Orin Kan: Kò Ni Si Àjàkálẹ Àrùn Níbẹ
(“Ọlọrun yio si nu omije gbogbo nù kúrò li ojú wọn; ki yio si si iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹni ko ni si ìrora mọ; nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ” (Ifi. 21:4))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ọrẹ bi Jesu ko si laye yi
Oun nikan l'ọrẹ otitọ
Ọrẹ aye yi le ko wa silẹ
Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe wa
Ègbè
Ah! Ko je gbagbe wa/ 2ce
Sugbon Jesu ko je gbagbe wa
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Mo r’itẹ funfun nla kan
L’or’ eyi t’ẹnikan jokole
Niwaju rẹ aye on ọrun fo lọ
A ko sir i aye fun wọn mọ
Ègbè
A o n’omije wa nu/2x
Oruk’ awa to wa n’nu ‘we ‘ye
2. Mo r’awọn oku t’ewe t’agba
Ti wọn duro niwaju itẹ
Lati gba ‘dajọ gbogb’ ohun wọn se
Nigbati wọn wa ninu ara
Ègbè
3. Mo r’awọn iwe niwaju itẹ na
Iwe akọsilẹ isẹ gbogbo
A s’awọn ‘we ‘wọnni silẹ
Bẹ latun siwe iye silẹ
Ègbè
4. Okun jọwọ ‘wọn oku rẹ silẹ
Bẹni iku at’ipo oku
A si se ‘dajọ gbgbo eniyan
Gẹgẹb’ isẹ wọn laye ti ri
Ègbè
5. Gbogb’ awọn ta ko kọ orukọ rẹ
Sinu ‘we ‘ye ti Ọd’aguntan
La sọ fun pe lọ kuro lọdọ mi
Si inu adagun ina
Ègbè
6. ‘Gbọn awa ti orukọ wá wà
Ni inu iwe iye na
Ni a sọ fun pe bọ sin’ayọ nla
Eyiti a ti pese fun wa
Ègbè
7. Ọrun ‘sinsinyi at’aye isinyi
Gbogbo wọn ni yio kọja lọ
Bẹ la ko sin i ri okun mọ
A o wa pẹlu Oluwa titi
Ègbè
8. Lọrun titun at’aye titun
Ilu mimọ Jerusalem’ titun
Nibiti ki yio sarọ tab’ alẹ
Iku, ẹkun, tab’ ajakalẹ arun
Ègbè
9. Gbogb’ ohun atijọ lo ti kọja lọ
Ag’ Ọlọrun si wa pẹlu wa
Jesu ni ‘mọlẹ wa tọsan toru
Ha! Ayọ ni lojojumọ
Ègbè
Comments
Post a Comment