Orin Kan: Ireti Mi Mbẹ Li Ọdọ Rẹ
(“Njẹ nisisiyi, Oluwa kini mo duro de? Ireti mi mbẹ li ọdọ rẹ” (Psa. 39:7))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Igba mi mbẹ li ọwọ Rẹ
Mo fẹ ko wa nibẹ;
Mo f’ara, ọrẹ, ẹmi mi
Si abẹ isọ rẹ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
Oluwa ‘wọn ‘mọ ogun
Mase doju ireti mi
Timi Oluwa mi
2. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
‘Gbagbọ mi wa n’nu rẹ
Ko si ninu ohunkohun
Tab’ orisa kankan
3. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
Ko si ‘nu enia Kankan
‘Tori asan ni gbẹkẹle
Ni inu ẹnikẹni
4. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
Kosi ninu awọn
Ọmọ ‘lade orilẹ-de
To mbẹ ninu aiye
5. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
Lati lu aluyọ
‘Tori ọla ati ọrọ
Lọwọ rẹ ni wọn wa
6. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
‘Tori ohun gbogbo lọrun
Ati ninu aiye ta wa
Gbogbo wọn jẹ tirẹ
7. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
Gba mow a ‘nu ‘damu
‘Tori agbara ati ‘pa
Ni ọwọ rẹ lowa
8. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
‘Gba t’ọta gb’ ogun de
‘tori ‘wọ lo le fun mi ni
‘Sẹgun lori ọta
9. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
‘Gba ko s’ ẹnikan mọ
‘Tori ‘wọ yo jẹ babami
Aya at’ ọmọ mi
10. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
‘Gba mo wa ‘nu aini
‘Tori ‘wọ ni yo ba gbogbo
Awọn aini mi pade
11. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
‘Gba mo wa inu idẹra
Ti mo joko l’alafia
Ni inu ‘yẹwu mi
12. Ireti mi mbẹ lọdọ rẹ
‘Gbat’ ayọ yi mi ka
‘Tori ‘wọ lorisun ayọ
Ti ẹnu ko le sọ
Comments
Post a Comment