Orin Kan: A Ti Fi Han Ọ
(“A ti fi han ọ, iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bere lọwọ rẹ, bikose ki o se otitọ, ki o si fẹ anu, ati ki o rin ni irẹlẹ pẹlu Ọlọrun rẹ” (Mik. 6:8))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Wa sọdọ Jesu, mase duro
L’ọrọ rẹ l’o ti f’ọna han wa
O duro li arin wa loni,
O nwi pẹlẹ pe, wa!
Ègbè
Ipade wa yio jẹ ayọ
‘Gbọkan wa ba bọ lọwọ ẹsẹ
T’a o si wa pẹlu rẹ Jesu
Nile aiyeraiye”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Nitori Ọlọrun fẹ araiye
Gidigidi lo se fun wa ni
Ọmọ bibi Rẹ kanna soso
Pe ka le ni gbala
Ègbè
A ti fi han ọ ọmọ enia
Ohun to dara t’Oluwa bere
Li ọwọ wa ohun ni ‘ronupiwada
Ati ‘gbala ọkan wa
2. Bi ẹnikẹni ba gbọ nipa rẹ
Ti o ronu to tun yipada
Kuro nin’ awọn ọna ẹsẹ rẹ
Ẹni na k’ yo segbe
Ègbè
3. Ẹnito ba gb’ ọmọ Ọlọrun yi gbọ
To ngbọrọ rẹ to tun nse fẹ rẹ
O daju p’ẹni na yio ni ‘ye
Iye ainipẹkun
Ègbè
4. ‘Wọ ọrẹ mi mase duro mọ
Yara Kankan lati yipada
Kuro nin’ awọn ọna ẹsẹ rẹ
Gba Jesu gbọ loni
Ègbè
5. Bi ‘wọ b agba Jesu gbọ loni
‘Wọ yo d’ọmọ loju Ọlọrun
orukọ rẹ ninu iwe iye
ki yio parẹ laelae
Ègbè
6. Ma se otitọ ma fanu han
Rin nirẹlẹ pẹlu Ọlọrun rẹ
Wọnyi ni Oluwa mbere
Lọwọ gbogb’ enia
Ègbè
Comments
Post a Comment