Orin Kan: Oluwa, O Tó Àkoko fun Ọ Lati Sisẹ
(“Oluwa, o tó àkoko fun Ọ lati sisẹ; nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo” (Psa. 119:126))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ọkan mi yin Oluwa logo
Ọba iyanu t’O wa mi ri
Un o l’agogo iyin y’aye ka
Un o si t’ifẹ Atobiju mi han
Ègbè
Oluwa, Ọpẹ ni fun Ọ
Fun ore-ọfẹ t’O fi yan mi
Jọwọ dimimu titi d’opin
Ki nle jọba pẹlu Rẹ loke
Orin Titun na Nìyí
1. Nkan ko rib o ti se yẹ mọ
Kaluku ya sipa ọna rẹ
‘Tori a o tete mu idajọ sẹ
Ọkan enia gbilẹ ni ibi
Ègbè
Oluwa o ti to akoko
Fun Ọ lati se isẹ
‘Tori ọpọ enia ‘nu aiye
Ti wọn ti sọ ofin rẹ d’ofo
2. ‘Gba ‘wọ Oluwa poju rẹ mọ
Kuro lara mi ati ‘sẹ mi,
Ẹnu awọn ọta mi nyọ mi
Wọn mbere ‘bi t’Ọlọrun mi wa
Ègbè
3. ‘Gba ‘wọ Oluwa ko tete dide
Ọpọ ‘wọn ọta lo yi mi ka
Wọn wipe awọn yio sẹgun mi
B’awọn ti se f’awọn ‘laigbagbọ
Ègbè
4. Seni wọn nfi Ọ w’awọn orisa
To l’oju ti ko le fi reran
To l’eti ti ko le gbọ rara
To l’ẹsẹ sugbọn ti ko le rin
Ègbè
5. Awọn ẹni ti mo gbẹkẹle,
An’ awọn to njẹ n’nu ounjẹ mi,
Wọn f’imọ wọn sọkan lori mi
Gbogbo wọn gbe gigisẹ si mi
Ègbè
6. Jọwọ Oluwa sanu fun mi
Gbe mi dide nipo ti mow a
Nip’ eyi lemi yio mọ pe
‘Wọ se ojurere Rẹ si mi
Ègbè
7. Sọ ‘kanu mi di ijo fun mi
Si bọ asọ ọfọ mi kuro
Wa fi ayọ di mi lamure
K’ogo mi ko ma kọrin si Ẹ
Ègbè
Comments
Post a Comment