Orin Kan: Ìwọ se Iyebiye

(“Niwọn bi iwọ ti se iyebiye to lohu mi, ti iwọ se ọlọla, emi si ti fẹ ọ: nitorina emi o fi enia rọpo rẹ, ati enia dipo ẹmi rẹ” (Isa 43:4))


Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.


Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Borukọ Jesu ti dun to
Ogo ni fun Orukọ Rẹ
O tan banujẹ at’ ọgbẹ
Ogo ni fun Orukọ Rẹ
Ègbè
Ogo f’okọ Rẹ, Ogo f’okọ Rẹ
Ogo f’orukọ Oluwa
Ogo f’okọ Rẹ, Ogo f’okọ Rẹ
Ogo f’orukọ Oluwa”
                                       
             
Orin Titun na Nìyí
1. Ma faye gba ‘bẹru ni inu rẹ
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Iwọ ẹniti mo ti rapada
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Ègbè
Ha! ‘Wọ se ‘yebiye, Ha! ‘Wọ se ‘yebiye
Ha! ‘Wọ se ‘yebiye loju mi
Ha! ‘Wọ se ‘yebiye, Ha! ‘Wọ se ‘yebiye
Ha! ‘Wọ se ‘yebiye loju mi


2. Emi ti pe ọ ni orukọ rẹ
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Temi ni ọ nki yo fi ọ silẹ
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Ègbè


3. Nigbati ‘wọ ban la omi kọja
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Emi ki yo jẹ kan bo ọ mọlẹ
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Ègbè

4. Bi iwọ ba nrin ni inu ina
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Emi ki yio jẹ ki ina jo ẹ
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Ègbè

5. Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Emi l’Olugbala ko sẹlomi
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Ègbè

6. Mo ra ọ pada ni ọwọ iku
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Mo f’ẹlomiran dipo ẹmi rẹ
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Ègbè

7. Iwọ ni temi mo fẹ ọ pupọ
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Nki yo fi ọ silẹ lai ati lailai
‘Tori iwọ se ‘yebiye
Ègbè

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan