Orin Kan: Ìkórè Nla Kan Mbọ

(“Niwọn igba ti aiye yio wa, igba irugbin, ati igba ikore, igba otutu ati our, igba ẹrun on ojo, ati ọsan ati our, ki yio dẹkun” (Gen. 8:22))
 
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:       
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ẹ dide, Ọmọ igbala
Ẹyin tẹ fẹ Oluwa
Dide ilu alagbara
Ki ọta to de Sion
Ègbè
Fagbara rẹ kọrin kikan
Bi iro omi okun
Nipa Ẹjẹ Kristi Jesu
Awa ju asẹgun lọ
Awa ju asẹgun lọ
Awa ju asẹgun lọ
Nipa Ẹjẹ Kristi Jesu
Awa ju asẹgun lọ.”
Ẹniti o Kọwe: Justus Falckner (1672-1723)
Olùpilẹsẹ Ìwe: James McGranahan (1840-1907)
Olùtumọ: Emma Frances Bevan (1827)

Orin Titun na Nìyí
1. Ìkore j’ asiko ayọ
Nin’ aiye afurungbin
To dide nigba ‘furungbin
Lati fun irugbin rẹ
Ègbè
Níwọn igba taiye yio wa
‘Gba otutu, ẹrùn on òjò
‘Gba rugbin, ‘kore on oru
‘Gba wọnyi k’ yo dẹkun lai
‘Gba wọnyi k’ yo dẹkun lai
‘Gba wọnyi k’ yo dẹkun lai
‘Gba rugbin, ‘kore on oru
‘Gba wọnyi k’ yo dẹkun lai

2. ‘Gba tówọ ati ‘gba àìwọ
Lafurungbin nfunrugbin rẹ
Ko fawọ irugbin sẹhin
Oun ki si sọlẹ
Ègbè

3. O funrungbin silẹ rere
Lẹba omi sisan
O bojuto rugbin to gbin
Titi t’awọn rugbin fi pọn
Ègbè

4. ‘Gbati irugbin na pọn tan
O wọ inu oko lọ
Pẹl’ awọn ‘rinsẹ ikore
Lati lọ kore oko rẹ
Ègbè

5. Asiko awẹ ti kọja
Asiko ẹrun ti lọ
Asiko ikore ni eyi
Agbẹ na nyayọ igbala
Ègbè

6. Ati yi ẹkun rẹ pada,
A yi igbekun rẹ pada
Ayọ nla gbọkan rẹ kan
Tori ati da lare
Ègbè

7. Ikore nla kan mbọ
Ni igbẹhin aiye
Ta o k’ohun ‘kọsẹ kuro
Nijọba awọn olotọ
Ègbè

8. Oko sa ni aiye yi
A o kore rẹ laipẹ
Awọn angẹli l’olukore
Ko ni si ojusaju
Ègbè

9. A o kawọn olododo
Sinu ‘jọba Baba wọn
Nibẹ wọn o ma ran bi orun
Ko si ni si ẹkun mọ
Ègbè

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan