Ó ti Múmi Gbàgbé Ìtìjú Ìgbà Èwe mi


(Bíbélì wípé, “má bẹrù, nitori ojú ki yio ti ọ: bẹni ki o mase dãmu; nitori a ki yio dójú ti ọ; nitori iwọ o gbagbe itiju igba ewe rẹ, iwọ ki yio si ranti ẹgàn iwa opo rẹ mọ” (Isa. 54:4))

Àfiyesi Pàtàkì Lati Ọwọ Ẹnito kọ Orin yi: Ti a ba ti le mọ orin inu iwe yi, a ti mọ orin titun ti mo kọ yi niyẹn.


Orin Inu Iwe na Niyi.

Ẹ dide, Ọmọ igbala
Ẹyin t’ẹ fẹ Oluwa
Dide, ilu alagbara
Ki ọta to de Sion

Ègbè

F’agbara rẹ kọrin kikan,
Bi iro omi okun
Nipa ẹjẹ Kristi Jesu,
Awa ju asẹgun lọ
Awa ju asẹgun lọ
Awa ju asẹgun lọ
Nipa ẹjẹ Kristi Jesu,
Awa ju asẹgun lọ



Orin Titun Na

1. Agbara rẹ ti pọ lapọju
Jehofa nla Ọba wa
Ọba angẹli at’eniyan
To gbaiye ka ori omi

Ègbè

Ọlọrun’yanu l’ Ọlọrun yi
Jehofa Oluwa wa
‘Tori o ti mu ki ngbagbe
Itiju igba ewe mi
Itiju igba ewe mi
Itiju igba ewe mi
‘Tori o ti mu ki ngbagbe
Itiju igba ewe mi


2. Ki a to bi mi ‘wọ mọ mi
‘Gba mow a ‘nu iyami
Iwọ ti pe mi lorukọ
‘Wọ yami sọtọ fun Ọ

Ègbè

3. Gba mo rọ mọ ‘mu iya mi
Iwọ ni o nsabo mi
‘Wọ ko fi aye fun ọta
Lati bori ẹmi mi

Ègbè


4. Nigbakan rim o sisẹ lasan
Mo lo agbara mi lofo
(Ti) gbogbo isẹ mi ko lere
Ti mo d’ẹni yẹpẹrẹ

Ègbè


5. Nigbana mo nrin nigbawẹ
T’omije si j’ounjẹ mi
‘Tori gbogbo eniyan mbere
Ibi t’Ọlọrun mi wa

Ègbè


6. Ngo mọ pe ‘wọ nri gbogbo rẹ
Pe iwọ ko gbagbe mi
Bi obinrin ko ti le gbagbe
Ọmọ ti o nfọmu fun

Ègbè

7. Li akoko itẹwọgba
Ni iwọ ti gbọ temi
Ati li ọjọ igbala
Ni iwọ ti ranmi lọwọ

Ègbè


8. ‘Wọ y’ẹgan aye mi pada
‘Wọ ti n’omije mi nu
O forin ọtun simi lẹnu
‘Wọ ti funmi ni sẹgun

Ègbè


9. Emi wolẹ mo júbà
Fun iwọ Ẹlẹda mi
Ọba Àìkú, Àìrí, Àìsá
Mo ke Kabiyesi rẹ

Ègbè


10. Níwọn igbati ngo wa laye
Lemi yio ma yin Ọ
Ngo ma ke Alleliua
Si Ọ Oludande mi

Ègbè

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan