Orin Kan: Wò Mi Sàn, Oluwa
(“Wò mi san, Oluwa, emi o si san! Gbamila, emi o si la, nitori iwọ ni iyin mi” (Jer. 17:14))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Jesu ọkan na ni titi
Bi o ti wa nigbani
Lasan li ọrun apadi
Ndojukọ agbara rẹ
L’ọkan awọn eniyan rẹ
O njọba titi d’oni
Tirẹ ni gbogbo agbara
O nfa ide ẹsẹ ja”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Wo mi san, emi o si san
Gbamila emi yio la
‘Tori ‘wọ nikansoso ni
Ọna ‘ye at’ otitọ
Mo ke pe Ọ ‘wọ Oluwa mi
Nin’ aisan at’ ailera mi
F’ọwọ iwosan rẹ kan mi
Botise f’ana Simon’
2. Wo mi san, emi o si san
Gbamila emi yio la
Nitori aisedede wa
Ni a se pa Ọ lara
Bẹni ‘na Alafia wa
Si wa ni ara rẹ
Ati nipa ‘na ara rẹ
Ni a mu wa larada
3. Wo mi san, emi o si san
Gbamila emi yio la
‘Tori ni igba asalẹ
‘Gbati orun ti wọ tan
Wọn gbe awọn alaisan wa
Pe k’iwọ ko wo wọn san
Iwọ fi ọwọ rẹ kan wọn
‘Wọ si mu wọn lara da
4. Wo mi san, emi o si san
Gbamila emi yio la
‘Tori ‘wọ nikan lo lagbara
Lati se ‘sẹ ‘rapada
Awọn t’ẹm’ esu nyọ lẹnu
‘Wọn gbe gbogbo wọn ‘dọ rẹ
‘Wọ l’ẹm’ esu wọnni jade
Iwọ si tu wọn silẹ
5. Wo mi san, emi o si san
Gbamila emi yio la
‘Tori orukọ rẹ bori
Gbogbo orukọ t’a n pe
Lọrun, nilẹ at’ nisalẹ ilẹ
Nigbogbo ekun nkunlẹ
Bẹni gbogbo ahọn njẹwọ
Pe Jesu Krist’ l’Oluwa
Comments
Post a Comment