Orin Kan: Ti Ko Ba Si Ìfẹ, Asán Ni
(“Bi mo si ni ẹbùn ìsọtẹlẹ, ti mo si ni oye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo imọ: bi mo si ni gbogbo ìgbàgbọ, tobẹ ti mo le si awọn oke nla nipo, tie mi ko si ni ifẹ, emi ko jẹ nkan” (1 Kor 13:2))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Párádísè, Párádísè
Tani ko fẹ ‘sinmi
Tani ko fẹ le ayọ na
Ile alabukun
Ègbè
Ni b’awọn olotọ
Wa lae ninu ‘mọlẹ
Wọn nyọ nigbagbogbo
Niwaju Ọlọrun
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Kóda bi o ba jẹ wipe
Mo nf’ọniruru ede
Ati ti awọn angẹli
Temi ko ni ifẹ
Ègbè
Ohun yow u ti mba ni
Ohun yo wu ti mba jẹ
Bikoba tis i ifẹ
Asan ni gbogbo rẹ
2. Bi emi ko ba ni ifẹ
Èdèkédè yio wu
Ti emi iba le ma sọ
Idẹ lasan ni mi
Ègbè
3. Bi mo l’ẹbun isọtẹlẹ
At’oye ohun gbogbo
Ati gbogbo imọ pata
Sibẹ lai si ifẹ
Ègbè
4. Bi mo ni gbogbo igbagbọ
Lati s’awọn oke
Nla nipo lọ sin’ ọgbun
Sibẹ lai si ifẹ
Ègbè
5. Bi mo fi gbogb’ ohun ‘ni mi
Bọ awọn talaka
Ati awọn alaini
Sibẹ lai si ifẹ
Ègbè
6. J’ohun gbogbo ninu aiye
Ẹ jẹ ka wa ifẹ
Ka fifẹ han s’awọn ara
Eyi l’Ọlọrun fẹ
Ègbè
Comments
Post a Comment