Orin Kan: Ìwọ Yio Tan Fitila Mi
(“Nitori iwọ, ni yio tan fitila mi:
Oluwa Ọlọrun mi yio tan imọlẹ si okunkun mi” (Psa. 18:28))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe
daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ
gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ
wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Bi Krist’ ti da ọkan mi
nde
Aye mi ti dabi ọrun
Larin ‘banujẹ at’ aro
Ayọ ni lati mọ Jesu
Ègbè
Alleluya! Ayọ lo jẹ
Pe mo ti ri dariji gba
Ibikibi ti mo ba wa
Ko s’ewu Jesu wa nibẹ”.
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Gbati gbi aiye bi lu mi
Ti o si bori ọkan mi
Tọna mi gbogbo si daru
Ti okunkun bomi mọlẹ
Ègbè
Oluwa Ọlọrun mi ni
Yio tan fitila mi
Oun yio tun tan imọlẹ
Ìmọlẹ sọna okunkun mi
2. ‘Gbati ọta gbogun dide
Ti ọta pa fitila mi
Ti ohun gbogbo ‘tan fun mi
Ti mo nrin ninu okunkun
Ègbè
3. ‘Gbati ngo ni ero ọla
Ngo mọ b’ọlayio se ri
‘Tori ‘koro ati ‘pọnju
Ti o bo ẹmi mi mọlẹ
Ègbè
4. ‘Gba mo d’ọdọ Olugbala
Gba mo d’ọdọ Jesu Kristi
Mo k’aniyan mi gbogbo le
Mo mọ p’oun yio si gba mi
Ègbè
5. Lọdọ Kristi mo ni ‘sinmi
Jesu Kristi ni imọlẹ
Fitila mi lo si ti tan
Oun si ni ‘mọlẹ sọna mi
Ègbè
Comments
Post a Comment