Orin Kan: Ìfẹ Lo Tobi Ju
(“Njẹ nisisiyi igbagbọ, ireti ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: sugbọn eyiti o tobi ju ninu wọn ni ifẹ” (1 Kor 13:13))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Párádísè, Párádísè
Tani ko fẹ ‘sinmi
Tani ko fẹ le ayọ na
Ile alabukun
Ègbè
Ni b’awọn olotọ
Wa lae ninu ‘mọlẹ
Wọn nyọ nigbagbogbo
Niwaju Ọlọrun
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
Torifẹ ki ‘se ilara
Ki ‘sọrọ gberaga
Ègbè
‘Gbagbọ ‘reti at’ ifẹ
‘Wọn mẹta yi lo wa
Sugbọn eyi to tobi ju
Ohun na ni ifẹ
2. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
Torifẹ ki huwa aitọ
Bẹni ki ifẹ rara
Ègbè
3. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
Torifẹ ki wohun tara rẹ
Bẹ laki mu binu
Ègbè
4. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
Torifẹ ki gbero ibi
Bẹni ki s’ohun ibi
Ègbè
5. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
A ma yọ ninu otitọ
Ki ‘yọ saisododo
Ègbè
6. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
Tori ‘fẹ a mu suru
A si ma seun pupọ
Ègbè
7. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
A ma farad’ ohun gbogbo
A ma gbohun gbogbo gbọ
Ègbè
8. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
A ma reti ohun gbogbo
A ma le ẹru lọ
Ègbè
9. Ìfẹ ni o tobi julọ
Ninu aye ti a ngbe
A ma fayaran ohun gbogbo
O mbo ‘pọ ẹsẹ mọlẹ
Ègbè
10. Gbatiwọ ba fifẹ han si
Arakunrin t’ori
‘Gbana lo j’ọm’ ẹhin Kristi
Lododo at’ otitọ
Ègbè
Comments
Post a Comment