̀ ati abuku ba orukọ Ọlọrun ninu aye wa, ani nigbati enia ba ti ri wipe awọn ohun ti enia lẹtọ si nã le è ma mu ki ohun ti Ọlọrun ti se ileri lati sọ wá dà lọjọ iwaju ó jẹ́ pataki loju wọn, ohun to dara ni lati pa ohun na ti sẹgbẹkan. 

"Nitori láìse àní-àní mo sì ka ohun gbogbo si òfo nitori ìtayọ ìmọ̀ Kristi JESU OLUWA mi: nitori ẹniti ,o ti sòfò ohun gbogbo, mo si ka wọn si ìgbẹ́, ki emi ki o le jere KRISTI" (Fil 3:8)

Abramu fi igbẹkẹle nla eleyi to ni ninu Jehofa nla hàn nipa sisọ nipa ohun àìrí eleyi ti Oluwa ti sọ fun wipe OUN yio se fun-un fun ọba Sodomu. Bi o tilẹ jẹ wipe ohun gbogbo to yí i ka lasiko ba ko ti sọ nipa imusẹ ileri (ọrọ àjọsọ) nã sibẹ, o gbẹkele, o si nfi igboya sọ ọ, bẹna ni o si nfi gbogbo igbẹkẹle nla rẹ han ninu Jehofa nla alagbara nã. Ọlọrun nfẹ ki o yé gbogbo eniyan wipe Ọlọrn a ma bùsí isẹ ọwọ́ olotitọ eniyan, Abramu nfẹ ki gbogbo eniyan mọ̀ daju wipe ọwọ́ ati ọkàn alãpọn la ó mu sanra. 

"Ọwọ alãpọn ni yio se akoso; sugbọn, ọlẹ ni yio wà labẹ ìsìnrú" (Owe 12:24)

Abramu nfẹ ki gbogbo enia mọ wipe, ọ̀lẹ ko ri aiye ire wa, ọlẹ kò le ni ibukun Ọlọrun, ati wipe oun ki ise ọlẹ, nitorina o di dandan fun Ọlọrun lati mu ileri na sẹ fun oun. 

"Ọkan ọlẹ nfẹ, ko si ri nkan; sugbọn ọkan awọn alãpọn li a o mu sanra" (Owe 13:4)

Nitorina, Abramu fi igbẹkẹle nla toni ninu Ọlọrun hàn, nitori ó mọ̀ wipe,

"Ninu gbogbo lãla li erè púpọ̀ wà; sugbọn ọrọ-ẹnu, lasan ni" (Owe 14:23)

Alábájọ ti Ọlọrun tikalara Rẹ se pè é ni ọ̀rẹ́ Oun, alabajọ ti o se wá di baba igbagbọ loni ati lati ipasẹ ẹniti a ti bukun fun gbogbo orilẹ ede aiye.

Awọn Heberu mẹta ninu iwe Danieli ori kẹta pẹ̀lú ko se alai sọ niti igbẹkẹle wọn tó daju ninu Ọlọrun ti wọn ko rí rí bikosepe wọn kà nipa rẹ nigbati wọn da ọba lohun wipe, 

"...kò tọ́ síwa lati fi esi kan fun ọ nitori ọ̀ràn yi."Bí ó bá ríbẹ, Ọlọrun wa ti awa nsìn, le gba wá lọwọ rẹ ọba. "Sugbọn bi bẹkọ, ki o ye ọ, ọba pe, awa ki yio sin orisa rẹ, bẹli awa ki yio si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ̀" (Dan. 3:16b-18)

Ìtàn awọn Heberu mẹta: Sadraki, Mesaki ati Abednego, wonyi jẹ itan to kari aiye kárí oko, sàsà ìlú ati orilẹ ede ni ko gbọ́ tabi kà nipa itan awọn ọkunrin akọni igbagbọ wọnyi. Kinni ohun to sẹlẹ si wọn? Ohun to sẹlẹ na ni wipe ọba Nebukadnessari, ẹniti Ọlọrun kó gbogbo ijọba gbogbo aiye le lọwọ ni asiko tiwọn ro ninu ara rẹ wipe awọn orisa ti oun ati ilu oun nsin lo fi gbogbo ijọba orilẹ-ede ati ìlú jákèjádò aiye le oun lọwọ, nitorina o yẹ ki oun se ọdun fun orisa oun, ọba nla na ro wipe, ó yẹ ki oun mú ki awọn ti wọn kò mọ nipa orisa oun ó mọ nipa rẹ, ani ọba Nebukadnessari rò ninu ara rẹ wipe àsìko tó, ó yẹ ki oun bu ọla fun orisa oun, o yẹ ki oun fi títóbi awọn orisa oun hàn, ki oun si tipa eleyi mu ki gbogbo awọn enia gba orisa oun ni ọba ati alasẹ jakekado agbaiye, o nfẹ ki wọn o mọ wipe kò si alagbara miran lẹhin orisa oun to fi gbogbo àkóso ijọba aiye le oun lọwọ, bẹni ki ise eleyi nikan, wọn tun fun oun lọ́gbọ́n lati kọ ijọba nla, awọn ile nla, wọn fun oun ni aseyọri irufẹ eleyi ti ko si iru rẹ ri laiye igbana.

Lati wá se ayẹyẹ nla fun awọn orisa wọnyi, ọba Nebukadnessari pasẹ wipe ki gbogbo enia o tẹriba fun ere orisa oun nígbàkúùgbà ti nwọn ba ti gbọ ìró fèrè, kàkàkí ati oniruru ohun elo orin gbogbo. Awọn iransẹ ọba si yara kánkán lati lọ sọ asẹ ọba yi fun gbogbo awọn olori ati alakoso ilu kọ̀ọ̀kan jakejado agbaiye wipe eleyi ni ọba pinnu lati se, ati wipe wọn nilati sọ ipinnu ọba nla ti i jẹ Nebukadnessari yi di mímọ̀ fun gbogbo awọn olugbe inu igberiko gbogbo, eleyi ni wipe, ki eku ile ó gbọ kó sọ fun toko nipa asẹ ọba yi.

Ki ise òní tabi àná ni ọba nla to njẹ Nebukadnessari ti pasẹ yi, nitoripe aiye igbana kò rí bi aiye ode oni ti aiye ti lu ja ara, ti ọrọ ti wọn nsọ ninu òkún le di mimọ fun awa ti a wà lori oke erupẹ lẹsẹkanna. Gẹgẹbi aiye igbana, ọba na fi ọjọ silẹ ti awọn iwẹfa ati awọn onisẹ rẹ yio mu asẹ ọba na de gbogbo ilu patapata. Nibiti o jìnna jọjọ, mo woye wipe ọba nla nã yio ran ẹranko lati lọ fi isẹ na fun wọn ninu ilu na, gẹgẹ bi a ti se mọ wipe wọn ma nlo ẹiyẹ lati lọ jisẹ fun ilu tó bá wa lẹhin òkun nibiti yio nilo ọjọ pupọ lati ré kọja okun ki onisẹ (eniyan) to le de (Gen 8:7-11). Lẹhin igbati gbogbo awọn ti ọba ran nisẹ na ti padà wa jisẹ fun ọba wipe isẹ to rán, àní asẹ to pa nã ti kan gbogbo eniyan lara, lọ́jọ́ ti ọba da na ni ọba pasẹ wipe ki a fun fèrè, kàkàkí ati awọn oniruru ohun elo orin na ki gbogbo enia ó gbọ́, ki nwọn o si le tẹriba fun ere orisa oun.

Gẹgẹ bi apẹrẹ ti mo nsọ lẹkan, mo woye wipe bi fere ati awọn oniruru ohun elo orin na ti dún lafin ọba, o sese ko jẹ wipe ní awọn ibùsọ kọkan ti ko jinna si afin na, ani awọn ibiti ọba ti yàn silẹ ni ọba ti setò awọn kan sibẹ ti wọn yio tun mã tú ilu ati fere ati awọn oniruru ohun elo orin wọnni na fọn...lati ipasẹ awọn ipele-ipele, àtagbà, àtagbà gbogbo wọnyi ni gbogbo enia ni ilu ati igberiko titi de inú ahéré fi gbọ nipa ìró oniruru ohun elo orin wọnni.

Gẹgẹbi a ti yan awọn ti yio ma fun fere ati ti nwọn yio ma lo oniruru ohun elo orin, bẹna ni ọba gẹgẹbi o ti se jẹ oni làkáyè enia yio tun yan awọn enia ti wọn yio ma foju silẹ feti silẹ, finu silẹ lati wò bóya a o ri ẹnikẹni ti ko ni mu asẹ ọba nla to njẹ Nebukadnessari sẹ.

Ọba Nebukadnessari si ti sọ ninu asẹ rẹ wipe ẹnikẹni to ba kùnà lati pa asẹ nã mọ, ẹnikẹni to ba kuna lati yẹ́ orisa oun to sọ oun di nla si nipa titẹriba ati wíwolẹ̀ àní fiforibalẹ̀ fun, iru ẹni bẹ tabi awọn ẹni bẹ wọn yio di gbígbe sinu ina ti oun yio da, ayafi ti awọn ti oun yio yan lati mã wo kakiri kò ba ri wọn lókù, tabi ti wọn ba ri wọn sugbọn ti wọn ko fi to oun leti wọn ba gbabọde fun oun.

Gẹgẹ bi asẹ ọba, a sètò iná nã kalẹ̀, iná nã gbóná girigiri, bẹna ni a sì tun fun fèrè na ti a si lu awọn oniruru ohun ilu orin ọba.

Sugbọn ohun ìyàlẹ́nu nla ló wá jẹ wipe lara awọn olóyè, lara awọn olori ni igberiko ọba gãn ni kò foribalẹ fun ere orisa ọba. Eleyi ni wipe, ki ise awọn tó wa ni ahéré tabi awọn to wa ni abúle, ki ise awọn ti wọn le sọ wipe awọn kò gbọ ìfilọ̀ ati asẹ ọba, ki ise awọn ti wọn le sọ wipe awọn kò gbọ́ fere ati oniruru ohun elo ọba gãn ni ko foribalẹ fun ere ọba bikose awọn ti wọn gbọ́ ọ dájúdájú ni wọn kọ etí ọ̀gbọn-hin si iro oniruru ohun elo orin wọnni.

Mo woye wipe yàtọ̀ si wipe awọn eniyan wọnyi ko foribalẹ fun ere ti ọba Nebukadnessari gbekalẹ, o sese ki wọn o má fi ọrọ na se ifilọ ni ilu ti wọn nse akoso le lori, nitoripe wọn jẹ ẹnito bẹru Ọlọrun gidigidi, bẹna ni wọn si nfẹ fi ibẹru Ọlọrun nã mú awọn enia mọ wipe Ọlọrun kan wa; Ọlọrun Abrahamu, Ẹ̀rù Isaaki ati Igbẹkẹle Jakọbu, Ọba to ni ọrun, ati aiye wipe Oun ló yẹ lati ma fi gbogbo ogo, ọla, agbara ati ipa fun, ati wipe Oun nikan lo yẹ lati yìn ati lati sin, nitorina, wọn ko se ifilọ asẹ ọba Nebukadnessari ninu ilu ati awọn agbegbe ti wọn nsàkóso le lori bẹna ni awọn gan kò ka asẹ na si.

Ohun miran tó tún sese ni wipe bi awọn eniyan wọnyi ko se mu asẹ ọba sẹ nipa sise ifilọ ọrọ ti ọba sọ ninu ilu ti wọn nse akoso le lori, o sese ki irohin na ti mã kan ọba léti lafin rẹ wipe awọn eniyan wọnyi kò pa ofin rẹ mọ, ti ọba yio si ti má a sọ fun wọn wipe ki wọn o mase da ara wọn lamu ki wọn o jẹ ki awọn ó gbé onisẹ dide lati afin ọba lọ kó lọ jisẹ na, nitoripe oun mọ̀ wipe wọn kò sã ni sọ wipe ki awọn onisẹ oun o mase jisẹ na larin ilu, "nitori à nwẹ̀ ẹ jare ọyẹ́ ni". Awọn oloye ọba Nebukadnessari nã yio si ti sọ wipe òtítọ́ ni."Lẹhin igbati a bá se gbogbo eleyi, ti ìró oniruru ohun elo orin ba si tun dún, sùgbọ́n síbẹ̀ ti awọn eniyan ilu wọnni kò ba tun foribalẹ ki nwọn o si wólẹ̀ lati sin orisa emi ọba, orisa to jogun gbogbo aiye fun mi, lẹhinna ni a ó wa fi wọn jofin, lẹhin igbana ni wọn yio fi imú kó ata ofin, "ọba Nebukadnessari pari ọrọ̀ rẹ.

Lotitọ ati lododo, gbogbo ojú nwo wọn, awọn enia na si se gẹgẹ bi ofin ati ilana woli Mose ti a ti fi kọ́ wọn kó tó di wipe a kó wọn ni igbekun lọ si ilẹ Babiloni. Ofin ti a fi kọ wọn ti wọn ntẹlẹ nã ni eleyi.

"Iwọ kò gbọdọ li ọlọrun miran pẹlu mi.

"Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ.

"Iwọ kò gbọdọ tẹ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹni iwọ kò gbọdọ sin wọn: nitori emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ ẹsẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta, ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi" (Eks 20:3-5)

A sè gbàgbọ́ ma sẹ ni awọn eniyan na, wọn kò tẹriba fun ere ọba nigbati iró fere ati oniruru ohun elo orin na dún....

Irohin àìgbọran awọn eniyan wọnyi ló kan ọba Nebukadnessari lafin, ti ọba na si sọ fun wọn wipe, oun ti ngbọ fìnrìn-fìnrìn àìgbọran wọn ó tó ijọ melo kan, nitorina oun nfẹ ki wọn o sọ wipe irọ ni wọn pa mọ awọn ki wọn o si tẹriba fun ere orisa oun lẹhin igbati oun ba pasẹ pe ki nwọn o tú fere ati oniruru ohun elo orin nã fọn. (Dan. 3:14-15)

Bi ọba Nebukadnessari ti se mba awọn enia wọnyi sọrọ bẹna ni awọn eniyan wọnyi nranti ọrọ asọtẹlẹ woli Isaiah ti o wipe, 

"Sugbọn nisinsinyi bayi ni Oluwa wi, ẹniti o da ọ, Jakọbu, ati ẹniti o mọ ọ́, Israeli, ma bẹru: nitori mo ti ra ọ pada, mo ti pe ọ li orukọ rẹ, ti emi ni iwọ."Nigbati iwọ ba nla omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati larin odò, nwọn ki yio bò ọ mọ́lẹ̀; nigbati iwọ ba nrin ninu ina, ki yio jó ọ, bẹni ọwọ́-ina ki yio ran ọ" (Isa. 43:1-2)

Wọn ranti ọrọ yi nã wọn se sọ nipa ti ohun ti wọn ko iti ri ko sẹlẹ si ẹnikẹni ri wipe yio sẹlẹ si wọn. Wọn fi igbẹkele wọn to lagbara ninu Ọlọrun hàn nipa sisọ wipe Ọlọrun ti awọn nsin lọsan ati loru yio gbàwọ́n lọwọ ati kuro ninu iná, bẹna ni yio si tun gbàwọ́n kuro lọwọ ìwọ ọba Nebukadnessari. Wọn ranti ọrọ woli na to wipe,

"nigbati iwọ ba nrin ninu ina, ki yio jó ọ, bẹni ọ̀wọ́-ina ki yio ràn ọ" (Isa. 43:2). 

Wọn ranti wipe Ọlọrun ti gba ẹnu woli rẹ sọ wipe, Oun yio pẹlu wọn ninu iná, nitorina nigbati Ọlọrun bá pẹlu enia ninu iná, lẹhin igbati iná ati ọ̀wọ́ ina kò jó eniyan, kilo ha tun ku ti Ọlọrun nã yio se kọja ki o tun gbà wọn? Ohun to dá wọn lójú sáká ni wipe ileri Ọlọrun ninu ọrọ rẹ na yio sẹ, nitori o wipe, ọrun ati aiye yio kọja sugbọn kekere ninu ọrọ Oun ko ni lọ laisẹ.

"Lotọ ni mo sá wi fun nyin, titi ọrun on aiye yio fi kọja lọ, ohun kíkíni kan ninu ofin ki yio kọja, bi o ti wù ki o ri, titi gbogbo rẹ yio fi sẹ" (Mt. 5:18)

Bi o tilẹ jẹ wipe kíkà ni awọn eniyan wọnyi ka ọrọ asọtẹlẹ na nigbana, tabi boya wọn mu iwe akọsilẹ na dani lọ silẹ igbekun, ti nwọn si nka lọhun, kikà ni ki ise wipe wọn rí i ri. O si le jẹ wipe gbígbọ́ ni wón gbọ́ ọ ri, sugbọn sibẹ wọ̀n ko i ti ri ẹnito sẹlẹ si lojukoju ri, sibẹ, wọn fi igbẹkẹle nla wọn ti nwọn ni ninu ọrọ Ọlọrun na han nipa jijẹri, nipa sisọ nipa ohun ti wọn kò rírí. Wọn sọ igbẹkẹlẹ wọn ninu ohun ti wọn ko ri rí wipe ohun na yio bẹrẹ sini sẹlẹ lati orí wọn lọ, bẹna lo si ri.

