Orin Kan: Ìfẹ Li Àkoja Òfin

(“Ìfẹ ki ise ohun buburu si ọmọnikeji rẹ: nitorina ifẹ li akoja ofin.” (Rom 13:10))


Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.



Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Duro, duro fun Jesu
Ẹyin ọm’ ogun Krist’
Gbe asia Rẹ s’oke
A ko gbọdọ fẹ ku;
Lat’ isẹgun de ‘sẹgun
Ni y’o tọ ogun Rẹ
Tit’ ao sẹgun gbogb’ ọta
Ti Krist’ y’O j’Oluwa”
                                    
                
Orin Titun na Nìyí
1. Ìfẹ li akoja ofin
“Tori ki s’ohun ibi
Biwọ ba f’ẹnikeji Rẹ
‘Wọ k’ yo le se nibi
Iwọ ko ni le jale
Sojukokoro ohun tirẹ
Tabi gbero ‘paniyan
‘Tori ‘fẹ ngbenu rẹ

2. Ìfẹ li akoja ofin
“Tori ki s’ohun ibi
Ko si le se pansaga
Tabi ko gbero agbere
Ko si le jẹri eke
Ditẹ tabi se lara
Torohun ni akoja ofin
Ofin mimọ lo nse

3. Ìfẹ li akoja ofin
“Tori ki s’ohun ibi
Lati m’ofin to tobiju
Amofin tọ Jesu lọ
O mbere asẹ nla
Ninu gbogb’ awon ofin
O dahun ‘pe fifẹ Ọlọrun
‘Tẹnikeji lasẹ nla

4. Ìfẹ li akoja ofin
“Tori ki s’ohun ibi
A ma mu suru funni
A si ma seun funni
Ki sọrọ igberaga
Ki w’ohun tirẹ nikan
Ki yọ si aisododo
A ma yọ n’nu otitọ

5. Ìfẹ li akoja ofin
“Tori ki s’ohun ibi
Nitorina ẹ gbe fẹ wọ
‘Yi lamure iwa pipe
Ẹ faraqda fun ra yin
Kẹ dariji ara yin
Bi Kristi ti se se fun yin
Ẹ se bẹ fun ara yin.

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan