Orin Kan: Ẹ Máa Wádìí Ohun Gbogbo Dájú
(“Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin.” (1 Tesa. 5:21))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Alleluya, Alleluya, Alleluya
Ija dopin ogun si tan
Olugbala jagun molu
Orin ayọ la o ma kọ
Aleluyah”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ẹ ma wadi, Ẹ ma wadi, Ẹ ma wadi.
Ẹ ma wadi ohun gbogbo
Dajudaju ki ẹ to se
Gbogbo ohun t’ẹba fẹ se
Ẹ ma wadi
2. Ẹ mase gba gbogb’ ẹmi gbọ
‘Gbọn ki ẹ dan gbogbo wọn wo
Lati m’eyi to nse t’Ọlọrun
Ẹ ma wadi
3. Awọn woil eke pupọ
At’ awọn olukọni eke
‘Wọn ti jade wa sarin wa
Ẹ ma wadi
4. Ọpọ l’awọn ‘ke ‘rakunrin
Ati eke arabinrin
Ti nwọn gbe agọ agutan wọ
Ẹ ma wadi
5. Nipa eso wọn ẹ o mọ wọn
Awọn ikoko n’nu asọ agutan
Ẹ ma gba ki nwọn o tan yin
Ẹ ma wadi
6. Ẹ ma kiyesi ara nyin
Bẹni ki ẹ ma gbadura
K’ẹma ba bọ si ọwọ wọn
Ẹ ma wadi
Comments
Post a Comment