Latinu awọn akawe wọnyi ni a ti ri gbangba gbàngbà ohun ti itumọ ìgbàgbọ jẹ, o jẹ sisọ pẹlu igboya niti ohun ti Ọlọrun sọ fun eniyan wipe yio sẹlẹ wipe ohun na kò ni se alaisẹlẹ siwọn nigbati aiye yio si mã jẹ aiye ti ẹni na bá sì wà loke erupẹ tabi nigbamiran, o le jẹ wipe ileri na wà fun awọn iran to mbọ lẹhin ẹni na, sugbọn ohun to daju ni wipe, ileri na yio sẹ tabi farahan bópẹ bóyá.... A o ranti wipe ọ̀rọ̀ ìsọtẹlẹ ti woli to ti Juda wa (ti ọpọ npe ni woli kekere) sọ ni Bẹ́tẹ́lì kò sẹ nisoju rẹ tabi nisoju ọba Jeroboamu, se nitotọ ọrọ tó sọ kò sẹ lasiko awọn ìran nã, sugbọn ó sẹ lọpọlọpọ ọdun lẹhin eleyi (I A. Ọba 13 cf II A. Ọba 23:17; Heb 11:39)

Ti o ba jẹ wipe iwọ na ti ka nipa ileri ati awọn ilana Oluwa Ọlọrun Eledumare ninu Bibeli ti o si npa awọn ofin ati ilana na mọ, iwọ na le è fi igboya fi igbẹkẹle nla ti iwọ na ni ninu ọrọ Ọlọrun wọnyi hàn nipa sísọ niti awọn ohun rere ti Ọlọrun ti sọ fun ẹ wipe o di dandan yio sẹlẹ si aye rẹ niwọn igbati iwọ ba si wa ninu aiye ati loke erupẹ.

Ohun afiyesi pataki ni wipe, gbogbo awọn to njẹri ohun àìrí, ki ise wipe wọn jẹ ẹlẹsẹ, ki ise wipe wọn ntẹsiwaju ninu ẹsẹ bikose wipe wọn ti fi ẹsẹ wọn silẹ patapata, ani awọn ẹsẹ eleyi ti wọn mọ.

"Njẹ àwa o ha ti wi? Ki awa ki o ha jòkó ninu ẹ̀sẹ̀, ki ore-ọfẹ ki o le mã pọ sí i? 

"Ki a ma ri...." (Rm 6:1-2a)

Ọpọ eniyan loni lósì njòkó sinu ẹsẹ ti wọn nfẹ ki ore-ọfẹ ma pọsi fun awọn. Ọpọ enia loni ni ko fi ẹ̀sẹ̀ silẹ sugbọn ti nwọn nfẹ ma fi igbẹkẹle wọn tó le hàn ninu ohun ti wọn ro wipe kò ni se alaisẹlẹ si wọn lọjọ iwaju gẹgẹbi wọn tise kà á ninu bibeli tabi gẹgẹbi wọn ti se la àlá rẹ, tabi gẹgẹbi woli tise sọ fun wọn, tabi gẹgẹbi wọn tise gbọ ninu iwasu. Kò si bi Ọlọrun se fẹ́ ré ileri rẹ kọja. Ko si bi Ọlọrun ti se fẹ foju fo ọrọ rẹ, ko si bi Ọlọrun se fẹ se ipa tirẹ̀ nigbati iwọ enia na kùnà lati se ipa tirẹ. O nilati se ipa tirẹ, o nilati se ojuse rẹ, o nilati sá fun ẹsẹ ki o si fi ara mọ gbogbo ọrọ Ọlọrun patapata, nigbati ni iwọ na le è sọ wipe igbagbọ ni ijẹri ohun ti o kò ì ti ri, sugbọn ti o da ẹ loju wipe yio sẹ laiye rẹ.




CHAPTER III (ORI KẸTA)

KINNI KI NKAN DÀGBÀ? 

Ki eniyan ó tó le è so wipe nkan ndagba, ohun (tabi ẹni) na yio kuro ni ipò tó wà tẹlẹ̀, ti yio si ga sí i tabi ki ó fẹ̀ sí i, tabi tóbi sí i, tabi kó gbé ìwọ̀n ju titẹlẹ lọ. Fun enia (tabi igi), a o ri wipe ọ̀nà ti a lè fi sọ wipe eniyan to ti ga de opin gíga fi ndàgbà sí i ni nipa òye ati imọ to ni nipa nkan, nipa ọrọ to ngbọ, nipa isẹlẹ to nsẹlẹ. Bi iru ẹniyi se ndájọ, bi o se nfèsì tabi dahun si awọn ọrọ ti wọn pè é si, eleyi ni yio mu ki awọn eniyan sọ wipe o ndagba si i. Eleyi ni wipe dídàgbàsókè ti eniyan to ti tójú bọ́ ndagbasoke ki ise eleyi to se fi ojuri, idagbasoke wọn jẹ eleyi to farasin.

ESO GẸGẸ BI APẸRẸ: Lati le salaye ọrọ yi daradara, ki o si le yé wa daradara, ẹ jẹ ka lo èso ti enia le è gbìn. A o ranti wipe nigbati Jesu gan nsalaye ọrọ ijọba ọrun fun awọn eniyan, ki ọrọ nã bà á le ye gbogbo enia daradara, ó lo eso lati fi salaye fun awọn ọmọẹhin rẹ nitoripe ó mọ̀ wipe ọpọlọpọ wọn ti ki iba se gbogbo wọn ló mọ̀ nipa isẹ àgbẹ̀, nitorina o lo eso lati sapẹrẹ, o si wa fi ọrọ rẹ we eso ti enia ma ngbìn. (Mt 13:3-8; 19-23; 24-30; 36-41; 31-32; Mk 4:3-8; 14-20; 31-32)

Gẹgẹ bi apẹrẹ eso ti Jesu lo yi, ohun to han gbangba ni wipe, ki a to le sọ wipe nkankan yio dagba, awọn nkan wọnyi nilati sẹlẹ saju: 

(1) ILẸ̀ RERE: Ki a tó gbin esokeso, eniyan yio kọkọ wa ilẹ ti yio gbin ohun na si. Bi enia ba ti ilẹ rere, ohun ti enia yio gbìn na yio se daradara, sugbọn ti enia ko ba ri ilẹ rere ohun ti enia yio gbin na kò nise daradara tó.

Awọn ilẹ miran lè dára, sugbọn ki wọn o ma dara fun eso ti a fẹ gbìn ohun na si, nitorina, enia yio tun wadi lati mọ daju boya ilẹ na ti oun ri yio dara fun eso ti oun nfẹ gbìn sinu rẹ lati mu ki o se daradara.

Gẹgẹ bi asa tiwa lapa ihinyi, lẹhin igbati enia ba ri ilẹ na tan, enia yio sán gbogbo igbó ati koriko to wa lori ilẹ na kuro, ani eniyan yio palẹ̀ ilẹ na mọ lati mura ilẹ na silẹ fun isẹ miran ti enia yio tun se lori rẹ. Bí igi ba wa lori ilẹ nã, eleyi to le è se tánnàdí fun idagbasoke irugbin ti enia fẹ gbìn sinu ilẹ na, enia yio ge igi na, ni ọpọ ìgbà iru awọn igi wọnyi ma ndi píparun lori ilẹ nã.

Lẹhin eleyi ni agbẹ na yio wa kọ ilẹ tabi ki o gba awọn alagbase lati ba kọ ebè ilẹ na ki o le gbin ohun na sinu ebè nã.

(2) ESO NÃ: Awọn eso ti enia fẹ gbìn sori ilẹ na, eniyan yio wa awọn eso na, awọn tó bá yẹ ni rírà, eniyan yio ràá, eniyan tabi agbẹ na yio si ri daju wipe oun ra eso eleyi tó tó lati gbìn sinu oko nã, ani sori awọn ebè nã.

Lẹhin igbati enia ba ti ri awọn èso wọnyi tan, awọn agbẹ yio tun wa gbe awọn eso wọnyi wò lati ri daju wipe wọn ni ìyè ninu. Lara awọn ọna ti awọn agbẹ ma nlo ni lati wo eso na daradara, tó bá jẹ eleyi tó ti jẹ tabi ju tabi to ti jẹrà, o han wipe iru eso bẹ́ẹ̀ ko ni dara ti wọn ba gbìn-ín, nitorina, awọn agbẹ yio ya awọn eso wọnyi sọtọ kuro lara awọn eleyi ti wọn fẹ gbìn.

Lehin eleyi, awọn tó kù wọn le dà á sinu omi, nigbati wọn ba dà á sinu omi, wọ́n mọ̀ wìpe awọn eleyi tó bá ti lọ si isalẹ omi na, ani awọn eleyi to ba ti rì sinu omi na, awọn eso wọnyẹn jẹ eleyi to dara fun gbígbìn, sugbọn, awọn eleyi ti wọn ba ti fò leke omi, ọpọ awọn wọnyẹn ni ko ni iye ninu mọ, wọn kò sì dara fun gbíngbìn, nitorina, awọn agbẹ yio ko wọn sọtọ kuro lara awọn eleyi ti wọn fẹ gbìn.

(3) GBÍNGBIN ESO NÃ: Ohun ti a ó gbìn yi nilati jẹ eleyi to ni iye ninu, ki ise eleyi tó ti kú tabi ti iye rẹ ti sọnu. Ìyè ohun na nilati wa ninu rẹ sibẹsibẹ̀ ki a to gbìn-ín. Eleyi lo fàá ti awọn àgbẹ̀ se ma nse iwadi lati mọ boya nkan ti awọn fẹ́ gbìn ni iye ninu tabi kò ni iye ninu kótó di wipe wọn yio gbìn-ín, nitori wọn mọ wipe ti awọn bá gbìn ohun (eso) ti kò ni iye ninu, nse ni awọn se àsedànù, nse ni awọn bun ilẹ̀ ni eso na nitoripe yio kú nigbato ba de inu ilẹ ni, ko si ni sọ sita. Gbingbin nkan ma nwaiye nigbati a ba ti irugbin na bọ inu ilẹ. Eredi ti a se ma nti awọn irugbin wọnyi bọ inu ilẹ ni ki awọn ẹranko ma ba jẹ wọn tan, ki enia o ma ba se asedanu. Sugbọn bi wọn fi irugbin silẹ lasan, ti wọn ko ti bọnu ilẹ, ti ẹranko ko ba ti dà á lamu, irugbin na yio hù jade nigbato báyá.

(4) IRUGBIN INU ILẸ: Irugbin ti a gbin sinu ilẹ ni asiko to fi wà ninu ilẹ na, yio ma mu omi, tobẹ ti yio fi sọ iye rẹ danu, eleyi ni wipe yio ku, nitoripe gbogbo ohun to wa lara irugbin tabi eso na ni yio di lilo patapata ninu ilẹ na ti irugbin na yio si wá bẹrẹ sini yọ jade."Lotọ, lotọ ni mo wi fun yin, bikosepe wóró alikama ba bọ silẹ, ti o ba si kú, o wà oun nikan; sugbọn bi o ba ku a si so ọpọlọpọ eso" (Jhn 12:24)

(5) IRUGBIN TO TI SỌ JADE: Bi irugbin na ba ti sọ jade, yio bẹrẹ sini fa omi ati awọn ohun ti yio mu dagba lati inu ilẹ, bẹna ni yio si tun ma gba oòrùn sara lati fi le pèsè ounjẹ fun ara rẹ, eleyi ti yio si mú u dàgbà.

(6) BÍ ASE NMỌ̀ WIPE NKAN NDAGBA: Irugbin eleyi to ti sọ jade latinu ilẹ yi, enia yio ma wò ó lojojumọ, bi enia ba si ti nwò ó, enia yio ri wipe ayipada nde ba ohun nã. Irugbin tó ga niwọn bata kan silẹ tẹlẹ diẹdiẹ, yio ga niwọn bata meji silẹ abbl. Nipasẹ ayipada to se fojuri fun eniyan yi na ni a se ma nsọ wipe nkan ndagba.

(7) ESO SISO: Nigbato ba ya, irugbin ti a nwo to n ni ayipada yi, yio dé opin idagbasoke rẹ, lehin eleyi yio bẹrẹ sini so eso nipasẹ eleyi ti yio fi ma mu owo wa fun agbẹ na, tabi ki agbẹ na má a jẹ ẹ́, nipasẹ eso yi na ni agbẹ na yio se tun ri omiran gbin lọdun miran tó bá tun fẹ gbìn irufẹ eso na. 


ENIYAN (ẸRANKO) BI APẸRẸ IDAGBASOKE: Iru awọn ipele oke ti a wo fun irugbin na ni ẹranko tabi eniyan na ma nla kọja, nipasẹ eleyi ti a o fi sọ pe ẹni na ndagba.

Obinrin tabi abo ẹranko yio kọkọ lóyún, lẹhin idàpọ pẹlu ọkunrin tabi akọ. Oyún na yio ma dagba...nigbati osu oyun na bá pé abo na yió bi ọmọ na. Ọmọ ti abo yi bi yio kọkọ́ wà ni ìkókó, lẹhin eleyi yio ma rákò, lẹhin eleyi yio ma dagba titi ti kò fi ni le ga mọ́. Lasiko ti ayipada nde ba àgọ́ ara rẹ yi, ohun ti awọn eniyan yio ma sọ nipa rẹ na ni wipe ọmọ na tabi eniyan na, tabi ẹranko na ndàgbà.:)Sugbọn lẹhin igbati enia na bá ti dé opin gíga, nipa ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye ti enia ni ni a ma fi nsọ nipa idagbasoke iru ẹniyi.

Awọn enia a tún ma fi bi eniyan se lọ́rọ́ tabi lówó lówó abbl si na sọ nipa dídàgbà ẹni na, sugbọn idagbasoke iru eleyi kò kó ohun gbogbo tán na ni eleyi to nise pẹlu ọgbọn, imọ ati oye ẹni na. Njẹ a ha le è sọ nipa iwọ oluka iwe mi yi nã wipe o ndagba? Tó bá jẹ idagbasoke nipa owó, iye ile ti o kọ́, iye ọkọ̀ ti o rà, iye iyawo ti o ni, iye ọmọ ti o bi abbl ni a fi nsọ wipe o ndagba, idagbasoke na kò kó ohun gbogbo já, idagbasoke eleyi to nise pẹlu ohun gbogbo ninu aiye ati ninu eniyan ni idagbasoke to dara julọ.

"Ọgbọn ti kọ ile rẹ, o si gbẹ ọwọ̀n rẹ meje...."Nitoripe nipasẹ mi (ọgbọn) ni ọjọ rẹ yio ma lé sí i, ati ọdun iye rẹ yio si ma le sí i" (Owe 9:1,11)

"Idahun pẹlẹ́ yi ibinu pada: sugbọn ọrọ lile ni iru ibinu sokè:)"Ahọn ọlọ́gbọ́n nlo imọ rere: sugbọn ẹnu asiwere a mã gùfẹ̀ were" (Owe 15:1-2)

"Ọgbọn ni a fi íkọ ile; oye ni a si fi nfi idi rẹ kalẹ.

"Nipa imọ ni iyara fi nkún fun oniruru ọrọ̀ iyebiye ati dídùn:)"Ọlọgbọn eniyan ni agbara: nitotọ eniyan ìmọ̀ a sọ agbara rẹ di pupọ.

"Nitori nipa igbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi segun rẹ: ati ninu ọpọlọpọ ìgbìmọ̀ ni isẹgun:

"Ọgbọn ga ju asiwere lọ: oun ki yio ya ẹnu rẹ ni ẹnubode (Owe 24:4-7)

Aposteli Jakọbu mọ isepataki ọgbọ́n, nitorina, o gba eniyan/onigbagbọ niyanju lati bere fun ọgbọn lọwọ Ọlọrun:)"Bi o ba ku ọgbọ́n fun ẹnikẹni, ki o bere lọwọ Ọlọrun, ẹniti i fi fun gbogbo eniyan ni ọpọlọpọ, ti ki isi i baniwi; a ó si fifun-un" (Jak 1:5)



ORÍ KẸRIN

ÌGBÀGBỌ GẸGẸ BI IRUGBÌN

Ni ori kẹta, a ti wo itumọ ki nkan o dagba, bẹni a sì se awọn akawe eleyi to le mu ki itumọ ọrọ na, dídàgbà ba le yé wa. Irugbin ni a lo lati fi salaye nkan didagba fun wa. Jesu pẹlu fi (ọrọ) ìgbàgbọ we irugbin nigbati o wipe, 

"Oluwa si wipe, bi ẹyin ba ni igbagbọ bi wóro irugbin mustardi, ẹyin o le wi fun igi sikaminre yi pe, ki a fa ọ tu, ki a si gbin ọ sinu oọkun; yio si gbọ ti nyin" (Lk 17:6)

Jesu lo nda awọn ọmọẹhin rẹ lohun nihinyi, nigbati awọn ọmọ-ẹhin Rẹ mbẹ Ẹ wipe kò bùsi igbagbọ won.

"Awọn aposteli si wi fun Oluwa pe, busi igbagbọ wa" (Lk 17:5)

Ẹ̀kọ́ ti Jesu Kristi sẹ̀sẹ̀ kọ awọn niyan na ló yà wọn lẹnu tóbẹ́ẹ̀ ti wọn fi ro wipe igbagbọ ti awọn ní kòle se ohun ti Jesu Kristi ọga ati Olukọ awọn nkọ wọn yi. Kini ẹkọ na? Ẹkọ na ni ẹ̀kọ́ ìdariji patapata, didariji ẹnikẹni tó bá sẹ̀ wọn. Awọn aposteli ati awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti wọn ti kọ ẹkọ woli Mose tó sì ti yé wọn yegeyege, ki ise wipe ẹkọ yi yé wọn nikan, sugbọn wọn nmu ẹkọ na lo gidigidi saju sise alabapade Jesu ati gbogbo ẹkọ rẹ.

"Ẹyin ti gbọ́ bi a ti wipe, oju fun oju, ati ehín fun ehín" (Mt 5:38)

Eleyi ni irú ẹkọ́ ti a ti kọ wọn latinu ofin woli Mose wa, ẹkọ gbígba ẹsan, ẹkọ sisan-an pada fun ọta gẹgẹbi o ti se si eniyan. Sugbọn Jesu wa nwi fun wọn wipe iru ẹkọ na kọ́ ni oun múwá bikosepe oun mu ẹ̀kọ idariji wa. 

Ẹkọ idariji Jesu yi kà wọ́n láyà tobẹ ti wọn fi wo wipe igbagbọ ti awọn ni ko iti de ikorita yẹn, igbagbọ ti awọn ni kole fi ayè ìyẹn silẹ, wọn wa bere wipe, ki Ọlọrun sọ igbagbọ awọn di pupọ sí i, ki Ọlọrun fun awọn nigbagbọ to le è fi àyè gba iru ọrọ to sọ yi.

A ó ri wipe awọn ọmọ-ẹhin kò le se alaima bẹ̀bẹ̀ fun eleyi lọdọ Ọlọrun nitoripe, Jesu kò tun sọ wipe ki wọn o dariji ẹnito ba sẹ̀ wọn lẹkan, sugbọn o wipe kódà to bá se ìgbà meje lójúmọ́ ló sẹ̀ wọn, ohun ti wọn nilati se ni wipe nigba mejeje na to bá pada wa sọdọ wọn fun idarji na ni ki wọn o dariji ẹni na.

"Ẹ ma kiyesara yin: bi arakunrin rẹ ba sẹ̀, bá a wi; bi o si ronupiwada, dariji i:

"Bi o ba si sẹ̀ ọ́ ni igba meje ni òòjọ́, ti o si pada tọ̀ ọ́ wá ni igba meje ni oojọ pe, mo ronupiwada, dariji i" (Luku 17:3-4)

A ó ri wipe ẹ̀kọ́ idariji to lagbara ni, pãpã fun iru wọn ti wọn kò mọ nipa idariji tẹlẹ, sugbọn ti a ò sọ fun wọn wipe ki wọn o dariji lẹkan, sugbọn ki wọn o fi gbogbo ìyókù gbẹsan, Jesu kò sọ wipe ki wọn o ma dariji diẹdiẹ, sugbọn o wipe ki wọn o ma dariji patapata, ki wọn o ma dariji ni gbogbo ìgbà, ki wọn o jẹ ki idariji o di omi ati ẹjẹ ara wọn.

Ẹkọ na lagbara, awọn aposteli pẹlu si mọ wipe igbagbọ awọn wẹ́ (kéré) siru ẹkọ na, ipele ti igbagbọ awọn wà ko i ti de iru ipele ti Jesu nsọ yi, nitorina wọn bẹ̀ ẹ́ lati busi tabi fikún igbagbọ wọn.

"Njẹ mo wi fun olukuluku eniyan ti o wa ninu yin, nipa ore-ọfẹ ti a fifun mi, ki o mase ro ara rẹ ju bi o ti yẹ ni rírò lọ: sugbọn ki o le rò ó niwọntunwọ̀nsìn, bi Ọlọrun ti fi ÌWỌ̀N ÌGBÀGBỌ́ fun olukuluku" (Rm 12:3)

Awọn aposteli ri wipe ìwọ̀n igbagbọ awọn kere si ọrọ Jesu nã, nitorina, wọn bẹ Jesu ọna ti ìwọ̀n ìgbagbọ wọn yio fi lòkè sí i.

Jesu Kristi na wa nsalaye fun wọn wipe ọna ti igbagbọ wọn le gbà gbé ìwọ̀n sí i ni ki wọn o ni igbagbọ eleyi to dabi ti hóró irugbọn mustardi. Ni ede miran, Jesu Kristi nsọ fun wọn wipe igbagbọ to nse iru ohun ti Oun nsọ yi jẹ igbagbọ eleyi to ndagba, o jẹ igbagbọ to ngòkè sí i, eleyi ni wipe ki ise ẹbun igbagbọ ni yio se iru isẹ yi, bikose eso igbagbọ, ani igbagbọ ti a o gbin ti yio yọ jade, ti yio hù jade ti yio si bẹrẹ sini dagba.

"Ati fun ẹlomiran (ẹ̀bùn) igbagbọ nipa Ẹmi kanna" (I Kọri 12:9a)

Ẹbun igbagbọ ki ise igbagbọ to ndagba. Ẹbun igbagbọ ma nfarahan ninu igbagbọ to ndagba, eleyi ni wipe ninu igbagbọ to ndagba ni ẹbun igbagbọ wa, sugbon ẹbun igbagbọ gãn kọ́ ni igbagbọ to ndagba. Fun apẹrẹ, gẹgẹ bi ati nlo eso lati fi salaye nkan to ndagba, a ri wipe ti a ba gbin èso, yio hù, yio si di ewebẹ̀ tabi igi nla. Ohun miran ni wipe lara igi yi, a le ri ohun miran mu jade ti yio wúlò fun ẹni na yàtọ̀ fun ohun pato ti a se itori rẹ gbin ohun na. Ninu iwe woli Isaiah a ri kà wipe ọba Hesekiah se àìsan, àìsan na pọ̀ jọjọ tobẹ to jẹ wipe ọba na ìbá bá àìsàn nã lọ. Sugbọn nigbato wá ojú Oluwa, Oluwa wi fun pe aisan na ki yio pa á, ati wipe oun Ọlọrun yio wò ó san. Lẹhin igbati a sọ eleyi ni woli Isaiah wa wi fun ọba na pe kó mú ìsù ọ̀pọ̀tọ́ ko fi le oówo tó wà ni ara rẹ wipe oówo nã yio si kuro, wipe yio gba alafia lẹhin igbati o ba ti fi isù ọpọtọ na lé oju (ori) oówo nã.

"Nitori Isaiah ti wipe, ki wọn mú isu ọpọtọ, ki a si fi si oówo nã, yio si sàn" (Isa. 38:21)

Nigbati awọn enia na gbọ ọrọ woli nã, wọn si se gẹgẹbi o ti se sọ, oówo na si kuro, ara ọba na si yá.

"Isaiah si wipe, mu isu ọpọtọ. Wọn si mu u, wọn si fi le oówo nã, ara rẹ si dá"  (II A. Ọba 20:7)

Ohun ti mo fẹ mu jade lati ihinyi ni wipe, a nlo igi ọpọtọ fun nkan miran yatọ fun wíwo oówo san.

Ẹ jẹ ka wo iwe Onidajọ lati ri wipe ọ̀pọ̀tọ́ tun ni ohun miran to nse yàtọ si wiwo oówo san nikan.

"Sugbọn igi ọpọtọ wi fun wọn pe, emi le fi adun mi silẹ, ati eso mi daradara, ki emi ki o si wá se olori awọn igi" (Ond 9:11)

Oniruru nkan miran ni igi ọpọtọ tún wulo fun yàtọ si wiwo èso oówo sàn. Bẹna ni igbagbo to ndagba ti se ri, lara awọn ohun to tun ma nfarahan ninu igbagbọ tó ndagba na ni "ẹ̀bùn igbagbọ" gẹgẹbi aposteli Paulu se sọ ninu iwe Kọrinti ori kejila ẹsẹ kẹsan yi. 

Ẹbun igbagbọ yi wulo fun isẹ ami ati isẹ iyany sise pupọ. Nipasẹ ẹbun igbagbọ yi, ọpọ eniyan yio ri iwosan, nipasẹ ẹbun igbagbọ yi ipese ma nwaiye lasiko ìyàn tabi àìní. Jesu lo ẹbun yi lasiko to mbọ ẹgbẹgbẹrun eniyan, woli Elisa na lò ó lati pese fun awọn ọmọ woli lasiko iyan(Mk 8:1-9; II A. Ọba 4:42-44)

"Elisa si tun pada wa si Gilgali, iyan si mu ni ilẹ na;.."Ọkunrin kan si ti Baali-Salisa wá, o si mu akara àkọ́so èso, ogun isu akara ọka barle, ati siri ọka titun ninu apo rẹ wa fun eniyan Ọlọrun nã. Òun si wipe fi fun awọn eniyan, ki wọn ki ó lè jẹ́."Iransẹ rẹ si wipe, kinla, ki emi ki o gbe eyi ka iwaju ọgọrun enia? Oun si tun wipe, fi fun awọn eniyan, ki wọn ki o le jẹ: nitori bayi ni Oluwa wipe wọn o jẹ, wọn o si sẹ́kù silẹ."Bẹni o gbé e ka iwaju wọn, wọn si jẹ, wọn si sẹku silẹ, gẹgẹ bi ọrọ Oluwa" (II A. Ọba 4:38a, 42-44)

Ẹbun igbagbọ yi farahan ninu igbagbọ to ndagba ni. Eleyi ni wipe, ẹniti ẹbun igbagbọ yi yio jẹ jade lati ọdọ rẹ, yio ti kọkọ́ ni irugbin igbagbọ to ndagba ninu aye rẹ.

Nitorina, nigbati awọn ọmọẹhin Jesu wipe, bùsí igbagbọ wa, Jesu wa sọ fun wọn wipe igbagbọ to ndagba gidigidi ni wọn nílò fun irú ohun ti oun nsọ yi, igbagbọ to ndagba leniyan nilo lati gbé ninu aiye ati lati ni ododo to ju ti awọn Farisi ati Sadussi lọ.

"Nitori mo wi fun yin, bikosepe ododo yin ba kọja ododo awọn akọwe ati ti awọn Farisi, ẹnyin ki yio le de ijọba ọrun bi o ti wù ki o ri" (Mt 5:20)



IRÚGBÌN MÚSTÁRDÌ

Ẹ jẹ ká wo bibeli fun ohun ti irugbin mustardi jẹ ni Ilẹ Israeli.

KÍNNI IRÚGBÌN MÚSTÁRDI? Iwe ihinrere ti Matteu 13:31-32 fun wa ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ idahun nipa ohun ti irugbin yi jẹ.

"Owe miran ni o (Jesu) pa fun wọn wipe, ijọba ọrun dabi woro irugbin mustardi kan, eyiti ọkunrin kan mu ti o si gbìn sinu oko rẹ:

"Eyiti o kere ju gbogbo irugbin lọ; sugbon nigbati o dagba, o tobi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, o si di igi, tóbẹ́ẹ̀ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun sì wá, wọn ngbe ori ẹka rẹ".

Awọn agbagba ninu igbagbọ ti wọn ti lọ si ilẹ Israeli ri, nigbati wọn ba msọrọ nipa irugbin mustardi yi fun wa nigbati a wà ni kekere wọn a fi we irugbin ọkà-bàbà nitoripe irugbin yi lo fẹrẹ kere julọ ni apa ilẹ Yoruba nihinyi.... Sugbọn lọjọkan, èmi na se alabapade irugbin yi, ó sì hàn gbangba wipe o tun kere ju irugbin ọka-bàbà yi lọ.... Lati inu ọrọ Jesu, a ri gbangba wipe, irugbin yi, mustardi, lo kere julọ ninu awọn irugbin to mbẹ ni ilẹ Israeli. Sugbọn, ohun iyalẹnu ni wipe, tòhun ti bi irugbin yi ti se kere to yi, bi eniyan ba gbìn-ín, ti o ba si hù jade, ti ohunkohun kò bá si se é bi o ti se hù u ni, a mã di igi nla ti yio si tun ni ẹka, lara awọn ẹ̀ka wọnyi, awọn ẹiyẹ oju ọrun a mã wa sibẹ̀, wọn a si mã kọlé sibẹ pẹlu. Awọn ẹranko miran bí i ọkẹ́rẹ́ a mã gun ori rẹ lati jẹun níbẹ̀, o hàn wipe tó bá wa larin inu igbo, awọn ẹranko bí i ọbọ le è gun ori rẹ nã. Bi irugbin na ti kere tó o nì, sibẹ, ó tún le è di igi nla.:)Iru ohun ti Jesu fi igbagbọ to ma ndagba ninu aye eniyan wé ni eleyi. Eleyi ni wipe igbagbọ to ma ndagba yio kọ́kọ́ wà gẹgẹbi irugbin to kere ninu aye eniyan, lẹhin igbati a ba ti gbìn-ín sinu aye eniyan, yio wa ẹrẹ sini dagba diẹ-diẹ titi ti yio fi di nla gidigidi ninu aye ẹni na, yio di nla gidigidi tobẹ ti yio le fi ààyè gba nkan miran lati fi ara tì í, eleyi ni wipe awọn onigbagbọ kekere yio le fi ara tì í, yio jẹ àbò fun awọn onigbagbọ kekere, yio jẹ ipese fun wọn, yio jẹ ibiti wọn le kọle si tabi má a gbe, yio jẹ ibiti wọn le mã bímọ si gẹgẹ bi ẹiyẹ ti se ma nbimọ sori igi.

Eleyi nikan kọ, nigbati irufẹ igbagbọ yi ba dagba daradara, yio tun so eso nipasẹ eleyi ti iru igbgbọ yi yio fi tàn kalẹ. Gẹgẹbi eniyan tise nmu irugbin mustardi lati ibikan lọ si ibomiran lati lọ gbìn-ín, bẹna ni igbagbọ to ndagba yi nigbati o ba ti dagba gidi yio di eleyi ti a nmu lati ibikan lọ si ibomiran lọ gbìn sibẹ.

ỌNA TI IRU IGBAGBỌ YI MA NGBA WA

Lara awọn ọna ti iru irugbin igbagbọ yi ma ngba wa niwọnyi:


(1) NIPA GBIGBỌ ỌRỌ ỌLỌRUN:

"Njẹ nipa gbigbọ ni igbagbọ ti nwa, ati gbigbọ nipa ọrọ Ọlọrun" (Rm 10:17)

Jesu pẹlu fi ọrọ Ọlọrun we irúgbìn, nigbati O si fi aye (ọkan) eniyan we ilẹ̀. Sugbọn oniruru ilẹ ló wà. Jesu wipe awọn ọkàn miran dàbí ẹ̀bá-ọ̀nà; awọn miran dabi apata, eleyi ti ko ni erupẹ púpọ; aye miran si dabi ilẹ̀ ẹlẹ́gun; nigbati ọkàn miran jẹ ọkàn ilẹ̀ rere. (Mt 13:3-8,19-23; Mk 4:3-8,14-20)

Gbogbo awọn aye tabi ọkan wọnyi ló gbọ́ ọrọ Ọlọrun, eleyi ni wipe, a fún irugbin ọrọ igbagbọ na si awọn orisi aye mẹrin wọnyi, sugbọn eleyi to se daradara julọ ninu gbogbo wọn ni irugbin eleyi tó bọ́ si ilẹ̀ rere. Irugbin igbagbọ tó bọ́ si ilẹ rere yi lo ni ohun gbogbo tó yẹ fun idagbasoke rẹ tó si mu awọn ohun na lò titi ti o fi di nla gidigidi, to si bẹrẹ sini iso èso. Nipa gbigbọ ọrọ Ọlọrun ni a se nfún irugbin igbagbọ to ndagba yi sinu aye eniyan. Iru ọrọ wo lo ha yàn lãyo? Ọrọ Ọlọrun ni tabi ọrọ eniyan? Ọrọ Ọlọrun ni tabi ọrọ aiye? Igbagbọ ko le wa nipa ọrọ eniyan, igbagbọ ko le wa nipa gbigbọ ọrọ aiye. Nigbati eniyan ba ngbọ ọrọ aiye tabi ọrọ esu, ejo laelae ni, ohun ti eleyi ma nfi sinu aye eniyan ni ìgbàgbé. Bi eniyan ba se ngbọ ọrọ aiye sí i, bi eniyan ba se ngbọ ọrọ esu si i, bẹni eniyan yio ma gbagbé Ọlọrun sí i, ti eniyan yio si má a yan esu ati isẹ ọwọ rẹ lãyo sí i.

Nigbati Efa ati Adamu gbọ ọrọ ejo ni, nigbana ni a fún irugbin igbàgbé sinu aye wọn, wọn gbàgbé Ọlọrun, wọn si nranti ohun tise ti esu nigbagbogbo. (Gen 3) Nipasẹ wọn na ni awa na se gbagbe Ọlọrun loni, ti awa na si nranti esu ninu ohun gbogbo ti a nse. Kò si ẹniti o ma nkọ ọmọde bi ati se nsepe, kosi ẹniti o nkọ ọmọde bi ati se njale, ko si ẹniti nkọ ọmọde bi ati se nse ipata, sugbọn nitoripe ati fun irugbin igbagbe Ọlọrun sinu aye awọn baba nla wa, eleyi ti awa pẹlu jogun, a o ri wipe nse ni a o ba awọn ọmọ wọnyi ti wọn nse ohun wọnyi kódà lati kekere wọn lọ.:)Nigbati Judasi Iskariotu bẹrẹ sini gbọ ọrọ awọn eniyan, ọrọ awọn agbagba Farisi ati Sadussi ati awọn Akọwe, nigbana ni igbage wọle, igbagbe wọnu aye rẹ, irugbin igbagbe na si fún irugbin igbagbọ to mbẹ ninu rẹ tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀ pa. (Mt 27:9; 26:15; Jhn 12:4-6; 13:2; Lk 22:3-5)

Iru ọrọ wo niwọ na ngbọ? Bí o bá ngbọ ọrọ eniyan, esu, aiye, ẹran ara, wã mã gbagbe Ọlọrun sí i, sugbọn bi o ba ngbọ ọrọ Ọlọrun, irugbin igbagbọ yio wa ninu rẹ, eleyi ti yio si ma dagba sí i.

(2) NIPA KIKA ỌRỌ ỌLỌRUN: Aposteli Johannu ninu iran rẹ to ri ni erekusu Patimosi sọ wipe

"Olubukun ni ẹniti nka, ati awọn ti o ngbọ ọrọ isọtẹlẹ yi, ti o si npa nkan wọnni ti a kọ sinu rẹ mọ; nitori igba ku si dẹdẹ̀" (Ifi 1:3)

Woli Mose ninu iwe karun rẹ Deuteronomi na wipe,

"(Iwe ofin yi) Yio si wà lọdọ rẹ, oun o si ma ka ninu rẹ ni ọjọ aye rẹ gbogbo: ki o le mã kọ ati bẹru OLUWA Olọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọrọ ofin yi mọ ati ilana wọnyi, lati ma se wọn" (Deut 17:19)

Ninu iwe woli Danieli ni a ti ri wipe lẹhin igbati woli Danieli ka akọsilẹ woli Jeremiah niti iye ọdun ti awọn eniyan Israeli ati Juda yio lo ni igbekun to si ri wipe akoko ti Ọlọrun sọ ti pe, o bẹrẹ sini gbadura fun itusilẹ awọn enia rẹ.

"Ni ọdun kinni ijọba (Dariusi ọmọ Ahaswerusi) rẹ ni emi Danieli fiyesi, lati inu iwe, iye ọdun, nipa eyiti ọrọ Oluwa tọ Jeremiah woli wa, pe adọrin ọdun ni Oun o mu pe lori idahoro Jerusalemu.

"Emi si kọju mi si Oluwa Ọlọrun, lati ma safẹri nipa adura ati ẹbẹ pẹlu awẹ, ninu asọ-ọfọ, ati eérú" (Dan 9:2-3)

Nipa kika ọrọ Ọlọrun, irugbin igbagbọ a mã bọ si ilẹ̀ aye eniyan, nigbati ilẹ nã bá sì jẹ ilẹ rere, irugbin nã yio hù jade ti yio si bẹrẹ sini dagba titi ti yio fi dagba gidigidi.

Ọrọ Ọlọrun ti a nsọ wipe ki eniyan tabi onigbagbọ o ma ka na ni Bibeli Mimọ, ninu iwe ti akọsilẹ awọn woli wa, ọrọ orin ati ewi wa nibẹ; ọrọ ihinrere wa nibẹ abbl. Aposteli Paulu sọ niti iwe Mimọ wipe, 

"Gbogbo iwe mimọ ti o ni imisi Ọlọrun ni o si ni ere fun ẹ̀kọ́, fun ibaniwi, fun ìtọ́ni, fun ìkọ́ni ti o wa ninu ododo."Ki eniyan Ọlọrun ki o le pe, ti a ti mura silẹ patapata fun isẹ rere gbogbo" (II Tim 3:16-17)

NIPA ADURA (BIBERE):

Ninu iwe Luku 17 yẹn, a ri wipe awọn aposteli sọ fun Jesu wipe ki o busi igbagbọ wọn, ni ede miran awọn aposteli nsọ wipe ki Jesu o mu igbagbọ wọn dagba sí i. Nipa gbigbadura si Ọlọrun, irugbin igbagbọ yi, Ọlọrun a mã fi fun eniyan nitori Jesu wi ninu iwe ihinrere Matteu 7:7 wipe, "Bere, a o si fi fun yin; wa kiri, ẹyin o si ri; kankun, a o si sí i silẹ fun nyin.

"Nitori ẹnikẹni ti o bere nri gbà; ẹniti o a si wa kiri nri; eniti o ba si nkankun, ni a o si i silẹ fun" (Mt 7:7-8)

Ti a ba gbe awọn igbesẹ adura wọnyi; bibere, wiwa kiri ati kikan ilẹkun, Ọlọrun yio fun wa ni iru igbagbọ to ndagba yi, yio fi irugbin igbagbọ na sinu wa, ti yio si mã dagba lọ.

"Ohunkohun ti ẹyin ba si bere ni orukọ mi, oun na ni emi o se, ki a le yin Baba logo ninu ọmọ.

"Bi ẹyin ba bere ohunkohun ni orukọ mi, emi o se e" (Jhn 14:13-14)

"Ati ni ijọ́ na ẹyin ki yio bimi lere ohunkohun, Lotọ, lootọ ni mo wi fun nyin, ohunkohun ti ẹyin ba bere lọwọ Baba ni orukọ mi, Oun o fi fin yin.

"Titi di isinsinyi, ẹ ko i ti i bere ohunkohun ni orukọ mi: ẹ bere, ẹ o si ri gba, ki ayọ yin ki o le kún" (Jhn 16:23-24)

Aposteli Johannu ninu awọn akọsilẹ oke yi jẹ ko ye wa wipe, a ò ni le gbe awọn igbesẹ adura wọnyi ti a ò ba lo orukọ Jesu. Nipa orukọ Jesu ni a fi le gbe gbogbo awọn igbesẹ wọnyi, nipasẹ orukọ Jesu ni a fi le bere lọwọ Ọlọrun ki a si rí gbà; nipasẹ orukọ Jesu ni a fi le wa kiri ki a si ri; nipasẹ orukọ Jesu ni a fi le kan ilẹkun ki o si di sísí silẹ fun wa, ti a ó si wọnu igbagbọ nla lọ. Aposteli yi, Johannu, wa ntẹnumọ wipe nigbati a bá ri awọn nkan ti a mbere gba tan, eleyi yio fun wa ni ayọ̀ kíkún. Nigbati agbẹ ba lọ si oko to si gbin nkan sinu oko sugbọn ti awọn irugbin tó fún sinu oko nã ko ba hù, inu agbẹ na ko ni dun, agbẹ na yio wa ninu ibanujẹ.... Ni idakeji ẹ̀ẹ̀wẹ̀ bi awọn ohun ti agbẹ nã bá gbìn bá hù daradara, inu agbẹ na yio dùn, ayọ agbẹ na yio kun, nitoripe awọn irugbin tó fún sinu oko rẹ na sọ jade, o si mọ wipe bi ojo ba rọ daradara, ti oun tun roko si awọn irugbin na laipẹ jọjọ oun yio bẹrẹ sini kórè awọn ohun ti oun gbìn nã, oun yio bẹrẹ sini jẹ ninu isẹ ọwọ́ oun.

Bẹna lo ti se ri nigbati irugbin igbagbọ eleyi ti Ọlọrun fi sinu wa ba bẹrẹ sini hù, inu awa na yio dùn, nitoripe a ó mọ iyatọ rẹ lara wa. Ọna wo ni a o fi mọ iyatọ nã? Lara awọn ọna ti a ó gbà mọ iyatọ nã ni wipe, a ó bẹrẹ sini ri wipe awọn ohun ti kò rọrun fun wa lati se ninu igbagbọ tẹlẹ, a o bẹrẹ sini se wọ́n pẹlu ìrọ̀rùn, eleyi to jẹ wipe lẹhin igbati a bá se wọn tan yio ya wa lẹnu, iyalẹnu yi yio fun wa ni ayọ̀ eleyi ti ọkan wa yio fi kun fun ọpẹ́ si Ọlọrun ti ete wa yio si mã yin In.

ORÍ KARUN

IDÀGBÀSÓKÈ IRUGBÌN ÌGBÀGBỌ́

Lẹhin igbati àgbẹ̀ bá ti ni ayọ̀ wipe awọn irugbin ti oun fọ́n tabi gbìn sinu oko oun ti bẹrẹ̀ sini hù, ifojusọna ati erongba àgbẹ̀ na lojojumọ ni wipe ki irugbin na o mã dàgbà sí i....Gẹ́gẹbi mo ti se lo eniyan fun apẹrẹ ni ori kẹta iwe yi, ẹ jẹ ki ntun lo eniyan na lati salaye ọrọ yi. Nigbati obinrin kò bá ri nkan osù rẹ mọ ti o si sọ fun ọkọ rẹ wipe oun ko ri nkan osu oun mọ, eleyi tó túmọ̀ si wipe ó ti fẹ́-ara-kù tai wipe o ti loyun, a o ri wipe inu awọn mejeji, ọkọ ati aya, yio dùn pãpã jùlọ ti ki iba ise wipe wọn loyun agbere tabi oyun pansaga. Ẹ̀ẹ̀wẹ̀ lẹhin igbati eleyi ti sẹlẹ ti inu wọn si ti dùn, nse ni awọn mejeji yio jijọ mã foju sọna fun idagbasoke ati ayipada eleyi ti yio ma de ba oyun na, sugbọn ti idagbasoke tabi ayipada kò bá sí, inu awon mejeji ko ni dùn, awọn mejeji yio si mọ wipe nkan ti ko dara kan ti sẹlẹ si oyún nã. Bẹna ni irugbin igbagbọ eleyi ti o ti hù jade ni ilẹ inu aye wa yio ti bẹrẹ sini fun wa ni ayọ nigbati a rí i tó hù jade, sugbọn, lẹhin ayọ̀ isaju yi, nitori híhù jade ti irugbin na hù jade, ko ni dabi nkankan mọ́ nigbati irugbin na ba kùnà lati mã dàgbà sókè sí i.

Lati mu ki irugbin ti agbẹ gbìn sinu oko rẹ o mã dagba si, agbẹ na ni ojuse tirẹ lati se, bẹna ni Ọlọrun na yio ma se ojuse tirẹ.



OJUSE TI ỌLỌRUN:

(1) SÍSE ÀKÓSO ÌGBÀ:

Ò ní ipa ti igba kọkan ma nko lara didagbasoke irugbin. Gbogbo ìgbà ati asiko wọnyi Ọlọrun lo nsakoso rẹ.

"Niwọn igbati aiye yio wà, igba irugbin, ati igba ikore, igba otutu ati ooru, igba ẹ̀rùn oun òjò ati ọ̀sán ati oru, ki yio dẹkun" (Gen :22)

Ojuse ti Ọlọrun ni lati mã mojuto gbogbo igba wọnyi, o si nse e lati mu itura wa ba aiye ati olugbe inu rẹ.

(2) RÍRỌ ÒJÒ

Bi agbẹ ba gbin nkan sinu oko, irugbin na nilo omi ki o ba le hu jade, ati ki o ba le dagba. Ki aiye o tó di aiye igbalode, eleyi ti awọn onimọ ijinlẹ npe ni sayẹnsi ti mún ọgbọ́n ati mã bu omi si nkan ọgbin jade, òjò lati ọdọ Ọlọrun ni ọpọ agbẹ ma nduro de. Bi aiye ti se di aiye igbalode to, sibẹ ọ̀pọ̀ agbẹ ni apa iwọ oòrùn Naijiria ojo lati ọdọ Ọlọrun ni a mã nduro de fun híhù ati didagbasoke awọn irugbin oko wa gbogbo. Òjò ti a wá nsọrọ rẹ yi, Ọlọrun nikan lo le rọ ojo fun eniyan.

"Ki ẹnyin ki o le má a jẹ ọmọ Baba yin ti o mbẹ ni ọrun; nitoriti o nmu oòrùn rẹ ran sara eniyan buburu ati sara eniyan rere, o si nrọjo fun awọn olóòtọ́ ati fun awọn alaisotitọ" (Mt 5:45)

"Ọlọrun iwọ ni o rán ọpọlọpọ ojo si ilẹ-ini rẹ, nigbati o rẹ̀ẹ́ tan; iwọ tù ú lara" (Ps 68:9)

"Ẹniti o fi awọsanma o oju ọrun, ẹniti o pese ojo fun ilẹ, ti o mu koriko daga lori awọn òkè nla" (Ps 147:8)

Ojuse Ọlọrun lati ri daju wipe ojo nrọ si ilẹ ni Ọlọrun kò bùkù ninu rẹ, Ọlọrun nse ojuse ti Rẹ yi lọ lati ri daju wipe oju ilẹ di ọ̀tun bẹni ilẹ si tutu.

(3) MÍMÚ ÌBÍSÍ WÁ

Lẹhin igbati Ọlọrun ba mu ojo rọ si awọn irugbin, tabi laiye ode oni, ti eniyan nbu omi si awọn irugbin nã, Ọlọrun nikan ló lè mu irugbin nã dàgbà, Ọlọrun nikan ló lè mu ki irugbin na bí sí i.

"Emi (Paulu) gbin, Apollo bomirin; sugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wa."Njẹ ki ise ẹniti o ngbin nkankan, bẹni ki ise ẹniti mbomirin; bikose Ọlọrun ti o nmu ibisi wa" (I Kor 3:6-7)

Lati mu ki nkan hù jade, lati mu ki nkan dàgbà lati mu ko bisi i, ojuse Ọlọrun ni, Oun ló mọ ọna ti ohun gbogbo to mbẹ ninu ilẹ, ninu afẹfẹ ati ninu irugbin nã yio fi sisẹ papọ̀ lati mu ki nkan dagba ki o si tun bí sí i.

(4) RÍRAN OÒRÙN

Isẹ kekere kọ́ ni oòrùn nse ninu idagbasoke irugbin, Ọlọrun nã lo si nmu ki oorun ran silẹ fun gbogbo aiye ati si ori awọn ohun ọ̀gbìn-in wa gbogbo. Gbogbo bi imọ ijinlẹ sayẹnis ti se se iwadi nipa eleyi to, o daju wipe wọn kò rí ọgbọ́n dá si oorun.

"Ki ẹyin ki o le má a jẹ ọmọ Baba yin ti o mbẹ ni ọrun: nitoriti o nmu oòrùn rẹ ran sara eniyan buburu ati sara eniyan rere, o si nrọjo fun awọn olóòtọ́ ati fun awọn alaisòótọ́" (Mt. 5:45)


OJUSE ÀGBẸ̀ (ENIYAN)

Ni mimu ki irugbin ti agbẹ gbìn o le dagba daradara, yatọ si ojuse ti Ọlọrun, eleyi to di dandan fun Un lati se, nitoripe ko le sẹ́ ara rẹ, ko le ba ọrọ Rẹ jẹ, eniyan na ni ojuse tirẹ lati sà ni mimu ki awọn irugbin to ti gbin na o le dagba daradara lẹhin igbati ó bá ti gbin awọn ohun na tan. Lara awon ojuse agbẹ niwọnyi:

(1) SÍSỌ́ Ọ:

Awọn irugbin kan wa to jẹ wipe nigbati o ba jade latinu ilẹ, eniyan nilati mã sọ́ ọ ki awọn eranko o ma ba à bajẹ. Awọn irugbin miran nigbati won bá dagba ti wọn fẹ ma so eso, olusọgba tabi agbẹ na nilati ma fojusi ki awọn ẹranko o ma ba jẹ gbogbo awọn eso na.

"O si pa owe yi fun wọn pe; ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbin si ọgba ajara rẹ̀; o si de, o nwa eso lori rẹ, ko si ri nkan. 

"O si wi fun olusọgba rẹ pe, sawò ó, lati ọdun mẹta ni emi ti nwa wo eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: gé e lulẹ; èése ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu?

"O si dahun o wi fun pe, Oluwa, jọwọ rẹ ni ọdun yi pẹlu titi emi o fi tu ilẹ idi rẹ yika, titi emi o si fi bu ilẹdu si i. 

"Bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi ko ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ge e lulẹ" (Lk 13:6-9). 

Latinu ọrọ yi ni ati ri wipe ojuse agbẹ ni lati mã sọ irugbin to gbìn sinu ọgba nã, tabi boya ti ọna rẹ ba jìnna, tabi boya isẹ rẹ pọ̀ kó gba enikan sí i ti yio ma sọ́ ọ.

"Oluwa Ọlọrun si mu ọkunrin nã, o si fi i sinu ọgba Edeni lati mã ro ó, ati lati má a sọ́ ọ" (Gen 2:15)

Sisọ ọgba Ọlọrun wa lara isẹ́ akọ́kọ́ ti Ọlọrun fun eniyan akọ́kọ, Adamu, to da sorilẹ aiye gẹgẹ bi a se ri ninu iwe yi.

(2) RÍRO AWỌN EPO KURO (DÀNÙ)

Ojuse keji ti agbẹ nilati ma se lati ri daju wipe awọn irugbin ti oun gbin sinu oko na dagba daradara ni lati ma ro awọn koriko tabi awọn èpò to le mã ba awọn irugbin na jà si awọn ohun meremere ti yio se irugbin na lore ti yio si mu ki awọn irugbin na dagba to mbẹ ninu ilẹ ja si dànù. Nigbati agbẹ tabi olusọgba na ba se eleyi, awọn ohun to gbìn sinu ilẹ nã yio le mã dagba daradara, bẹni yio le se rere ti yio si le ma mu eso wa. Sugbọn bi agbẹ tabi olusọgba na ba kuna lati se eleyi, awọn ohun ọ̀gbìn na kò ní se daradara, o sese nigbamiran pẹlu ki awọn èpò (tabi koriko) wọnyi tilẹ pa awọn irugbìn na patapata. 

"O si bi Abẹli arakunrin rẹ, Abeli a si ma se olusọagutan, sugbọn Kaini a ma a se alaroko ilẹ" (Gen 4:2)

BÍBU ÌLẸ̀DÚ SI AWỌN IRUGBIN NÃ NIDI

Ojuse olusọgba tabi agbẹ na ni lati ma bu ilẹdu tabi ohun ti wọn npe ni fatalisa sidi awọn ohun ọgbin na lati ma fun wọn ni awọn ohun àìfojuri ti yio sisẹ papọ pẹlu oòrun, omi ati awọn nkan miran lati mu ki irugbin na dagba daradara. 

"O si dahun o wi fun un pe, Oluwa jọwọ rẹ ni ọdun yi pẹlu titi emi o fi tu ilẹ idi rẹ yika, titi emi o si fi bu ilẹdu sí i" (Lk 13:8)

(4) BÍBU OMI RIN AWỌN IRUGBIN NA

Ni awọn ibiti ojo ki i ti rọ̀ daradara Olorun fi ọgbọn sinu eniyan lati ma bu omi sidi awọn ohun tó bá gbìn na ki o bã le dagba daradara. Nibomiran ti ojo ti nrọ pẹlu, lasiko ti ojo ko ba rọ, awọn agbẹ ma nse eto lati ma bu omi sidi irugbin ti wọn ba gbin lorekore ki o ba le se daradara. Se nitotọ, agbẹ kan tilẹ sọ fun mi wipe ti awọn agbẹ ba le ma ri omi bù sidi ohun ọgbìn wọn lasiko ọ̀gbẹlẹ̀, lasiko ti ojo kò rọ̀, o wipe lasiko yi ni awọn irugbin na ma nse daradara julọ, nitoripe ọpọlọpọ awọn kòkòrò àìfojuri yo ma mba irugbin jẹ ki ise daradara lasiko ọ̀gbẹlẹ̀.

"Emi gbìn, Apollo bomirin; sugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wa" (I Kor 3:6).

Ojuse agbẹ ni lati ma bomirin awọn ohun ọgbin na ki o ba le se daradara. Ati wo ojuse Ọlọrun ati teniyan (agbẹ) lati ri daju wipe irugbin na ti agbẹ gbin sinu oko rẹ se daradara, ati wipe o dagba gidi. Gẹgẹbi apẹrẹ ohun to se fojuri yi, bẹna ni irugbin igbagbọ to mbẹ ninu wa, eleyi ti a ti sọ bi o se le de inu wa ni awọn ori ti a ti wo saju eleyi. Mo wipe, irugbin igbagbọ a ma wa sinu eniyan nipa gbigbọ ọrọ Ọlọrun, nipa kika ọrọ Ọlọrun, nipa bibere lọwọ Ọlọrun eleyiun ni ni nipa adura gbigba. 

Irugbin igbagbọ ni a pè é, ki ise irugbin ìgbàgbé, nitorina, ẹniti yio ni irugbin igbagbọ ninu rẹ, oun na pẹlu yio ti kọkọ́ fi aye rẹ fun Jesu Kristi patapata, nigbayi ni irugbin igbagbọ na to le nitumọ sí i. Ẹniti ko i ti fi aye rẹ fun Jesu, irugbin ti a nsọrọ rẹ yi kò le nitumọ si, gẹgẹbi ẹniti ki ise àgbẹ̀ ko ni se ka awọn ohun ti ẹlomiran gbin sinu oko si, bẹna ni ẹniti ko ni igbala ko ni se ka irugbin igbagbọ si. Njẹ o ha ti ni igbala bi? Ti o kò ba i ti gba Jesu sinu aye rẹ, o se pataki fun ẹ lati ronupiwada kuro ninu awọn ẹsẹ rẹ gbogbo loni, ki o si yipada si Ọlọrun nipa fifi aye rẹ fun Kristi Jesu patapata, nipa pipe Jesu wọ inu aye rẹ lati wa ma ba ẹ gbe, lati wa ma ba ẹ se ohun gbogbo, nipasẹ eleyi ni iwọ na yio fi ni irugbin igbagbọ ninu aye rẹ, nipasẹ eleyi niwọ na yio fi mọ nigbati irugbin na ba jade ti iwọ na yio si ma se ojuse tirẹ nigbati Ọlọrun pẹlu yio ma se ojuse tirẹ.

Njẹ awọn ọna wo wá ni irugbin igbagbọ yi yio fi ma dagba si ninu aye onigbagbọ?

ỌNÀ TI IRUGBIN IGBAGBỌ FI NDAGBÀ SÍ I

Diẹ ninu awọn ọna ti irugbin igbagbọ ninu aye onigbagbọ fi ma ndagba si niwọnyi:

(1) GBÍGBỌ́ ỌRỌ (ỌLỌRUN) NA SI I:

Ki irugbìn igbagbọ bà á le ma dagba si ninu aye onigbagbọ, onigbagbọ yio ma gbọ ọrọ Ọlọrun si i. Ki ise awọn àdábọwọ́ ọrọ ni yio ma gbọ́ sí i bikose awọn ọrọ ti yio mú u dagba, awọn otitọ ọrọ Ọlọrun.

"Nitoripe igba yio de, ti wọn ki yio le gba ẹ̀kọ́ ti o yè koro; sugbọn bi wọn ti jẹ ẹniti eti nrin wọn o lẹ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn" (II Tim 4:3)

(2) KÍKA ỌRỌ NÃ SÍ I

Ọlọrun nfẹ ki a mọ nipa Oun daradara, ere idi niyi to se kọ ọrọ na kalẹ fun awa ọmọ Rẹ ki a ma ba wa ninu okunkun ati ki a ba le mã dagba si ninu igbagbọ. Nipa kika ọrọ Ọlọrun yi, ani nipa kika bibeli daradara ni a ó fi mã mọ Ọlọrun sí i ti a ó si fi ma dagba ninu Rẹ si i.

"Ẹyin nwa inu iwe-mimọ nitori ẹyin ro pe ninu wọn ni ẹyin ni iye ti ko nipẹkun; wọnyi si ni awọn ti njẹri mi" (Jhn 5:39)


(3) ÀJÙMỌ̀KẸ́GBẸ́PỌ̀ PẸ̀LÚ ARÁ

Ẹniti eniyan ba mba rin nise pupọ pẹlu bi igbesi aiye eniyan yio ti ri. Awọn agbagba Yoruba bọ wọn wipe, "fi ọrẹ rẹ han mi ngo si sọ iru eniyan ti o jẹ", wọn tun wi ni ọ̀nà miran ẹ̀wẹ̀ wipe, "agutan to mba ajá rin yio jẹ ìgbẹ́". Onigbagbọ to ni irugbin igbagbọ ninu rẹ nilati mọ ẹniti oun yio ma ba se ọrẹ.

"Ki a ma tan yin jẹ: ẹgbẹ buburu ba iwa rere jẹ" (I Kor 15:33)

Aposteli Paulu lo mba awọn are Kọrinti sọrọ nihinyi, o si wipe ẹgbẹ buburu ma mba iwa rere jẹ ni. Bi onigbagbọ ba da ara rẹ papọ mọ ẹgbẹ alaigbagbọ, nigbato baya, yio bẹrẹ sini se bi awọn alaigbagbọ wọnni to mba rin, eleyi lo fa ti bibeli se wipe,

"Ẹ mase fi àìdọ́gba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ: nitori idapọ kinni ododo ni pẹlu aisododo? Idapọ kinni imọlẹ si ni pẹlu okunkun?

"Irẹpọ kinni Kristi si ni pẹlu Beliali? Tabi ipin wo ni ẹniti o gbàgbọ ni pẹlu alaigbagbọ?

"Irẹpọ kinni tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu orisa? Nitori ẹyin ni tẹmpili Ọlọrun alaye; gẹgẹbi Ọlọrun ti wipe, Emi o mã gbe inu wọn, emi o si ma rin ninu wọn; Emi o si jẹ Ọlọrun wọn, wọn o si jẹ eniyan mi.

"Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si ya ara yin si ọ̀tọ̀, ni Oluwa wi, ki ẹ mase fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́; emi o si gba yin.

"Emi o si jẹ Baba fun yin, ẹyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, ni Oluwa Olodumare wi" (II KỌR 6:14-18)

Iwọ gẹgẹbi ọmọ Ọlọrun, ẹniti o ba fi se ọrẹ́ kòríkòsín rẹ se pataki pupọ, o si nise pẹlu bi irugbin igbagbọ na yio ti se tete dagba si.

(4) LÍLỌ SI ÀPÉJỌPỌ̀ DÉDÉ

Lẹhin ajinde ati ìgòkè lọ si ọrun Jesu Kristi, awọn aposteli ati awọn ọmọlẹhin Jesu yoku duro de ileri Baba, Eyiti ise Ẹmi Mimọ, wọn si ri ẹbun Ẹmi Mimọ na gba. Lẹhin eleyi ọpọ eniyan gbàgbọ́. Gbogbo awọn to gbagbọ yi pẹlu awọn miran to tun ngbagbọ lẹhin igbana ni wọn npàdé fun ẹ̀kọ́ ọrọ Ọlọrun lorekore ki nwọn o bã le mã dàgbà sí i ninu igbagbọ.

"Wọn si nfi ọkan kan duro ni ojojumọ ninu tẹmpili ati ni bibu akara lati ile de ile, wọn nfi inu didun ati ọkan kan jẹ ounjẹ wọn" (I. Apo 2:46)

Ninu iwe Heberu, onkọwe iwe na gba gbogbo awọn eniyan mimo to mbẹ nilu Heberu niyanju wipe,

"Ki a má má a kọ ìpejọpọ ara wa silẹ, gẹgẹ bi asà awọn ẹlomiran; sugbọn ki a mã gba ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹnyin ti ri pe ọjọ ni nsunmọ etile" (Heb 10:25)

Nigbati a bá nsapọn lati má a bá awọn ará ninu Kristi Jesu pé lorekore lati tun kọ́ ẹkọ ọrọ Ọlọrun sí i, nigbana irugbin igbagbọ na yio tun ma dàgbà sí i. Nitoripe nipa ìrírí awọn ará ti a jumọ sọ larin ara wa, awa na yio tun ri ẹ̀kọ́ kan tabi omiran kọ́. Nipa ọrọ Ọlọrun ti a gbọ lati ẹnu ẹlomiran, yio bukun aye wa, ohun ti a lè ro wipe a ti mọ daradara tẹlẹ ẹlomiran yio tun tan imọlẹ sí i fun wa. Ki íwá tun nse eleyi nikan, nini ipejọpọ yi, a o ma ri iranlọwọ gbà lọwọ ara wa, eleyi ti yio tun mu ki igbagbọ wa ninu Kristi Jesu dagba si i, ti ifẹ wa si ara wa yio si tun pọ̀ sí i.

Nipa apejọpọ wọnyi ati ohun to nsẹlẹ ninu apejọpọ wọnyi ni Ọlọrun yio fi ma rọ òjò si irugbin igbagbọ na ninu aye wa; nipasẹ eleyi ni awọn èpò tabi koriko to wa ninu ilẹ aye wa to mba idagbasoke irugbin ìgbàgbọ́ na dije yio ma di fífàtu kuro ti alafia yio si mã dé bá irugbin igbagbọ na ti yio si le mã de ba irugbin igbagbọ na ti yio si le mã dagba si gidigidi laiye wa.

(5) MÍMÚ AWỌN IWUKARA ÀTIJỌ́ KÚRÒ

Iwukara jẹ ohun to nmu ki ìyẹ̀fun di wíwú.

"Isefefe yin ko dara. Ẹyin kò mọ pe iwukara diẹ ni imu gbogbo ìyẹ̀fun di wiwu?" (I Kor 5:6)

Ilẹ rere aye wa nibiti a fún irugbin igbagbọ si, ti o si ti hù jade nã ni a fi we iyẹfun. Njẹ iyẹfun yi, eyiti ise ilẹ rere aye eniyan le è di wiwu pẹlu iwukara eleyi ti Ọlọrun ko fẹ. Bi iyẹfun aye wa ba si di wíwú eleyi tumọ si wipe, awọn ìwà ati ise ara eleyi ti a jogun lati ọdọ ejo laelae nì ni yio ma farahan.

"Nitorina ẹ mu iwukara àtijọ kuro ninu nyin, ki ẹnyin ki o le jẹ iyefun titun, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ àìwukara. Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rúbọ fun wa" (I Kọr 5:7)

Gbogbo awọn iwukara atijọ wọnyi ni awọn ohun àìdara ti a nse nigbati a ò ti mọ Kristi Jesu, gbogbo awọn nkan wọnyi ni a nilati dágbére fun ki irugbin nã bà á le mã dàgbà daradara ninu aiye wa.

"Nitorina ẹ má a pa ẹya-ara yin ti o mbẹ ni aiye run: agbere, ìwà-èérí, ifẹkufẹ, ifẹ buburu, ati ojukokoro, ti ise ibọrisa:

"Nitori ohun ti ibinu Ọlọrun fi mbọwa sori awọn ọmọ alaigbọran.

Ninu eyiti ẹyin pẹlu ti nrin nigbakan ri, nigbati ẹnyin ti wà ninu nkan wọnyi.

"Sugbọn nisinsinyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, ìrunú, arankan, ọrọ-odi, ati ọrọ idibajẹ kuro ni ẹnu nyin.

"Ẹ masi se purọ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ́ ọ̀gbólogbo ọkunrin ni silẹ pẹlu ise rẹ;

"Ẹ si ti gbé ọkunrin tuntun na wọ̀, eyiti a sọ di tuntun si imọ̀ gẹgẹ bi aworan ẹniti o dá a" (Kol 3:5-10)

Awọn iwukara atijọ ati awọn miran ti ngo kọ sihinyi ti yio se akobá fun irugbin igbagbọ wa niwọnyi, gbogbo wọn ni a nilati mu kuro ki a si di ẹda titun gẹgẹ bi Ọlọrun ti nfẹ nipa gbigbe àìwukara titun wọ̀.

Àìwukara titun jẹ eleyi to dara, awọn ohun ti Ọlọrun nfẹ ki a ma se, awọn ohun ti yio mu ki ilẹ wa wuni, awọn ohun ti yio mú irugbin igbagbọ nã dàgbà si i, ninu aye wa ni ohun ti a npe ni àìwukara titun yi.

"Nitorina ẹ jẹ ki a se ajọ na, ki ise pẹlu iwukara atijọ, bẹni ki ise pẹlu iwukara arankan ati iwa buburu; bikose pẹlu àìwukara ododo ati otitọ".

Apẹrẹ aiwukara yi ni a pè ni ododo ati otitọ nihinyi. Eleyi ni wipe, awa gẹgẹ bi onigbagbọ ati ọmọ Ọlọrun, a nilati ma sọ otitọ pẹlu ara wa, anilati jẹ olododo nibi gbogbo ti a bá wa, ki awọn ọmọ aiye ati ọmọ okunkun bàá le pe wá ni ọmọ Ọlọrun, ki wọn bàá le ri wipe lotitọ irugbin igbagbọ to mbẹ ninu wa ndagba soke sí i. (Ef. 4:23-32)

(6) SÍSÁ FUN AWỌN NKANKAN-KAN

Ki irugbin igbagbọ to wa nilẹ rere aye wa bàá le dagba daradara, a nilati má a sá fun awọn nkankan kan, kini awọn ohun na?

(i) Ifẹkufẹ èwe 

"Má a sa fun ifẹkufẹ èwe: si má a lepa ododo, igbagbọ, ifẹ, alafia, pẹlu awọn ti nkepe Oluwa lati inu ọkan funfun wá" (II Tim 2:22)

Ifẹkufẹ èwe wa ninu awọn nkan ti aposteli Paulu sọ wipe ki ọmọ rẹ Timoteu o sa fun. Ninu iwe rẹ kinni si awọn ara Kọrinti ẹ̀ẹwẹ, o sọ nipa nkan mẹta latinu eyiti ifẹkufẹ ko ti ni se alai ma jade.

"Nigbati mo wa ni ewe, emi a má a sọrọ bi èwe, emi a ma moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: sugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi iwa ewe silẹ" (I Kọr 13:11)

Ninu akọsilẹ oke yi ni a ti ri awọn nkan mẹta ti aposteli sọ wipe o ma nmu ki ifẹkufẹ ewe o jade:

(i) Ọ̀rọ̀ èwe,

(ii) Oye ewe, 

(iii) Ero ewe.

Latinu nkan mẹtata wọnyi ni ifẹkufẹ ewe ti ma njade.

Ninu iwe Samueli keji ori kẹtala a rí ìsẹ̀lẹ̀ kan to sẹlẹ si awọn ọmọ Dafidi meji ti a npe ni Tamari ati Amnoni. Amnoni jẹ ọdọkunrin nigbati Tamari jẹ omidan obinrin to lẹ́wà gidigidi. Amnoni ọmọ Dafidi ni ọrẹ kan ti a npe ni Jonadabu.

Amnoni ati Tamari gẹgẹbi ọmọ baba kan, a mã wọle wọn a si ma jìjọ jade, lede miran wọn jijọ ma nse eré papọ̀ bóyá wọn tilẹ jijọ wà ni ile iwe giga kanna ni a kò le sọ.

Gbogbo bi wọn ti se jijọ nwọle ti wọn njade yi, nigbato di asiko kan, nse ni Amnoni yi ri wipe èrò kan nwa si ọkan oun, njẹ kini ero nã? Ero to nwa si ọkan rẹ na ni ki o fẹ aburo rẹ, ki oun ati aburo rẹ jìjọ ni ìbálòpọ̀ gẹgẹbi tọkọ-taya. Bi o se nro ero yi lati ọjọ́ de ọjọ́ ni eleyi titi to fi di wipe ero na ko fun ni isinmi mọ, ero nã dàá lamu tobẹ́ẹ̀ gẹ to fi di àìsàn si i lara, aisan yi farahan loju rẹ wipe nkan nse e. Ọrẹ rẹ to njẹ Jonadabu yi lo fiyesi ọrẹ rẹ, Amnoni, kínní-kínní lojọkan to si sọ fun ọrẹ rẹ na wipe, "o dabi ẹnipe nkan nse ẹ...sọ ohun to nse ẹ fun mi gẹgẹbi ọrẹ rẹ"

Amnoni na si sọ fun ọrẹ rẹ ero to nwa si ọkan rẹ lati igba-de-igba eleyi to nda lamu ti ko si fun ni isinmi.

Jonadabu na si fun imọran gẹgẹ bi ọmọde ohun to yẹ ko se lati fi mu erongba buburu na sẹ. Eleyi na ni Amnoni si se to si fi dẹsẹ si Ọlọrun, o bá aburo rẹ se pọ̀.

"O si se, lẹhin eyi, Absalomu ọmọ Dafidi ni aburo kan ti o se arẹwa, orukọ rẹ a si mã jẹ Tamari, Amnoni ọmọ Dafidisi fẹran rẹ

"Amnoni si banujẹ titi o fi se aisan nitori Tamari aburo rẹ obinrin; nitoripe wundia ni; o si se ohun to soro ni oju Amnoni lati bá a se nkankan.

"Sugbọn Amnoni ni ọrẹ kan, orukọ rẹ a si ma jẹ Jonadabu, ọmọ Simea ẹgbọn Dafidi: Jonadabu si jẹ alarekereke eniyan gidigidi.

"O si wi fun un pe, èése ti iwọ, ọmọ ọba, fi nrù lojojumọ bayi? O ki yio ha sọ fun mi? Amnoni si wi fun un pe, emi fẹ Tamari aburo Absalomu arakọnrin mi

"Jonadabu si wi fun un pe, dubulẹ ni ibusun rẹ, ki iwọ ki o si díbọ́n pe iwọ kò sàn: baba rẹ yio si wa wò ọ́, iwọ o si wi fun un pe, jọwọ jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá ki o si fun mi ni ounjẹ, ki o si se ounjẹ na niwaju mi ki emi ki o rí i, emi o si jẹ ẹ́ ni ọwọ rẹ̀.

"Amnoni si dubulẹ, o si díbọ́n pe oun saisan: ọba si wà wò ó, Amnoni wi fun ọba pe, jọwọ jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá, ki o si din akara meji ni oju mi, emi o si jẹẹ́ ni ọwọ rẹ.

"Dafidi si ransẹ si Tamari ni ile pe, lọ si ile Amnoni ẹgbọn rẹ, ki o si se ounjẹ fun un

"Tamari si lọ si ile Amnoni ẹgbọn rẹ, oun si mbẹ ni idubulẹ. Tamari si mu iyẹfun, o si pò ó, o si fi se akara ni oju rẹ, o si din akara nã.

"Oun si mu àwo nã, o si dà á sinu awo miran niwaju rẹ; sugbọn o kọ̀ lati jẹ. Amnoni si wipe, jẹ ki gbogbo ọkunrin jade kuro lọdọ mi. Wọn si jade olukuluku ọkunrin kuro lọdọ rẹ.

"Amnoni si wi fun Tamari pe, mu ounjẹ nã wa si yara, emi o si jẹ lọwọ rẹ. Tamari si mu akara ti o se, o si mu u tọ Amnoni ẹgbọn rẹ ni iyẹwu.

"Nigbati o si sunmọ ọ lati fi ounjẹ fun un, oun si dì í mu, o si wi fun un pe, wa dubulẹ tìmí, aburo mi.

"Oun si da a lohun wipe, bẹkọ ẹ̀gbọ́n mi, mase fi agbara mu mi; nitoripe kò tọ́ ki a se iru nkan bẹ́ẹ̀ ni Israeli; iwọ mase huwa were yi.

"Ati emi, nibo ni emi o gbé itiju mi wọ? Iwọ o si dabi ọkan ninu awọn asiwere ni Israeli. Njẹ nitorina emi bẹ̀ ọ́, sọ fun ọba; nitoripe oun ki yio kọ̀ lati fi mi fun ọ.

"Sugbọ́n ó kọ̀ lati gbọ ohun rẹ; o si fi agbara mú u, o si sẹgun rẹ, o si bá a dàpọ̀" (II Sam 13:1-14)

Ninu akọsilẹ oke yi, a ó ri wipe ero ewe, oye ewe ati ọrọ ewe yọri si ifẹkufẹ ewe eleyi to di mimusẹ lati ọwọ Amnoni wa. Irufẹ ifẹkufẹ ewe ti aposteli Paulu ngba ọmọ rẹ ninu ẹmi, Timoteu lati máa sá fun ni eleyi. Ninu Genesisi orí kọkandinlogun, a ó tun ri apẹrẹ ifẹkufẹ ewe miran lati ọwọ́ awọn ọmọbinrin Loti (Gen 19:30 - 38)

Ifẹkufẹ ewe a mã bori ọkan ewe lasiko ti wọn wà lewe nitoripe wọn kì íronu ọjọ iwaju lasiko nã, ohun to nsẹlẹ lọwọlọwọ ni wọn ma nmọ, nitorina, wọn yio fi ààye gba ero wọn lati dari wọn, dipo ti awọn yio fi dari ero nã wọn ko ni se bẹ, ero wọn a dari wọn, a sì tì wọn lọ sinu àsìse ati iparun. 

A o ni gbagbe Esau nikorita yi, o fi ààyè gba ifẹkufẹ ewe niti àìle ko ara rẹ nijanu lati sẹgun rẹ, eleyi to mu ki ohun to lẹtọ si ó di ti ẹlomiran. (Gen 25:29-34) Ifẹkufẹ ewe bori ọkan Orpa eleyi to mu ko pada sidi orisa awọn baba rẹ (Rutu 1)...Ifẹkufẹ ewe lo bori ọkan ololufẹ Jakọbu, iya Josefu, ẹniti a npe ni Rakeli nigbati o jí orisa baba rẹ dani, eleyi to wa lara awọn idi ti ko se wọ ilẹ̀ Kenani pẹlu ọkọ rẹ (Gen 31:19, 30, 34). Ifẹkufẹ ewe ti Dina kuna lati sá fun nã lo fa idamu bá á, eleyi to sọ ọ di ẹni ibajẹ (Gen 34:1)

Ki irugbin igbagbọ to mbẹ ninu wa o bà á le mã dàgbà sí i, a nilati má a sá fun ifẹkufẹ ewe nigbagbogbo ati nibikibi ki a bà á le jẹ ilẹ to wuni, ki a ba si le mã mu eso jade lọgọrọrun, lọgọtọta fun Olọrun.  (ii) Ohun keji ti bibeli ti ni ki a ma sa fun ni agbere.  

"Ẹ má a sa fun agbere. Gbogbo ẹsẹ ti eniyan ndá o wa lode ara; sugbọn ẹniti o nse agbere nsẹ si ara oun tikararẹ" (I Kọr 6:18)  

"Sugbọn, iwọ eniyan Ọlọrun sá fun nkan wọnyi" (I Tim 6:11a)  

Njẹ kinni awọn nkan nã ti aposteli Paulu ngba ọmọ rẹ ninu ẹmi Timoteu niyanju lati sá fun? Awọn nkan na ni a o ri kà ni ẹsẹ meji to saju ẹsẹ kọkanla yi.  

"Sugbọn awọn ti nfẹ di ọlọ́rọ̀ a mã bọ sinu idanwo ati idẹkun, ati sinu were ifẹkufẹ pupọ ti ipanilara, iru eyiti i mã ri eniyan sinu iparun ati egbe  

" Nitori ifẹ owó ni gbongbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn sako kuro ninu igbagbọ, wọn si fi ibanujẹ pupọ̀ gún ara wọn ni ọ̀kọ̀" (I Tim 6:9-10)

Ifẹ ati di ọlọrọ ati ifẹ owo ni ohun ti aposteli Paulu gba ọmọ rẹ niyanju lati ma sa fun, eredi ni wipe, ifẹ lati se awọn nkan wọnyi ni abajade buburu gẹgẹbi o ti se kọ awọn abajade wọn tẹle awọn ifẹ lati da awọn nkan wọnni.  Ẹkiyesi, ko sọ wipe didi ọlọrọ kò dara, ko sọ wipe didi olowo ko dara, nitoripe aposteli Paulu na mọ wipe, ọwọ́ alapọn la o mu sanra, aposteli Paulu na mọ wipe ẹnito ba fifunnu a ó fifun ẹni na pada, àkìmọlẹ, àmìnpọ ati akùnwọ́ silẹ la ó wọ̀n si apo ẹni na, aposteli na mọ wipe, igbega kò ti ila orun tabi iwọ orun wa, sugbọn Ọlọrun lo ngbe ẹnikan leke ti yio si tun rẹ ẹlomiran silẹ̀ (Lk 6;38; O.D 75:6; Owe 11:25) aposteli yi mọ pataki ati iwulo owó ati ibukun ninu ihinrere, sugbọn ohun to wi ni wipe ki a ma se nifẹ rẹ, ki a mase ni ifẹ owo, nitori nini ifẹ owo yio se ipalara pupọ fun irugbin igbagbọ na ninu aye wa, nini ifẹ owo yio di ẹ̀gùn ti yio fun irugbin igbagbọ na pa laiye wa, eleyi ti yio si mu wa kuro ninu Kristi Jesu Oluwa, nitorina lo se wipe kí a sa fun ifẹ nkan wọnyi ki a bà á le gba ifẹ Kristi Jesu laye lati jọba lọkan wa. Gẹgẹbi ko ti se rọrun fun eniyan lati sin Ọlọrun ati Mammoni papọ lẹkansoso (Mt 6:24), bẹna ni ko ti se rọrùn lati ni ifẹ owo tabi ifẹ ọrọ ati ifẹ Jesu papọ lẹkansoso ninu aye eniyan. Eniyan ni yio yan ọkan ti yio si korira ekeji laiba se eleyi, eniyan ntan ara rẹ jẹ lasan ni. Nitori eleyi lo se wipe,

"Sugbọn iwọ, eniyan Ọlọrun, sa fun nkan wọnyi: ki o si mã lepa ododo, iwabi-Ọlọrun, igbagbọ, ifẹ, sùúrù, iwa tutu" (I Tim 6:11) 

Nigbati a ba nsisẹ wa botise tọ ati botise yẹ, Ọlọrun yio bukun fun wa lati ipasẹ (Owe 10:4b) rẹ, sugbọn ki ise wipe ki a ma lepa ati di ọlọrọ lọnakọna tabi ki a nifẹ owó. Níní ìfẹ́ ati di ọlọrọ lo ma nmu ki enia se ohun ti ko dara gbogbo pẹlu erongba ati ipinnu wipe oun sàá fẹ di ọlọrọ ninu aiye dandan.  Sugbọn, bi a bá nse isẹ wa tọkan-tara, ti a si gbe ifẹ Ọlọrun ka iwaju wa tọ̀sán-tòru, ti ifẹ Ọlọrun borí gbogbo ifẹ owo ati ifẹ gbígbóná lati di ọlọrọ ni ọna konà tó wà lọkan wa, a ó ri wipe ọna ti Ọlọrun yio gba lati sọ wa di ọlọ́rọ̀ a ò ni le è mọ̀ ọ́, a ò ni le è sọ ọ́, gẹgẹbi Ó ti se sọ awọn baba igbagbọ, Abrahamu, Isaaki, Josẹfu, Dafidi, Solomoni abbl di ọlọrọ níwọ̀n igbati wọn gbe ifẹ Ọlọrun nìkan ka iwaju wọn, bẹna ni Ọlọrun yio se se tiwa nã, nitoripe Ọlọrun wa yi, ọkan ni lana, loni ati lọla, kò yípadà rí.  

"Jesu Kristi ọkanna ni ni àná, ati ni òní, ati titi lae" (Heb 13:8) 

Njẹ iwọ nã o kì yio ha gbe Kristi Jesu nikan ka iwaju rẹ bayi bi?  

(iv) Lẹhin awọn nkan ti a nilati sá fun wọnyi ki irugbin igbagbọ wa bàá le se daradara gidi, bibeli tun gba wa niyanju lati takété si ohun gbogbo ti o jọ ibi. 

"Ẹ mã takété si ohun gbogbo ti o jọ ibi" (I Tess 5:22; Rm 12:9b) 

Títakété si nkan tumọ si fifa sẹhun si nkan ti eniyan ri, lọpọ igba, a ma nlo ede yi fun nkan ti eniyan kàn dédé se alabapade lojiji. Fun apẹrẹ, bi ẹnikẹni ba se alabapade ejò lojiji, nse ni eniyan yio sún sẹhin ti yio si duro, ti ko ni fẹ tẹsiwaju mọ bikose ki o ma wo ọtun ati osi fun ohun ti yio fi pa ejò nã, tabi tó bá jẹ ẹlomiran lẹhin igbati o ba fàsẹhin tán-an nì, nse ni yio tun pariwo, nigbati ẹlomiran yio tilẹ yi oju pada ti yio si mã sa pada lọ si ọnà ibiti ó ti mbọ̀ wá tẹ́lẹ̀. Ohun ti titakete túmọ̀ si ni eleyi.  Nigbati aposteli Paulu wá wipe, ki a mã takete si ohun gbogbo ti o jọ ibi, eleyi tumọ li ọna kan si wipe, o sese ki eniyan má mọ̀ wipe ibi mbẹ ninu irin ajo ti oun nrin lọ tẹ́lẹ̀, sugbọn ni kété ti o ba ti ri wipe ohun to farajọ ibi wa loju ọna na nse ni ki ẹni na ó ta kété sí i. Fun apẹrẹ ẹnito ti nlepa ati lọ silu eyibo lati ọjọ́ pípẹ́ sugbọn to jẹ́ wipe gbogbo ìnọ̀gà ati ilepa rẹ lo njasi asán, nigbatose díẹ ló wá se alabapade ẹnikan to sọ wipe oun yio ràn-án lọwọ lati mu erongba yi sẹ. Inu rẹ dun jọjọ nigbato gbọ eleyi to si ti npalẹmọ lati di ero ilu eyibo, sugbọn nigbato ku diẹ ti yio lọ silu eyibo ni ẹni na wa pèé wipe yio ba oun gbe ẹrù kan dani fun ọrẹ oun lọhun...boya ko tete mọ iru ẹru nã, sugbọn lẹhun o rẹhin kótó di wipe ọjọ ti yio lọ silu eyibo pé lo wa gbọ wipe oògùn olóró ni ẹni na nfẹ ki oun ba oun gbe lọ silu eyibo. A o ri wipe ibi ni eleyi, àmọ̀ràn aposteli Paulu fun iru eniyan bẹ́ẹ̀ ni wipe ki o sa fun iru irin ajo bẹ́ẹ̀, kó pa irin ajò na ti nitori ati de ijọba Ọrun.  Ẹjẹ ki ntun se apẹrẹ miran, bóyá ẹnito ti nwá ọkọ tabi aya tipẹ, nigbose o se alabapade ẹnikan lẹhin ọpọlọpọ adura ati awẹ, lẹhin igbati wọn bẹrẹ sini fẹ ara wọn lo wa ri wipe ẹni na nse awọn ohun ti ko ba ihinrere mu, boya o nmu ọti, boya o nji owo awọn to mba sisẹ lati ma fi se ọmọkunrin, ki o ba le ma farahan loju afẹsọna rẹ wipe oun le gbọ bukata rẹ...lẹhin igbati irú ibi yi ba ti hàn si ẹni na, ohun ti aposteli Paulu sọ ni wipe ki ẹni na takete siru irin ajo bẹ nitori ati de ijọba ọrun, àní nitori ati mu ki irugbin igbagbọ to ti hù jade na le dagba daradara. Aposteli Paulu wipe, "ẹ mã takété si ohun gbogbo ti o jọ ibi". Wiwo ọrọ yi kínní-kínní fihàn wipe, awọn nkankan wa ti wọn jọ ara wọn gãn tobẹ gẹ ti eniyan le ma da rere mọ yatọ̀ kuro ninu ibi awọn ohun nã. Fun apẹrẹ, awọn ibeji kan wa ti wọn ma njọ ara wọn gidigidi tobẹ gẹ to fi jẹ wipe awọn ara ìta kì í da irufẹ awọn eniyan bawọnni mọ yatọ si ara wọn. Mo wo ere ori itage kan nibiti ẹnikan ti ni ibeji to jọ ara wọn jọjọ. Ìkan lara awọn ibeji wọnyi a ma se ìkà (ibi), ó jẹ́ eniyan buburu bẹni kò si mọ Ọlọrun, nigbati ẹni keji jẹ enia rere, ti o si bẹru Ọlọrun gidigidi. Sugbọn nigbati eyi to ma nse ibi ba se buburu rẹ tan yio salọ, wọn yio si mu ekeji ti wọn yio si fiyajẹ ẹ́, fun ẹsẹ ekeji rẹ. Bẹna ni irufẹ ohun ti aposteli yi nfẹ ki a rí nihinyi, nigbati o wipe ki a ma takete si ohun gbogbo to jọ ibi. Eleyi ni wipe awọn ohun to jọ ibi na súnmọ́ ara wọn jọjọ tobẹ gẹ ti ẹniti ko ba wò ó daradara nigbamiran ko ni mọ wipe irufẹ ohun na ki ise ibi. 

Ninu iwe Danieli ori kinni ni a ti ka nipa Danieli ati awọn ọdọ miran ti a kó ni igbekun lati ilẹ ajeji wa si ilẹ Babiloni. Ọba Babiloni to njẹ Nebukadnessari wa pasẹ wipe ki a sa awọn ọmọ to dara, awọn ọmọ ti wọn lẹ́wà, awọn ọmọ ìjòyè, awọn ọmọ ọlọ́lá, awọn ọmọ-ọba tó wa lara awọn ti wọn kó ni ìgbèkùn sọ́tọ̀ fun oun. 

Lẹhin igbati awọn iwẹfa ọba ti mu asẹ ọba sẹ tan, ọba wa wi fun wọn wipe ki wọn o berẹ sini kọ́ wọn ni ìwé ati ede awọn ara Kaldea, ati ki wọn o mã fun wọn ni ounjẹ to dara, omi to dara, ọti waini to dara mu....  

"Ọba si wi fun Aspenasi, olori awọn ìwẹfa rẹ̀, pe, ki o mu awọn kan ninu awọn ọmọ Israeli wa, ninu iru-ọmọ ọba, ati ti awọn ijoye;  

"Awọn ọmọ ti ko labawọn lara, sugbọn awọn ti o ba oju rere pupọ pade, ti o si ni imọ ninu ọgbọn gbogbo, ti o mọ oye, ti o si ni iye ninu, ati iru awọn ti o yẹ lati duro ni ààfin ọba, ati awọn ti a ba ma kọ ni iwe ati ede awọn ara Kaldea.  

"Ọba si pese ounjẹ wọn ojojumọ ninu adidun ọba ati ninu ọti-waini ti o nmu; ki a bọ́ wọn bẹ́ẹ̀ ni ọdun mẹta, pe, ni opin rẹ, ki wọn ki o le duro niwaju ọba. 

"Njẹ ninu awọn wọnyi ni Danieli, Hananiah, Misaeli ati Asariah, lati inu awọn ọmọ Juda." (Dan 1:3-6)  

Ẹsẹ kọ ni awọn ounjẹ wọnyi, sugbọn o farajọ ibi lawọn eniyan wọnyi se sá tabi ki a wipe takete si i. Iru awọn ounjẹ wo ni awọn ounjẹ wọnyi? Awọn ounjẹ to ma nfẹ múni gbọ́n tabi mòye ni awọn oúnjẹ na, ani awọn ounjẹ ti enia ma nfẹ ma gbẹkẹle tabi sọ di ọlọrun kekeke ki enia o to le se nkan ni awọn ounjẹ na. Fun apẹrẹ igbó mimu, kokeni, ọti mimu abbl. Iwadi fiahn wipe awọn nkan wọnyi a ma mu ki enia o se ohun to jẹ wipe enia ko ni le se to bá jẹ lojú lasan ni... awọn miran ti wọn ko ba mu ọti, wọn ko ni le ba ọpọ eniyan sọrọ lawujọ, fun idi eleyi, ni gbogbo igbati wọn ba fẹ ba enia sọrọ wọn yio mu ọti... wọn wipe awọn nse eleyi ki ori wọn o ba le tanna silẹ.  

"Nigbati obinrin na si ri pe, igi nã dara ni jijẹ ati pe o si dara fun oju, ati iti ti a nfẹ lati MU NI GBỌ́N, o mu ninu eso rẹ o si jẹ, o si fi fun ọkọ rẹ pẹlu rẹ, oun si jẹ" (Gen 3:6)  

Iya nla wa jẹ eso na nitori o ri wipe o jẹ èso to ma nmu ki eniyan o gbọ́n. Bẹna ni awọn ounjẹ tabi awọn ohun mimu wọnyi, awọn nkan na ma nmu ki ori awọn enia o tanna silẹ ti wọn yio si wa dabi ọlọgbọn, nitorina awọn eniyan ma ngbekele awọn nkan wọnyi, awọn enia yio si ma mu-ún tabi jẹ awọn ohun na, ti wọn yio si gbe igbẹkẹle wọn kuro ninu Ọlọrun. Ohun yi farajọ ibi, nitorina awọn eniyan wọnyi kọ̀ ọ́, awọn enia wọnyi ko fẹ gbe igbẹkẹle wọn kuro ninu Ọlọrun, wọn kọ ohun na. Irufẹ ohun ti aposteli na nsọ niyi. Awọn ohun ti eniyan yio fẹ gbẹkẹle ti yio si mu ki igbẹkẹle ati igbagbọ eniyan ó kuro ninu Ọlọrun ni iru awọn ohun ti o farajọ ibi ti aposteli yi ngbawa niyanju lati sa fun. Ani iru awọn ohun to ti sọ ara wọn di Ọlọrun mọ wa lọwọ wọnyi ni a nilati ma takete si. 

(v) Fi Fà-sẹ́hìn:

"Olufẹ, mo bẹ yin, bi àlejò ati bi èrò, lati fà sẹ́hìn kuro ninu ifẹkufẹ ara ti mba ọkan jagun" 

Ohun ti a tumọ si "fà-sẹhìn" nihinyi ni a pè ni "apecho". Ọrọ yi kanna ni a lo ninu episteli si awọn ara Tesalonika kinni ori kẹrin ẹsẹ kẹta ati ori karun ẹsẹ kejilelogun (I Tess 4:3; 5:22). 

"Fà-sẹ́hìn" tumọ si ki nkan o ma se dede tabi dọ́gba-dọ́gba pẹlu awọn nkan yoku. A tun le sọ wipe ki nkan ó lọ silẹ̀ ju awọn nkan yókù lọ. Fun apẹrẹ, bi eniyan bi mẹta tabi jubẹlọ ba jijọ nrìn lọ, ti irin ẹnikan lara wọn kò bá bá ti awọn yoku mu, tabi bi irin ẹnikan lara wọn kò ba se dede pẹlu ti awọn yoku, awọn wọnyẹn yio bere lọwọ ẹni na ohun to fàá ti o fi nfa sẹhin, wọn yio bere lọwọ rẹ ohun to fàá tó fi nyọ ara rẹ kúrò larin wọn.... Tabi bi awọn kan ba njíròrò lori ohunkan, ti ẹnikan lara wọn kò si sọ ohunkohun si gbogbo ọ̀rọ̀ ti awọn yókù ti nsọ lati ìgbàti wọn ti nsọrọ wọn yio bere lọwọ ẹni na èrèdí to fi nfa sẹhin tabi to fi nyọ ara rẹ kuro larin ọ̀rọ̀ ti wọn nsọ.... Eleyi ni ohun ti a npe ni fífà-sẹhin. Fifasẹhin ni a tun le pe ni ede miran wipe ó jẹ́ yíyọ ara ẹni sọtọ kuro ninu ohun ti ẹgbẹ́ tabi awọn eniyan kan jìjọ nse tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀.  

Nigbati a ti ri itumọ fífà-sẹhin bayi, ẹ jẹ ki a tun wo ọrọ olori awọn aposteli, Peteru, yẹn daradara sí i. Ninu ọrọ aposteli Peteru yi, a ri wipe aposteli na nsọ fun awọn eniyan mimọ ohun ti wọn nilati fà-sẹhin kuro ninu rẹ. Kísìni ohun na? Ohun na ni "ifẹkufẹ ara". 

Ibere ti a nilati dahun wa ni wipe, "kini ifẹkufẹ ara?  Guy Woods, tumọ ifẹkufẹ ara si "gbogbo ifẹ buburu ti a npongbẹ fun lọkan wa lati ni". 

Ẹ kiyesi, ki ise gbogbo ohun ti a nfẹ (npongbẹ fun lọkan wa) lati ni na lo jẹ buburu, sugbọn ohun ti a npe ni ifẹ buburu ma nsẹlẹ nigbati awọn ohun ti a npongbẹ fun lọkan wa lati ni wọnyi bá jẹ awọn ohun ti Ọlọrun korira, ati tabi awọn ohun ti Ọlọrun ko fẹ.  

Diẹ lara awọn ifẹkufẹ ara wọnyi to jẹ jade lara awọn ohun buburu ti a nfẹ lati ní ni wiwọ asọ ìyẹ̀wù tabi yárá lọ si ìta awọn miran ojú kì í tilẹ tiwọn iru asọ wọnyi nse ni wọn yio wọ̀ ọ́ lọ si àárín ọjà, wọn yio ma pe eleyi ni ọlaju nipasẹ sise eleyi wọn nfọwọ so ọwọ́ pọ̀ pẹlu esu lati mu ẹ̀sẹ̀ gbilẹ si ninu aiye... iru ifẹkufẹ ara ti aposteli Peteru nsọ wipe ki a fà sẹhin kuro ninu rẹ ni eleyi. 

Ninu aiye lode oni, ó hàn wipe, ọ̀pọ̀ obinrin ni kò mọ bi ase njoko larin awujọ nse ni wọn yio joko bó ba se wù wọn. Ọpọ nitori àìfẹ mã kiyesara nipa ijoko lọ yan sòkòtò wìiwọ̀ layo nigbati bibeli wipe, 

"Obinrin kò gbọdọ mu ohun ti ise ti ọkunrin wọ̀, bẹni ọkunrin kò gbọdọ mu asọ obinrin wọ̀: nitoripe gbogbo ẹniti o ba se bẹ́ẹ̀ ÌRÍRA ni wọn si Oluwa Ọlọrun rẹ" (Duet 22:5)  

Awọn ohun irira wonyi ni a nse loni ti a npe ni ọlaju, a npe wọn ni àsà igbalode, a nfi ẹsẹ kun ẹsẹ, eleyi ni ifẹkufẹ ara, eleyi ti aposteli Peteru wipe a nilati fa sẹhin kuro ninu rẹ, nitoripe o nda ọkan wa lãmu, kò fún ọkan wa nisinmi.  

Ọpọ̀ ọkunrin ni kò mọ bi a se nmura, nse ni awọn miran yio wọ sokoto ti a ti fi abẹfẹlẹ ya niyakuya, nigbati awọn miran yio wọ asọ ti a kọ oniruru nkan ti ko dara si sibẹ, wọn yio wipe ọ̀làjú ni, sibẹ wọn yio wipe àsà igbalode ni, eleyi ni aposteli nã nwipe ki a fà sẹhin kuro ninu awọn asọ buburu wọnyi ki a si má a wọ asọ to dara, ki a mã wọ asọ to fi ògo fun orukọ Oluwa.... Awọn miran yio wọ asọ tó dára, sugbọn wọn ki yio fa "polo" ọrùn asọ wọn sókè dipo ki wọn tẹ̀ẹ́ silẹ, wọn yio ma sọ wipe awọn nsakọ tabi hùwà ìgbàlọ̀dé. Eleyi na ni aposteli Peteru wipe ó yẹ ki a fà sẹhin kuro ninu nkan wọnyi. 

Nitori ìlèpa ile aiye, nitori ìfẹ́ ati di ọlọ́rọ̀, nitori ifẹ owó, awọn òbí miran kò ri aye fun awọn ọmọ wọn mọ́, isẹ́, isẹ́, isẹ́ sá á ni wọn yio ma pariwo ti wọn yio si ma lepa, bẹsini awọn agbalagba si wipe, "ọmọ ti a kò kọ́ ni yio gbe ile ti a kọ́ tà", nitorina, Ọlọrun nfẹ ki a mã fi aye silẹ lati mã kọ́ awọn ọmọ wa, Ọlọrun nfẹ ki a ma mọ nkan ti wọn nse. Iru ere wo ni wọn nwo lori ẹ̀rọ amohun-maworan? Iru orin wo ni wọ́n yàn layo lati má a gbọ, se orin aiye ni tabi orin to dàpọ̀ mọ ihinrere?

Láì fà sẹhin kuro ninu ilepa ati ifẹ owo, a ò ni le mojuto awọn eleyi, a ò ni le lo akoko to tọ́ to si yẹ pẹlu awọn ọmọ wa.  Ọrọ̀ aposteli yi kan awọn olori ati awọn alasẹ wa gbogbo nã, nitori ọpọ awọn tó bá ti di olori, nse ni wọn ma nko ohun aiye jọ, wọn yio ní ọ̀kẹ́ àìmọye ọkọ̀, wọn yio ni ọkọ ofurufu oniruru, wọn yio ni ọpọ ìyàwó, wọn yio ni ọpọ ọmọ-ọdọ, gbogbo ile ìfowó pamọ́sí ni wọn yio ni owó si... wọn yio ma sọ wipe awọn ti jẹ ọpọlọpọ ìyà ninu aiye, nitorina, lasiko ti Ọlọrun ngbà fun awọn yi, awọn fẹ́ jẹ aiye na dáradára. Ifẹkufẹ ara ni eleyi ti wọn nmusẹ yi, Ọlọrun si wipe nse ni ki wọn o fa sẹhin kuro ninu rẹ ki ọkan wọn bàá le ni isinmi. Ẹ jẹ ka gbọ ohun ti Ọlọrun pa lasẹ fun awọn olórí lati se ti wọn ba fẹ jẹ olori ti yio fi Ọlọrun hàn nitotọ.  

"Sugbọn oun (olori) kò gbọdọ kó ẹsin jọ fun ara rẹ, bẹni ki o mase mu awọn eniyan pada lọ si Egipti, nitori ki o ba le kó ẹsin jọ: nitori OLUWA ti wi fun nyin pe, ẹyin kò gbọdọ tun pada lọ ni ọna nã mọ. 

"Bẹni ki o mase ko obinrin jọ fun ara rẹ, ki àyàa rẹ̀ ki o ma ba yipada; bẹni ki o mase ko fadaka tabi wura jọ fun ara rẹ ni ọpọ̀lọpọ̀" (Deut 17:16-17)  

Ọlọrun lo nfun awọn ọmọ Israeli lasẹ lati ipasẹ woli Mose wipe ohun ti awọn ti wọn ba jẹ olori tabi ọba wọn nilati ma se ni eleyi ki wọn o ba le se aseyọri ninu ètò ìsèjọba wọn. A o ri wipe akojọpọ gbogbo ọrọ yi ni fifa-sẹhin kuro ninu ifẹkufẹ ara, ki ọkan irufẹ awọn olori bẹ́ẹ̀ bàá le se dede, ki irufẹ ọkan wọn ba le sinmi ninu Oluwa. Nitori ọkàn to sinmi ni ọkan ti yio darí awọn enia ba bótise tọ́ ati botise yẹ. :)Ohun to panilẹkun loni ni wipe, ọpọ awọn olori aw ninu ihinrere, awọn olori wa ninu ìgbàgbọ́, ọpọ wọn lo buru ju awọn olori inu aiye lọ, nitoripe ọpọ wọn lo nko oniruru ohun aiye jọ fun ara wọn, wọn nko awọn eniyan pada lọ sinu ìwà ati àsà aiye lati le ri daju wipe awọn n ni ọrọ̀ sí i, eleyi ló mú ki ihinrere lọ sílẹ̀ loni, ti ihinrere si ndabi alailagbara mọ, ti o si ndi ìmirísí ati ìsọ̀rọ̀ òdì si larin awọn alaìgbagbọ gbogbo. Lati bori awọn nkan wọnyi, aposteli Peteru wipe ka fà sẹhin kuro ninu awọn ifẹkufẹ ara wọnyi ki ọkan wa bà á le bọ lọ́wọ́ ogun àìnidi. :)Bi a ba le fa sẹhin kuro ninu awọn ifẹkufẹ ara wọnyi, igbagbọ wa yio tubọ ma dagba si tobẹ ti yio si má a wuni.  

(7) SÙÚRÙ:  Ẹni-oju-nkan ko le se isẹ́ àgbẹ̀. Ẹni-oju-nkan ko le è ba Ọlọrun rìn. Tóbá jẹ wipe ojú nkan woli Elisa ni gẹgẹbi oju tise kan ìkan lara awọn ọmọ isẹ rẹ to njẹ Gehasi, o daju wipe kò ni ri ibukun ọ̀gà rẹ, woli Elija, gbà. (II A. Ọba 5).... Tóbá jẹ wipe oju kan woli Enọku ni, oun kì bá ti ni isipopada kuro ninu aiye lai tọ ikú wò.... Tò bá jẹ wipe ojú kán Abrahamu bàbá ni, o hàn wipe gbogbo ileri ti Ọlọrun se fún-un kò ni wá si imusẹ....Gẹgẹbẹ nã ni irugbin igbagbọ yi se ri. Irugbin igbagbọ ti yio dagba gidigidi, o nilo suru lati ọdọ ẹniti irugbin na wa ninu aye rẹ.  

"Ki si ise bẹ́ẹ̀ nikan, sugbọn awa si nsogo ninu wahala pẹlu: bi a ti mọ̀ pe wahala nsisẹ sùúrù;

"Sùúrù nsisẹ ìrír; ati iriri ni o nsisẹ ìrètí:  

"Ìrètí ki si idojutini: nitori a ti tan ifẹ Ọlọrun ká wa lọkan lati ọdọ Ẹmi Mimo wá ti a fifun wa" (Rm 5:3-5)  

Bi àgbẹ̀ ba gbin nkan yio ni suru tititi irugbin na yio fi hù jade, lẹhin igbato ba hù jade tan yio tun ma tulẹ̀ sidi rẹ titi ti yio fi dagba ti yio si bẹrẹ sini mu èso jade. Bẹna ni irugbin igbagbọ to mbẹ ninu wa, nse ni a nilati ni suru fun irugbin na ti a ó si má a roko sí i titi ti yio fi dàgbà ti yio si mã mu eso jade.  


ORÍ KẸFÀ: 

DÍDÀGBÀ GIDIGIDI  

ìgbàgbọ́ ti yio dagba gidigidi ninu aiyé onigbagbọ jẹ igbagbọ to nse gbogbo ọrọ Ọlọrun patapata.  

"Nitori ẹnikẹni ti o ba se ifẹ Ọlọrun, oun nã ni arakọnrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi" (Mk 3:35; Mt 12:50; Jak. 1:22; Ifi 1:3e) 

Irufẹ igbagbọ yi jẹ eleyi ti yio fi gbongbò rẹ mulẹ daradara ninu ọnà nã, ani ninu ọrọ Ọlọrun. Eleyi ni wipe yio ma ri omi mu lati ibito jìnnà gidigidi, bẹna si ni afẹfẹ súẹ́súẹ́ ko ni le bì í subu.  

"Nitorina bi ẹyin ba ti gba Kristi Jesu Oluwa, bẹni ki ẹ mã rin ninu rẹ:  

"Ki ẹ fi gbòngbò múlẹ̀, ki a si gbé yin ró ninu rẹ, ki ẹ si fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ yin gẹgẹbi ati kọ yin, ki ẹ si mã pọ̀ ninu rẹ pẹlu idupẹ.  

"Ẹ ma kiyesara ki ẹnikẹni ki o mase fi ìmọ̀ ati ẹtan asan dì yín ni ìgbèkùn, gẹgẹbi itan eniyan, gẹgẹbi ipilẹsẹ ẹkọ aiye, ti ki ise bi ti Kristi.  

"Nitoripe ninu rẹ ni gbogbo ẹ̀kún iwa-Ọlọrun ngbé ni ara-ìyára  

"A sì ti se nyin ni kikun ninu rẹ, ẹniti ise orí fun gbogbo ijọba ati agbara " (Kol 2:6-10)  

"Bi ẹyin ba duro ninu igbagbọ, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro sinsin, ti ẹ ko si yẹsẹ̀ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ, eyiti a si ti wãsu rẹ ninu gbogbo ẹdá ti o mbẹ lábẹ́ ọ̀run, eyiti a fi emi Paulu se iransẹ fun" (Kol 1:23)  

Igbagbọ ti a nsọ wipe o ti fi gbòngbò rẹ múlẹ̀ yi, ti ó sì ti nri oúnjẹ lati inu ilẹ ati awọn ohun miran lati inu afẹfẹ awọn eleyi ti Ọlọrun ti pèsè fun ìwúlò ati idagbasoke igi nã, irufẹ igbagbọ yi ni o mã nwa nigbati eniyan ko ba duro de àlá, ìran, àsọtẹ́lẹ̀ ki o to mã se ifẹ Ọlọrun. Awọn miran, bi wọn kò ba ìtí lá àlá wọn ko ni le se ifẹ Ọlọrun. Ọpọ̀ ìgbà ni oniwasu yio sọ wipe nkan kò bá ìhinrere mu, sugbọn irufẹ awọn eniyan na ko ni gba iwasu na wọle àyàfi igbati wọn ba tó la ala ki wọn o to le yipada patapata si ọrọ nã. Àìmọye ìgbà ni ẹlomiran ti kàá wipe ohun irira ni fun obinrin tabi ọkunrin lati mu ohun ti ise ti ọkunrin tabi obinrin wọ̀, sugbọn sibẹ wọn ko yipada wọn wipe ninu majẹmu lailai ni ọrọ na wa ati wipe ko kan awa ti majemu titun (Dt. 22:5), sugbọn ileri ati ọrọ Ọlọrun bí i wipe, 

"Emi mọ ero ti mo ro si nyin, ni Oluwa wi, ani iro alafia, ki si ise fun ibi, lati fun nyin ni igba ikẹhin ati ireti" (Jer. 29:11) 

To wa ninu majẹmu lailai na ni yio kan wọn nitoripe o jẹ ileri Ọlọrun, sugbọn ọrọ to ba wọn wi ni wọn yio yọ sẹhin, nitoripe o ba wọn wi, tabi nitoripe wọn ro wipe aiye ti laju kọja iyẹn, sugbọn aiye kì í lajú kọja awọn ileri yoku.  Awọn miran yio tilẹ wipe o di igbati awọn bá tó lá àlá ki awọn si ri wipe Ọlọrun sọ fun awọn wipe ọrọ nã kan wọn ki wọn ó tó yípadà. Irufẹ ẹniyi ko ti ni igbagbọ to ndagba gidigidi...nitoripe ẹnito ba ti ni igbagbọ to ndagba gidigidi ni ẹniti yio ma se ifẹ Ọlọrun patapata, ani ẹniti yio ma se gbogbo ifẹ Ọlọrun, ki ise ẹniti yio ma yọ ẹyọkan sẹhin, sugbọn ti yio si ma se awọn yoku, ki ise ẹniti yio ma duro de àlá, tabi ko duro de ìran, tabi ko duro de asọtẹlẹ ko to ma sá fun ẹsẹ ati gbogbo awọn ohun to farajọ ibi.  Awọn miran wọn ko le se ifẹ Ọlọrun nigbati o ba ku awọn nikan. Fun apẹrẹ, ẹniti isẹ́ gbé lọ si ilu miran, bóyá nilu ti isẹ tilẹ gbe lọ nã ko si ihinrere nibẹ̀, iru ẹni bẹ kò ni le se ifẹ Ọlọrun mọ́ ni ibito de na. Sugbọn ti ẹniti igbagbọ rẹ ti dàgbà gidigidi kò ríbẹ, yálà o wa nibiti awọn ará wà, tabi ibiti awọn onigbagbọ kò sí, yio mã se ifẹ Ọlọrun sá á ni. Ifẹ Ọlọrun sise ti di omi ara ati ẹjẹ rẹ, fun irufẹ awọn eniyan wọnyi, ifẹ Ọlọrun jẹ bẹni ati amin. Nitori gbogbo ohun ti wọn ba ti ri ninu ọrọ Ọlọrun ni wọn yio ma se.  

"Sugbọn bi Ọlọrun ti jẹ olóòtọ́, ọrọ wa fun nyin ki ise bẹni ati bẹni ati bẹkọ.  

"Nitoripe Jesu Kristi, ọmọ Ọlọrun, ẹniti ati wasu rẹ larin yin nipasẹ wa, ani nipasẹ emi ati Silfanu ati Timoteu, ki ise bẹni ati bẹkọ, sugbọn ninu rẹ ni bẹni.  

"Nitori gbogbo ileri Ọlọrun ninu rẹ ni bẹni: ati ninu rẹ pẹlu ni Amin, si ogo Ọlọrun nipasẹ wa" (II Kọr 1:18-20).  

Irufẹ igbagbọ yi lo nduro ninu ọrọ Ọlọrun nibi gbogbo  

"Nitorina Jesu wi fun awọn Juu ti o gbà a gbọ pe, bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ̀ mi, nigbana ni ẹyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitotọ." (Jhn 8:31)  

ORÍ KEJE: 

ISẸ́ ÌGBÀGBỌ TO NDÀGBÀ  

Díẹ lara awọn nkan to ma njẹ àbájade fun irugbin igbagbọ to ndagba gidigidi niwọnyi: 

(1) Bi irugbin ba ti dàgbà, nigbato ba to asiko kan yio bẹ̀rẹ̀ sini mu èso jade  

"Sugbọn ẹniti o gba irugbin si ilẹ rere ni ẹniti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ nã, ti o si yé e; oun ni o si so eso pẹlu o si so omiran ọgọrọrun, ọmiran ọgọtọta, omiran ọgbọ-ọgbọn" (Mt 13:23)  

"Gbogbo ẹka ninu mi ti ko ba so eso, oun a mú u kuro: gbogbo ẹka ti o ba si so eso, oun a wẹ̀ẹ́ mọ́, ki o le so eso sí i" (Jhn 15:2) 

(2) Igbagbọ to ndagba yio jẹ ilé fun awọn miran  

"Eyiti o kere ju gbogbo irugbin lọ; sugbọn nigbati o dagba, o tobi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, o si di igi, tóbẹ́ẹ̀ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun si wa, wọn si ngbé ori ẹka rẹ" (Mt. 13:32)  

(3) Yio jẹ ibi ãbo tabi ibòji fun awọn miran  

"O sì tẹle èniyan Ọlọrun na lẹhin, o si ri i, o joko labẹ igi oaku kan" (I A. Ọba 13:14a)  

"... O si wá, o si joko labẹ igi juniperi kan..." (I A. Ọba 19:4b)  

"Orukọ Oluwa, ile-isọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ, o si là" (Owe 18:10)  

Iru igbagbọ yi ni Abrahamu fi gba Lotu aburo rẹ la kuro lọwọ ogun (Gen 14)  

(4) A le lo ẹka rẹ lati fi se awọn nkan miran bí i kikọ ile abbl.  

(5) Yio le ba Ọlọrun sọrọ gẹgẹ bi ọrẹ-si-ọrẹ tabi bi Baba si ọmọ.  

"Ẹni meji le rin pọ̀, bikosepe wọn rẹ́?" (Amosi 3:3; Gen 18:16-33) 

(6) Iru igbagbọ yi ni Ọlọrun kì í fi asiri ohun to fẹ se pamọ fun 

"Nitori Oluwa ki yio se ohunkankan, sugbọn o fi ohun ikọkọ rẹ han awọn woli iransẹ rẹ" (Amosi 3:7)  

(7) Nipasẹ igbagbọ yi ni a lè fi bá Ọlọrun rìn.  

"Enọku si ba Ọlọrun rìn: oun kò sì sí nitori ti Ọlọrun mu u lọ" (Gen 5:24) 

(8) Irufẹ igbagbọ yi ni a le lọ gbìn si ibomiran, eredi ni wipe o nso èso. Ẹniti o niru igbagbọ yi, yio ni suru, bibeli si wipe suru nsisẹ ìrírí (Rm 5:4) nipasẹ iriri rẹ ti awọn miran ti kọ́ ohunkan tabi omiran lara rẹ, wọn yio mã sọ ọ́ nibomiran fun awon miran lati le è kọ́ ẹ̀kọ́ 

"Nkan wọnyi si se si wọn bi àpẹrẹ fun wa: a si kọ̀wé wọn fun ikilọ awa ẹniti igbẹ̀hìn aiye dé bá" (I Kor 10:11) 

(9) O wúlò ninu sísí òkè nidi  

"Jesu si dahun o si wi fun wọn pe, ẹ ni igbagbọ si Ọlọrun.  

"Lotọ ni mo wi fun nyin, ẹnikẹni ti o ba wi fun oke yi pe, sidi, ki o si bọ sinu òkun: ti ko ba si siyemeji ni ọkàn rẹ, sugbọn ti o ba gbagbọ pe ohun ti oun wi yio sẹ, yio ri bẹ́ẹ̀ fun un" (Mk 11:22-23) 

Ki iru igbagbọ ti Jesu Kristi nsọ nihinyi ma bã sokunkun si awọn ayanfẹ, aposteli Paulu ninu iwe rẹ sọ iru igbagbọ nã.  

"...Bi mo si ni gbogbo igbagbọ, tóbẹ́ẹ̀ ti mo le si awọn oke nla nipo..." (I Kọr 13:2b-d)  

(10) A ma nfi iru igbagbọ bẹ́ẹ̀ sògo, o jẹ ohun àmúsògo  

"Tobẹ́ẹ̀ ti awa tikarawa nfi yin sogo ninu ijọ Ọlọrun, nitori suru ati igbagbọ nyin ninu gbogbo inunibini ati wahala yin ti ẹyin nfarada" (II Tess 1:4)  

IBEERE?  Njẹ bawo ha ni igbagbọ rẹ? Bawo ni igbagbọ mi? Se eleyi to ndagba ni tabi eleyi to wa lojukanna?  



NIPA IWE YI: ... 

Igbagbọ to ndàgbà ki ise ohun to nwa lọjọkan bikose ohun ti yio la oniruru nkan kọjá, sugbọn sibẹ ti kò ni yingin, bùkù, dínkù tabi lọ sẹhin bikosepe ki o mã pọ̀ sí i.  Iru igbagbọ yi ni Ọlọrun pè wá si gẹgẹ bi ọmọ Rẹ ati ọmọlẹhin Rẹ...  

NÍPA ONKỌ̀WÉ YI: 

Arakunrin Ogundare 'Segun jẹ olùkọ́ Ọrọ Ọlọrun ni ọpọ ibi ni orilẹ-ede Nigeria.  Ọmọ bibi ilu Ilẹmẹsọ-Ekiti ni ipinlẹ Ekiti orilẹ-ede Nigeria ni ise. Oun ati olólùfẹ́ rẹ̀ fẹ́ran Ọlọrun ati ihinrere Kristi Jesu. Iwe yi jẹ ọkan lara awọn iwe rẹ lede abinibi.


Ogundare Olusegun


Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan