Orin Kan: Ìdí Lati ma Bẹru Lasiko Àjakalẹ Arun Kòrónà Farọsi


(“Èmi o wi fun Ọlọrun pe, Ìwọ li abo ati odi mi; Ọlọrun mi, ẹniti emi gbẹkẹle” (O. Daf. 91: 2:))

Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.


Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“B’orukọ Jesu ti dun to
Ogo ni fun orukọ rẹ
O tan banujẹ at’ ọgbẹ
Ogo ni fun orukọ rẹ

Ègbè
Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ,
Ogo f’orukọ Oluwa,
Ogo f’okọ rẹ, Ogo f’okọ rẹ,
Ogo f’orukọ Oluwa,”
           

Orin Titun na Nìyí
1. Emi o wi f’ Olodumare pe
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
‘Gba gbogbo lemi o ma wipe
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ègbè
Iwọ lodi mi, Iwọ labo mi
Iwọ ni Ọlọrun mi,
Iwọ lodi mi, Iwọ labo mi
Iwọ ni mo gbẹkẹle

2. Nki yo bẹru ibi Kankan
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
‘Tori mo ngbe ibi ikọkọ rẹ
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ègbè

3. Iwọ yo gba mi ‘nu kẹkun gbogbo
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ati nin’ ajakalẹ arun ibi
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ègbè

4. Nki yo bẹru kokor’ airi Kankan
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Eyi to nrin lọsan tabi loru
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ègbè

5. Iparun ti nrunni lọsangangan
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Wọn ki yo de sakani mi rara (tori)
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ègbè

6. ‘Wọ Oluwa lo nse abo mi
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Mo si f’Ọga Ògo se ibugbe
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ègbè

7. Oun o pami mọ labẹ iyẹ rẹ
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Otitọ rẹ lasa at’ apata mi
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ègbè

8. Yo si f’ẹmi gigun tẹmi lọrun
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
‘Gbala rẹ ni yo fi demi lade
Iwọ ma ni Ọlọrun mi
Ègbè

Comments

Popular posts from this blog

ÒWE YORÙBÁ (YORÙBÁ PROVERB)

Displacing Yourself to Please Others, It Does Not Mean They Would Pay You Back