Orin Kan: Nigba Meje li Õjọ Ni Emi Nyin Ọ
(“Nigba meje li õjọ li emi nyin Ọ
nitori ododo idajọ Rẹ.” (Psa. 119:164))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe
daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ
gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ
wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“L’ojojumọ l’angbe Ọ ga
Nigbati ilẹ ba mọ
T’aba kunlẹ lati yin Ọ
Fun anu ti owurọ
Orin Titun na Nìyí
1. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
‘Gba mob a rant’ ohun gbogbo
Ti iwọ ti se fun mi
2. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
‘Tori odod ‘dajọ rẹ
Tiwọ se larin eniyan
3. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
Ọba to r’ẹmi mi kuro
Ninu iparun gbogbo
4. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
Ẹnito fi iseun ifẹ
Oun ‘yọnu demi lade
5. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
Ẹniti o ti wo mi san
To si tan gbogb’ arun mi
6. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
Ẹnit’o fi mọlẹ bora
Bi a ti f’asọ bora
7. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
Ẹnito ran ọrọ rẹ jade
Ta si mu mi lara da
8. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
Ẹnito gbawa kuro n’nu
‘Parun t’ajakalẹ arun
9. Nigba
meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
Ọba to fa mi yọ kuro
Ninu ojiji iku
10. Nigba meje lojọ lemi
Un fiyin f’orukọ rẹ
Ọba to ja gbogbo ide mi
To si sọ mi d’omnira
Comments
Post a Comment