Orin Kan: Fi Ọna Rẹ Han Mi
(“Fi ọna rẹ han mi, Oluwa; kọ mi ni ipa tirẹ” (Psa. 25:4))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ẹ jẹ ka finu didun
Yin Oluwa Olore
Anu rẹ, O wa titi
Lododo dajudaju”
Orin Titun na Nìyí
1. F’ọna rẹ han m’Oluwa
Kọ mi ni ipa tirẹ
‘Tori ‘nu aiye ta wa
O jẹ ibugbe ika
2. F’ọna rẹ han m’Oluwa
‘Tor’ alejo oun atipo
Ni emi jẹ nin’ aiye
Ng ko mọ ibi kankan
3. F’ọna rẹ han m’Oluwa
‘Tori ọmọde ni mi
Emi ko loye ohun kan
Ki emi ma ba sise
4. F’ọna rẹ han m’Oluwa
Ki emi le mọ Ọ si
K’ emi si ma bẹru rẹ
K’ emi ko le fẹ Ọ si
5. F’ọna rẹ han m’Oluwa
Ki emi le fa sẹhin
Kuro ninu ọna ẹsẹ
Ki ‘fẹ mi si Ọ le pọ si
6. F’ọna rẹ han m’Oluwa
Ki emi ma ba sina
Kuro ninu asẹ rẹ
Ki nsi ba maj’mu rẹ jẹ
7. F’ọna rẹ han m’Oluwa
Ki nle ma fiyes’ awọn
Ohun wọnni to wa n’nu
Ọrọ ati ‘lana rẹ
8. F’ọna rẹ han m’Oluwa
Ma rant’ ẹsẹ ‘gba ewe mi
Bi anu rẹ Oluwa
Iwọ ranti mi si ‘re
9. F’ọna rẹ han m’Oluwa
‘Tori mo gbẹkẹle Ọ
Ma jẹ ki oju timi
Ma se jẹ k’ọta yọ mi
10. F’ọna rẹ han m’Oluwa
‘Tori ‘wọ l’Ọlọrun mi
Iwọ nikan ni mo mọ
‘Wọ mo duroti ngba gbogbo
Comments
Post a Comment