Orin Kan: Ó ti tó Wákàti

(“Ati eyi, bi ẹ ti mọ akoko pe, o ti to wakati nisisiyi fun nyin lati ji loju orun: nitori nisisiyi ni igbala wa sunmọ etile ju igbati awa gbagbọ lọ.” (Rom 13:11))


Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.


Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ẹlẹsẹ, ẹ yipada
Ese ti ẹ o fi ku?
Ẹlẹda yin ni mbere
To fẹ ki ẹ ba On gbe
Ọran nla ni O mbi yin
Isẹ ọwọ rẹ ni yin
A! Ẹyin alailọpẹ
Ese t’ẹ o kọ ‘fẹ Rẹ”
                             
                       
Orin Titun na Nìyí
1. Eyi ni wakati na
Lati ji loju orun
‘Tori nisisiyi ni
‘Gbala wa sunmọ etile
Ju ‘gbat’ awa gbagbọ lọ
Our bu kọ ja lọ tan
Ilẹ ma si fẹrẹ mọ
Torina ẹ yipada

2. Eyi ni wakati na
Lati ji loju orun
Ki a bọ isẹ ara
Tise t’okunkun silẹ
Ki a si gbe ‘hamọra
‘Hamọra timọlẹ wọ
Ki a ma rinrin titọ
Gẹgẹb’awọn ‘mọ mọlẹ

3. Eyi ni wakati na
Lati ji loju orun
Ki a mu iwa eri
Ati iwa wọbia
‘Rede our, mọti para
Ija oun ilara
Ka mu kuro lọna wa
Kama rin pẹlu Kristi

4. Eyi ni wakati na
Lati ji loju orun
Ki awa mase pese
Pese fun isẹ tara
Awa ko si gbọdọ mu
Ifẹkufẹ tara sẹ
Sugbọn eyi ni ka se
Kagbe Jesu Kristi wọ

5. Eyi ni wakati na
Lati ji loju orun
Ki a si d’ẹni titun
Ninu ẹmi inu wa
Ẹ si jẹ ki a ma rin
Nipa t’ẹmi Ọlọrun
Ka gb’ọkunrin titun wọ
Eyit’ ada npa Ọlọrun

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan