Orin Kan: Ọrẹ Mi Ni Ẹnyin Jẹ
(“Ọrẹ mi ni ẹnyin jẹ, bi ẹ ba se ohun ti emi palasẹ fun nyin” (Joh. 15:14))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Mo ti ni Jesu lọrẹ
O j'ohun gbogbo fun mi
Oun nikan larẹwa ti ọkan mi fẹ
Oun nitanna ipado
Oun ni Ẹnikan naa
To le wẹ mi nu kuro nin'ẹsẹ mi
Olutunu mi lo jẹ ni gbogbo wahala
Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori
Oun n'Itanna Ipado Irawọ Owurọ
Oun nikan l'Arẹwa ti ọkan mi fẹ
Ègbè
Olutunu mi lo jẹ ni gbogbo wahala
Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori
Oun n'Itanna Ipado Irawọ Owurọ
Oun nikan l'Arẹwa ti ọkan mi fẹ”
Ẹniti o Kọrin Yi: William Charles Fry May 30, 1838- August 24, 1882
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Sinyi emi ko pe nyin ni ọmọ-ọdọ mi mọ
‘Tor’ ọmọ-dọ ko m’ohun t’ọga rẹ nse
‘Gbọn ohun tie mi npe yin na ni ọrẹ rere
‘Torina mot i pe nyin l’ọrẹ rere
Gbogb’ ẹni to ba pa asẹ ti mo fi lelẹ mọ
Ọrẹ mi ni gbogbo awọn ẹni na
Ko si ọrẹ ti o nifẹ to pọj’ eyi lọ
P’ẹnikan f’ẹmi rẹ lelẹ f’ọrẹ rẹ
Ègbè
Ọrẹ mi lẹyin nse gbat’ ẹnyin ba ti nse
Ohun gbogbo ti mo palasẹ fun nyin
Ọrẹ kan wa to f’ara mọ ni j’arakọnrin lọ
Ọrẹ yin a ni Jesu Kristi nse
2. Ki ise ẹyin lo yan mi, ‘gbọn emi n mo yan yin
Emi si fi yin si ipo to dara
Ki ẹnyin ko le jade lọ lati ma so eso
Ati ki eso yin ki o le duro
A n’ eyi ni ofin mi kẹ nifẹ ara nyin
Bi emi tise fifẹ mi han sin yin
‘Gbat’ ẹ ba si nse eyi gbogb’ enia yio mọ pe
Ọmọ ẹhin otitọ mi lẹyin jẹ
Ègbè
3. Bi o ti se jẹ pe irin na lo se pọn irin
Bẹ lọrẹ otitọ jẹ fun ọrẹ rẹ
Ọrẹ otitọ ko ni fi ẹ silẹ nigbakan rara
Oun yio si fara mọ ẹ titi lai
Nigba ẹrun tabi ojo oun yio wa pẹlu rẹ
Oun yio si ma ran ailera rẹ lọwọ
Jesu nikan ni ọrẹ to le seyi f’enia
Jesu Kristi nikan l’ọrẹ otitọ
Ègbè
4. ‘Tori ati ni ọrẹ kan to j’ ọrẹ aiye lọ
Awa ni igboya b’aba mba sọrọ
‘Tori a ti kuro l’ẹru a sit i d’ominira
A le ber’ ohunkohun lorukọ rẹ
Gbogb’ ohun ti a ba bere ni orukọ Jesu
Ohun na ni Ọlọrun yio se fun wa
Nitori awa nse ‘fẹ rẹ, gbagbọ wa, wa n’nu rẹ
Oun yio dahun bere awa ọrẹ rẹ
Ègbè
Comments
Post a Comment