Orin Kan: Èmi Ati Ìdílé Mi Wà Fun Ìyanu Ninu Aiye
(“Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Oluwa ti fi fun mi wa fun ami ati fun iyanu ni Israeli, lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wa, ti ngbe oke Sioni.” (Isa. 8:18))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Sa gbẹkẹle l’ọjọjọ
Gbẹkẹle l’arin ‘danwo
Bi ‘gbagbọ tilẹ kere
Gbẹkẹle Jesu nikan
Ègbè
Gbẹkẹle ni ‘gbagbogbo
Gbẹkẹle lojojumọ
Gbẹkẹle lọnakọna
Gbẹkẹle Jesu nikan”
Ẹniti o Kọrin Yi: Edgar Page (1876)
Orin Titun na Nìyí
1. Awọn ọmọ ti Oluwa
Ti fi fun mi nin’ aiye
A wa fun isẹ ami
A wa lat’ f’ogo Rẹ han
Ègbè
Emi ati ‘dile mi
Ti oluwa fi fun mi
A wa fun ‘yanu laiye
‘Tori ti Jesu niwa
2. Emi ati ọkọ mi
Yo fi gbogbo ọjọ wa
Sin Olurapada wa
Jesu Krist’ ọkọ ijọ
Ègbè
3. Emi ati aya mi
Yo gbe oju wa s’oke
Si ori oke wọnni
Nibi ‘ranlọw’ wa ti nwa
Ègbè
4. Bi ‘Wọ ba m’ẹmi mi gun
Ti mo si r’ọmọ-ọmọ mi
Iran kinni de ‘kẹrin
Gbogb’ aiye wa la o fi sin Ọ
Ègbè
5. Nigbat’ aiye w aba pin
Ta ba pari ‘re ‘je wa
A fẹ gbọ ohun ‘tura
Kabọ ọmọ-ọdọ rere
Ègbè
Comments
Post a Comment