Orin Kan: Yínyin Oluwa Agbara Mi
(“Èmi o fẹ Ọ, Oluwa agbara mi.”
(Psa. 18:1))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe
daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ
gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ
wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ko su wa lati ma kọ orin
ti igbani
Ogo f’Ọlọrun Aleluiah
A le fi igbagbọ kọrin na
s’oke kikan
Ogo f’Ọlọrun Aleluiah
Ègbè
Ọmọ Ọlọrun ni ẹtọ lati ma
bu s’áyọ
Pe ọna yin ye wa si
Ọkan wa ns’afẹri Rẹ
Nigbose ao de afin Ọba wa
ologo
Ogo f’Ọlọrun Aleluiah
Orin Titun na Nìyí
1. Oluwa ni imọlẹ mi ati igbala mi
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Oluwa lagbara ẹmi mi nki yo bẹru
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ègbè
Tinu-tinu gbogbo ni ngo ma fi yin Oluwa
Niwaj’ awọn orisa
Lem’ o ma kọrin ‘yin si
Nitori seun ifẹ rẹ nitori otitọ rẹ
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
2. “Gbat’ awọn enia ibi at’ọta sunmọ mi
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Nitori wọn yio kọsẹ wọn yio subu
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ègbè
3. B’ogun tilẹ doti mi aya mi ki yo fo
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
B’ogun tilẹ dide si mi ọkan yo le
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ègbè
4. “Tori ni igba ipọnju Oun yo pa mi mọ
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ni inu agọ rẹ ni yio pa mi mọ si
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ègbè
5. ‘Gbana yo gbemi soke ka ori apata
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
“Gbayi lori mi gbe soke ju ti ọta lọ
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ègbè
6. “Gbati baba oun iya mi ba kọ mi silẹ
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Nigbana ni Oluwa de to si tẹwọgba mi
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ègbè
7. Ohun kan ti emi ntọrọ lọwọ Oluwa ni
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ki emi le ma gbenu ‘le rẹ lọjọ aiye mi
Ngo ma yin Oluwa agbara mi
Ègbè
Comments
Post a Comment