Orin Kan: Ìrètí Sì Wà Fun Ẹ
(“Nitoripe àbá wà fun igi, bi a bá ke lulẹ, pe yio si tún sọ ati pe ẹka rẹ titun, ki yio da” (Job. 14:7))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ọkan aarẹ ile kan mbẹ
L’ọna jinjin s’aiye ẹsẹ
Ile t’ayida ko le de,
Tani ko fẹ sinmi nibẹ
Ègbè
Duro, rọju duro, mase kun/2x
Duro, Duro (sa) rọju duro mase kun”
Orin Titun na Nìyí
1. Ẹ ma jẹ k’ọkan yin daru
Ẹnyin tẹ gba Ọlọrun gbọ
Ti gbagbọ nyin wa n‘nu Kristi
‘Tor’ O ni ‘pinnu rere fun nyin
Ègbè
Ireti si wa fun ọ, ọrẹ/2x
Ireti wa, ireti wa fun ọ ọrẹ
2. Ma se sọkun mọ ‘wọ ọrẹ
Nu omije oju rẹ kuro
‘Tori isẹ rẹ ni ere
Eyi l’ohun t’Olugbala sọ
Ègbè
3. Fun ‘wọ ẹnit’ a kọ silẹ
T’ọpọ enia korira
Fun ‘wọ ‘ransẹ ‘wọn olori
Ẹni ‘tẹmọlẹ lawujọ
Ègbè
4. Ireti si wa fun igi
Bo tilẹ jẹ pe a ke lulẹ
Nigbat’ o ba gborun omi
Yo si y’ẹka titun jade
Ègbè
5. ‘Gungun gbigbẹ rẹ yio tun ye
‘Tor’ ao da ‘kolọ rẹ pada
‘Bi isan omi ni gusu
‘wọ yo tun layọ lẹkan si
Ègbè
6. Iran na bi o tilẹ pẹ
O daju yow a si imusẹ
‘Gbat’ akoko kikun ba de
Iwọ yo kọ orin titun
Ègbè
Comments
Post a Comment