Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan
( “Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ pe, lotọ ni ikore pọ, sugbọn awọn alagbase ko to nkan” (Matt. 9:37)) Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi: Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa. Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi “Bibeli Mimọ tọrun Ọwọn isura temi ‘Wọ ti nwi bi mot i ri ‘Wọ ti nsọ bi mo ti wa ” Ẹniti o Kọrin Yi: John Burton Orin Titun na Nìyí 1. Jesu sọ pe ‘kore pọ ‘Gbọn ‘wọn ‘lagbase o to nkan F’eyi ẹ b’Oluwa ‘kore Ko ran awọn alagbase wa 2. Mo nran yin b’ọd-agutan Si arin awọn ikoko ‘Torina ẹgbọn bi ejo Bi adaba ẹ ni wa tutu 3. Nile kile tẹ ba wọ Ẹ wip’alafia fun ‘le yi Alafia yin yo ba le ‘Wọn ọmọ Alafia ibẹ 4. Lẹhin na ẹ ba wọn sọ Ọrọ ijọba Ọlọrun Ẹ bẹrẹ latibi tẹ wa Lọs’ orilẹ ede aiye
Comments
Post a Comment