Orin Kan: O Dájú Wipe Yio Gba Awọn Israeli ti Ẹmi Na Pẹlu
(“Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egypti ti ko mọ Josẹfu” (Eks. 1:8))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ko tọ k’ awọn mimọ bẹru
Ki nwọn sọ ‘reti nu
‘Gba wọn ko reti ‘ranwọ rẹ
Olugbala y’ o de”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. O si se lopin ọjọ wọnni
Lẹhin ‘ku Josẹfu
Ọba miran jẹ ni Egypti
Ti ko mọ Josẹfu
2. Awọn ọmọ ‘Sraeli bi si
Wọn si rẹ nilẹ na
Wọn di alagbara nla gan
Ilẹ na kun fun wọn
3. Ọba titun ni Egypti
P’ awon oloye rẹ jọ
Wọn gbimọ pọ wipe ki wọn
F’ ọgbọn ba ‘Sraeli lo
4. Wọn yan awon ‘konisisẹ
Bẹni wọn npọn wọn loju
Wọn f’ awon enia Rẹ s’abẹ
Isinru to le gan
5. Sugbọn awon ọmọ Israeli
Kigbe tọ Ọlọrun lọ
Ọlọrun si gbọ igbe won
O gb’ olugbala nde
6. O ba Mose pade l’aginju
O si ran si wọn
O pe Aaroni ‘rakunrin rẹ
Lati j’ oluranwọ rẹ
7. Mose oun Aaroni yọ si
Awon ọmọ Israeli
Wọn ba gbogbo awon agbagba
Sọ ohun t’ Oluwa sọ
8. Gbat’ awon ọmọ Israeli
Gbọ p’ Oluwa bẹ won wo
Wọn wolẹ niwaj’ Oluwa
Wọn si sin Ọlọrun
9. Mose oun Aaroni lọ ba
Farao ati awon ti
Wọn j’oloye nilẹ Egypti
Pe k’wọn jẹ k’Israeli lọ
10. Sugbọn Farao ati awon
Alasẹ ilẹ Egypti
Bere tali Oluwa na
Ti ‘s’ Ọlọrun Israeli?
11. Wọn kọ lati jẹ ki awon
Ọmọ Israeli jade
Lati lọ sin Ọlọrun wọn
Ni inu aginju
12. ‘Gbana Ọlọrun n’ọwọ rẹ
O fi sẹ ‘yanu rẹ
Kọlu ohun gbogbo to mbẹ
Ni ilẹ Egypti
13. Lẹhin isẹ ‘yanu ‘kẹwa
Tise iku akọbi
Farao ati gbogbo olugbe
Ilẹ Egypti jẹ k’wọn lọ
14. Bi Oluwa ti gba awon
Israeli t’ara la bayi
O daju wipe yio gbawa
Israeli t’ẹmi na la
15. Kiki ki a sa gbẹkẹle
Ki ‘ret’ ohun ‘gbagbọ wa
Wa ni inu Jesu Kristi
Ọmọ Bibi kan soso
Comments
Post a Comment