Orin Kan: Ayọ Rẹ, Lagbára à Mi


(“… Ẹ mase banujẹ; nitori ayọ Oluwa on li agbara nyin” (Neh. 8:10d))

Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:       
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ẹkun ko le gba mi
Bi mo le f’ẹkun wẹju
Ko le mu ẹru mi tan
Ko le wẹ ẹsẹ mi nu,
Ẹkun ko le gba mi
Ègbè
Jesu sun, o ku fun mi
O jiya lori igi
Lati sọ mi d’ominira
On na l’O le gba mi”



Orin Titun na Nìyí
1. ‘Gbakan ri mo wa ninu
Ninu ibanujẹ nla
Ti ko sọna abayọ
Ti un o m’ohun mo le se
Ti ọna mi daru
Ègbè
Jesu n’omije mi nu
Jesu fun mi ni ayọ
Ayọ to fun mi tayọ
Ayọ Rẹ lagbara mi

2. ‘Gbakan ri omije ni
Ounjẹ mi lọsan loru
‘Gbat’ ọta nwi nigbagbogbo
Pe mbo l’Ọlọrun mi wa
Ti ko sọna abayọ
Ègbè

3. B’ida nin’ Egungun mi
L’ẹgan tawọn ọta ngan mi
‘Gba wọn nwi lojumọ pe
Ọlọrun rẹ ti o npe
Jẹ o ha le gba ọ?
Ègbè

4. Emi wi f’Ọlọrun mi
Ese tiwọ gbagbe mi?
Ese temi nrin n’gbawẹ
‘Tori inilara ọta?
Yara Kankan gba mi
Ègbè

5. Emi si se ireti
Nin’ apata igbala mi
Mo keep orukọ rẹ
O da mi lohun mb’aye nla
Ọlọrun mi gba mi
Ègbè

6. Banujẹ mi dayọ
Ẹkun mi si di ẹrin
‘Gbat’ Ọlọrun gbọ ‘gbe mi
To dahun adura mi
Banujẹ mi dayọ
Ègbè

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan