Orin Kan: Mã Se Ìtọ ati Amọna Mi


(“Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: Nitorina nitori orukọ Rẹ mã se ìtọ mi, ki o si ma se amọna mi” (Psa. 31:3))
 
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:       
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Sa gbẹkẹle l’ọjọjọ
Gbẹkẹle l’arin ‘danwo
Bi ‘gbagbọ tilẹ kere
Gbẹkẹle Jesu nikan
Ègbè
Gbẹkẹle ni ‘gbagbogbo
Gbẹkẹle lojojumọ
Gbẹkẹle lọnakọna
Gbẹkẹle Jesu nikan”

Ẹniti o Kọwe:
Olùpilẹsẹ Ìwe:
Olùtumọ:

Orin Titun na Nìyí
1. Dẹti rẹ silẹ simi
Gba mi ni isinsinyi
Iwọ li mo gbẹkẹle
Iwọ Ọlọrun ‘gbala
Ègbè
Iwọ l’apata at’odi mi
Nitori orukọ rẹ
Jọwọ ma se itọ mi
Ki o si s’amọna mi

2. Okunkun b’aye mọlẹ
O sofo o ri juju
Sugbọn Iwọ n’ Imọlẹ
T’okunkun ko le bori
Ègbè

3. Ninu aiye ẹsẹ yi
Ti ‘wa ibi di pupọ
Tọkan gbogbo jẹ ibi
Iwọ lo le ko mi yọ
Ègbè

4. Larin eke arakunrin
Larin eke arabinrin
Awọn to npete ibi
Iwọ lo le ko mi yọ
Ègbè

5. Un jẹ talo le gbani
Lọwọ ọmọ ‘ya buburu
To mborukọ ‘mọ ‘ya jẹ
Bikose ‘wọ apata mi
Ègbè

6. Larin ‘wọn ‘gabagebe
At’ awọn onikupani
Ti wọn yi agọ mi ka
Iwọ lo le ko mi yọ
Ègbè

7. Gbami Oluwa gba mi
Ma fi mi l’ọta lọwọ
Ọdọ rẹ ni mo sas i
Gba mi Jes’ Oluwa mi
Ègbè

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan