Orin Kan: Orin Àwọn Orin
(“Àdàbà mi, ti ó wà ninu pàlàpala
okuta, ni ibi ikọkọ okuta, jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbọ ohun rẹ; nitori
didun ni ohun rẹ, oju rẹ si li ẹwà” (O. S. 2:14))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe
daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ
gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ
wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Mase foya ohunkohun
Ọlọrun y’O tọ ọ
Magbe ibi ikọkọ rẹ
Ọlọrun y’O tọ ọ
Ègbè
Ọlọrun y’O tọ ọ
Lojojumọ, lọna gbogbo
On y’O ma tọju rẹ
Ọlọrun y’O tọ ọ”
Orin Titun na Nìyí
1. Orin to ju orin lọ ni
Ni orin ifẹ jẹ
Orin to dun jọjọ leti
Ni orin ifẹ jẹ
Ègbè
Adaba mi jẹki
Emi ri oju ẹwa rẹ
Jẹk’ emi gbohun rẹ
Tor’ ohun rẹ ladun
2. Orin to dara lati gbọ
Ni orin ifẹ jẹ
Orin to dun ti ngo kọ fun ọ
Ni orin ifẹ jẹ
Ègbè
3. Orin ti nsọ nipa ‘fẹ rẹ
Ni orin ifẹ jẹ
Orin to nfi ẹwa rẹ han
Ni orin ifẹ jẹ
Ègbè
4. Nin’ orin ti mo ti mọ pe
Ni orin ifẹ jẹ
Ko s’abawọn lar’ olufẹ mi
Ni orin ifẹ jẹ
Ègbè
5. Orin to f’agbara ‘fẹ han
Ni orin ifẹ jẹ
Agbara ‘fẹ ko loduwọn
Ni orin ifẹ jẹ
Ègbè
6. Orin to sọ p’omi ko le
Ni orin ifẹ jẹ
Pana ‘fẹ lọkan olufẹ
Ni orin ifẹ jẹ
Ègbè
7. Orin to nsọ p’olufẹ mi
Ni orin ifẹ jẹ
Jẹ temi tit’ aiyeraiye
Ni orin ifẹ jẹ
Ègbè
Comments
Post a Comment