Orin Kan: O Ya Lati Gbẹkẹle Oluwa
(“O ya lati gbẹkẹle Oluwa, ju ati gbẹkẹle eniyan lọ” (Orin Daf. 118:8))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ọlọrun Bẹtẹl’ ẹniti
O mbọ awọn tirẹ
Ẹnit’ O mu baba wa la
Ọjọ aiye wọn ja”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
Eniyan ẹlẹran ara
T’ẹm’ rẹ wa niho ‘mu rẹ
2. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
Gbogbo awọn ọmọ alade
Orilẹ ede lọ
3. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
Kẹkẹ tabi ẹsin ogun
Tab’ awọn Ologun
4. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
Ọrun, ọkọ ati ida
At’ awọn ohun ogun
5. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
Fadaka, wura tabi pearl’
At’ ọpọlọpọ ọrọ
6. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
‘Wọn orisa orilẹ ede
‘Tori wọn kis’ Ọlọrun
7. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
‘Wọn alufa tabi woli
‘Tor’ enia ni wọn
8. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
Awọn ọba ati awọn
Olori orilẹ ede
9. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
Baba, iya, tabi ẹgbọn
Aburo tabi mọlẹbi
10. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
‘Wọn ọlọla, ‘wọn ijoye
‘T’awọn ‘lasẹ ib’okunkun aiye
11. Lati gbẹkẹl’ Oluwa ya
Ju lati gbẹkẹle
Ọkọ, aya tabi ọmọ
At’ awọn t’anpe l’ọrẹ
Comments
Post a Comment