Orin Kan: Àgbà Obìnrin
(“Bẹ gẹgẹni ki awọn àgbà obìnrin jẹ ẹni-ọwọ ni ìwà, ki nwọn ma jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin, tabi ọmuti, bikose olukọni ni ohun rere” (Titu 2:3))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“L’owurọ ọjọ ajinde
T’ara t’ọkan yo pade
Ẹkun, ‘kanu on irora
Yo dopin”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. O dara k’awọn agba obinrin
Jẹ ẹn’-ọwọ ni iwa
K’awọn ma jẹ ẹntio nsọrọ
Ẹni lẹhin
2. O dara k’awọn agba obinrin
K’ nwọn mase jẹ omuti
B’kose k’ nwọn j’ olukọni
L’ohun rere
3. O dara k’awọn agba obinrin
Letọ awọn ọdọmọbinrin
Lati le ma fẹran awọn
Ọkọ ti nwọn
4. O dara k’awọn agba obinrin
Le ma k’ awọn ọdọmọbinrin
Lati le ma fẹran awọn
ọmọ t’ wọn bi
5. O dara k’awọn agba obinrin
Ki nwọn jẹ alairekọja
Ẹni mimọ at’ osisẹ
Ninu ile
6. O dara k’awọn agba obinrin
Ki nwọn jẹ ẹni rere
Awọn ẹni to ntẹriba
f’ọkọ ti wọn
7. O dara k’awọn agba obinrin
Ki nwọn ma jẹ opurọ
‘Gbọn eleyi ni ki nwọn jẹ
Olotitọ
8. O dara k’awọn agba obinrin
Mase j’ ẹlẹnu meji
Bikose k’ wọn di ‘gbagbọ mu
L’ọkan funfun
Comments
Post a Comment