Orin Ìsẹgun ati Ọpe
(“On o gbe iku mi lailai; Oluwa
Jehofa yio nu omije nu kuro li oju gbogbo enia; yio si mu ẹgan enia Rẹ kuro ni
gbogbo aiye: nitori Oluwa ti wi i.” (Isa. 25:8))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe
daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ
gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ
wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“B’Ọlọrun Ọba Ọrun
Ti ma nsọrọ n’ igbani
O tun ba wa sọrọ bẹ loni
Arakunrin o tọ ni
Ohun t’O ba wi fun ọ
Ohun kan l’aigbọdọ mase
gbọran
Ègbè
Sa gbọran, sa gbọran
Eyi ni ‘fẹ rẹ
‘Gbat’o ba ransẹ si ọ
Ohun kan ni ki o se
Sa gbọran, sa gbọran
Orin Titun na Nìyí
1. Emi o si mu gbekun
Awọn enia mi pada
Ngo si gbe wọn ro bi ti gbani
Emi o si wẹ wọn nu
Kuro ninu ẹsẹ wọn
Ngo si dari gbogbo ẹsẹ wọn ji wọn
Ègbè
Ẹ f’ọpẹ, f’Oluwa
Oluwa ‘wọn ọmọ-ogun
Nitori t’Oluwa seun
Anu rẹ duro lailai
Ẹ f’ọpẹ, f’Oluwa
2. Ngo parọ orukọ wọn
‘Rukọ ọtun ni ngo fun wọn
Wọn ki o pe wọn nikọsilẹ mọ
Tabi ẹni ahoro
‘Tori mo ra wọn pada
Emi funrami ni mo gba wọn la
Ègbè
3. Ngo nu omije wọn nu
Ngo m’ẹgan wọn kuro
Gbogbo awọn to duro de mi
Wọn yok un fun ayọ mi
Wọn yok un f’alafia
Inu wọn yio si dun sigbala mi
Ègbè
4. Ọkan wọn yo si dabi
Ọgba ti a bomi-rin
Wọn ki o rin nikanu mọ rara
Ọmọde ati agba
Obinrin at’ ọkunrin
Ni yo kọrin titun s’orukọ mi
Ègbè
5. Ẹfọpẹ fun Oluwa
Gbogbo ẹyin enia rẹ
“Tori Oluwa ti s’oun ‘yanu
O ti wo ilẹ wa san
Oun sit i gba wa la
Oun ti gbewa leke ọta gbogbo
Ègbè
Comments
Post a Comment