Orin Kan: Oun Yio Mu Ọran Rẹ Loju
(“Awọn olori awon ọmọ Israeli si ri pe, ọran wọn ko li oju, lẹhin igbati a wipe, ẹki o dinku ninu iye briki nyin ojojumọ” (Eks. 5:19.))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Fi ibukun Rẹ tu wa ka
Fi ayọ kun ọkan wa;
K’ olukuluku mọ ‘fẹ Rẹ!
K’a layọ n’nu ore Rẹ
Tu wa lara, Tu wa lara
La aginju aiye ja”
Ẹniti o Kọrin Yi: John Fawcett (1786)
Orin Titun na Nìyí
1. Nigbati ile aiye su ẹ
T’ ohun gbogbo ko se dede
Nigbat’ ọran rẹ ko loju
Ti gbogbo ipa rẹ pin
Ma se gbagbe pe Ọlọrun
Yo mọran rẹ lojutu
2. Nigbat’ awon ‘mọ Israeli
Fẹ jade nilẹ Egypti
‘Wọn Egypti mu won sin l’asinpa
‘Wọn bẹ ọba ko sanu won
Sugbọn ọran wọn ko lojutu
Afi ‘gba t’ Ọlọrun dasi
3. Jona wọ ọkọ to nlọ si Tarsis’
‘Gbọn ji lile nde lokun
To bẹ t’ọran gbogbo ero
To wa ninu ọkọ na
Ko fi loju, Ko fi loju
A fi gba won ju Jona somi
4. Ọkunrin kan f’ọmọ t’ẹmi
Esu ndamu t’ọmọ ẹhin lọ
‘Gbọn awọn ‘mọ ẹhin Jesu
Ko le l’ẹmi na jade
Ọrọ ọmọ na ko lojutu
Afi igbati Jesu de
5. B’ọrọ aiye rẹ tilẹ su ọ
‘Tor’ ohun gbogbo to daru
‘Tọran rẹ ko si loju mọ
Tiwọ ko mohun to fẹ se
‘Gbọn gbẹkẹle Jesu Kristi
Oun yio mọran rẹ loju
Comments
Post a Comment