Orin Kan: GBIGBEGA Li Oluwa
(“Ki gbogbo awọn ti nwa Ọ, ki o ma yọ, ki inu wọn ki o si ma dun sipa tirẹ: ki gbogbo awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe. Gbigbega li Oluwa” (Orin Daf. 40:16))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Jesu yio gba ẹlẹsẹ
Kede rẹ fun gbogb’ ẹda
Awọn ti wọn sako lọ
Awọn ti wọn subu
Ègbè
Kọ lorin, ko si tun kọ
Kristi ngb’ awọn ẹlẹsẹ
Fi o tọ ye wọn pe
Kristi ngb’ awọn ẹlẹsẹ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Gbogbo awọn ti o nwa
Oluwa Ọlọrun wa
O yẹ kinu wọn ko dun
Ki nwọn ma yọ nwaju Rẹ
Ègbè
O ti da, o ti dun to
Lati ma wi ngba gbogbo pe
Gbigbega ni Oluwa
Larin orilẹ aiye
2. Gbogbo awọn ti nwọn fẹ
Igbala Ọlọrun wa
Wọn nilati gbẹkẹle
Ki gbagbọ wọn wa n’nu Rẹ
Ègbè
3. ‘Wọn orisa orilẹ ede
Ko seyi ta le fi we
Oluwa Ọlọrun wa
To ngb’ arin awọn Kerubu
Ègbè
4. Ẹni nla l’Oluwa wa
Ọba to yẹ lati yin
‘Tori ko s’ẹni dabi
Oluwa ninu aiye
Ègbè
5. Ijọba tirẹ nise
Agbara tirẹ nise
Ọba ainipẹkun ni
Oun l’Oluwa gbogbo aiye
Ègbè
Comments
Post a Comment