Orin Kan: Ẹ Yipada, Kí Ẹ Si Ye

(“Nitoripe Emi ko ni inu didun si iku ẹniti oku, ni Oluwa Ọlọrun wi: nitorina ẹ yi ara nyin pada, ki ẹ si ye” (Esek. 18:32))
 
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:       
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ko tọ kawọn mimọ bẹru
Ki wọ sọ ‘reti nu
‘Gba wọn ko reti ‘ranwọ rẹ
Olugbala yio de”.
            It is not meet for Saints to Fear (Yoruba edition)
Orin Titun na Nìyí
1. Owe tawọn kan npa nipe
Baba ti jẹ eso
Ajara kikan leso na
Ehin awọn ọmọ kan

2. Sugbọn Oluwa n’gbato gbọ
Si dawọn lohun pe
Ẹ ki yo raye lati pa
Owe yi mọ larin yin

3. ‘Tori gbogb’ ọkan ntemi
B’ọkan baba t’jẹ temi
Bẹni ọkan ọmọ pẹlu
Si ti se jẹ temi

4. Bọkan agba ti jẹ temi
Bẹni ọkan ọdọ
Gbogb’ ọkan to ba si ti sẹ
Kiku ni oun yo ku

5. Sugbọn b’enia kan bas i
Seyi to tọ to yẹ
To si nrin ninu asẹ mi
Yi ye ni oun yio ye

6. Sugbọn bi ọdọ kan ba wa
To n s’ohun ibi gbogbo
To tun nni talaka lara
Kiku lohun yok u                                                                                                     

7. Ọkan to ba sẹ ni yio ku
Ọmọ k’ yo r’ẹsẹ baba
Tabi ki baba r’ẹsẹ ọmọ
Ẹj’ ẹlẹsẹ wa lori rẹ

8. Sugbọn b’enia buburu
Bale yipada kuro
Ninu gbogbo ẹsẹ to nsẹ
Yiye loun yio ye

9. B’olododo ba yipada
Kuro n’nu ododo rẹ
To si huwa aisedede
Yio ku n’nu aisedede rẹ

10. ‘Torina ẹ mu rekọja
Yin kuro lọdọ yin
Kẹ si da ọkan at’ ẹmi
Titun fun ara yin

11. Un ko ninu didun rara
Pe kenia ibi ku
Bikosepe ko yipada
Ki oun ko si ye

12. Torin’ ẹ yipada si mi
Gbogbo opin aiye
Emi l’Olugbala lẹhin
Mi ko tun s’Olugbala

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan