Orin Kan: Nigbat’ O Yẹ Lati Gbẹkẹle Oluwa

 (“Nigbati ẹru ba mba mi, emi o gbẹkẹle Ọ?” (O. Daf. 56:3))


 

Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:

Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.

 

Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi

“A f’ayọ ro ore-ọfẹ

T’Alufa giga wa;

Ọkan rẹ kun fun iyọnu

Inu rẹ nyọ fun ‘fẹ

Ẹniti o Kọrin Yi:




Orin Titun na Nìyí

1. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

Nitori ‘wọ ni Ẹni na

To le m’ẹru mi lọ

 

2. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

Bi Jakọb’ ti gbẹkẹle Ọ

To si gba l’ọwọ Esau

 

3. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

Bi Jona ti gbẹkẹle Ọ

Ti ẹja pọ silẹ

 

4. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

Bi Jehosafat’ at’ Juda

Ti gbẹkẹle Ọ to si gba wọn

 

5. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

‘Gbati ko s’ounjẹ mo le jẹ

‘Tori ‘wọ o pese fun mi

 

6. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

Gba gbogbo ‘reti pin fun mi

Iwọ ni ‘reti mi

 

7. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

Gba mow a lor’ ẹni arun

‘Wọ ngba mi ni ‘yanju

 

8. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

‘Tori ‘wọ lo gbọran mi ro

‘Wọ gbami lọwọ awọn ẹlẹtan

 

9. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

‘Gbati iji ngba mi kiri

Iwọ yio gba mi

 

10. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

‘Gba mor o pe mo sasenu

‘Wọ mu sẹ mi lere

 

11. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

‘Gba angẹl’ okunkun parade

S’angẹli imọlẹ

 

12. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

Nitori ‘wọ yo tan ‘mọlẹ

Sọna okunkun mi

 

13. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

Nigbat’ emi darugbo tan

‘Tori ‘wọ k’ yo kọ mi

 

14. Nigbati ẹru ba mba mi

Em’ o gbẹkẹle Ọ

‘Tori ‘wọ yo mu mi sọji

Lat’ ọgbun ilẹ wa


Comments

Popular posts from this blog

Coronavirus Philanthropists: Gave with Right Hand, Collect with Left Hand

A Hymn: Cain and Abel