Orin Kan: Bi Ẹnyin Ba Bere Ohunkohun Ni Orukọ Mi, Emi O Se E


(“Bi ẹnyin ba bere ohunkohun ni orukọ mi, emi o se e.” (Joh. 14:14))


 

Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:

N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi

“’Gbati ipe Oluwa ba dun, t’aye y’o si fo lọ

Ti imọlẹ ọjọ titun y’o si de

Nigbati awọn ọmọ igbala ba pejọ l’oke

T’a ba si p’orukọ nibẹ, un o wa m’bẹ

 

Ègbè

‘Gbat’a ba p’orukọ lọhun/3x

‘Gbat’a ba p’orukọ lọhun, un o wa mbẹ

Ẹniti o Kọrin Yi:

 


Orin Titun na Nìyí

1. Lotọ ati lododo ni ohun temi nwi fun nyin

Isẹ tie mi nse lawọn to gbami yo se

Ani ‘sẹ to tobi juyilọ nisẹ ti wọn yo se

‘Tori Emi npada lọ s’ọdọ Baba

Ègbè

Gbogb’ ohun t’ẹnyin ba bere/3x

Gbogb’ ohun t’ẹnyin ba bere lorukọ mi lem’o se

 

2. Ki a ba le yin baba logo ani ninu Ọmọ

Bi ẹnyin bere ohunkohun t’ẹba fẹ

Ni ọwọ baba mi eleyi ti o wa ni ọrun

Baba mi to mbẹ li ọrun y’o se fun yin

Ègbè

 

3. Gẹgẹ bi Baba ti fẹmi bẹni emi na fẹ yin

Bi ẹnyin bas i ngbe inu mi

T’awọn ọrọ mi wọnyi ba si rilẹ si inu yin

Gbogb’ohun tẹba bere l’okọ mi l’em’o se

Ègbè

 

4. Ni orukọ mi d’isinyi ẹ ko I bere ohunkan

Ẹ kànkùn, Ẹ wá kiri, Kẹ bere

Ẹ bere ẹnyin yo si ri ohun ti ẹ bere gba

Ki ayọ yin ba le kun ninu mi

Ègbè

Comments

Popular posts from this blog

Scientific Insight To My Observation on Beans

Some Prayer Points From The Book of Isaiah

Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan