( “Èmi o wi fun Ọlọrun pe, Ìwọ li abo ati odi mi; Ọlọrun mi, ẹniti emi gbẹkẹle” (O. Daf. 91: 2:)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “B’orukọ Jesu ti dun to Ogo ni fun orukọ rẹ O tan banujẹ at’ ọgbẹ Ogo ni fun orukọ rẹ Ègbè Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’orukọ Oluwa, Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’orukọ Oluwa,” Orin Titun na Nìyí 1. Emi o wi f’ Olodumare pe Iwọ ma ni Ọlọrun mi ‘Gba gbogbo lemi o ma wipe Iwọ ma ni Ọlọrun mi Ègbè Iwọ lodi mi, Iwọ labo mi Iwọ ni Ọlọrun mi, Iwọ lodi mi, Iwọ labo mi Iwọ ni mo gbẹkẹle 2. Nki yo bẹru ibi Kankan Iwọ ma ni Ọlọrun mi...
Comments
Post a Comment