Orin Kan: Ẹgbẹ Buburu Ba Iwa Rere Jẹ
(“Ki a ma tan nyin jẹ: ẹgbẹ buburu ba iwa rere jẹ” (1 Kor. 15:33))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ọlọrun ọdun t’o kọja
Iret’ eyiti mbọ
Ib’ isadi wa ni iji
A t’ ilẹ wa laelae”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ẹ ma jẹ k’ẹnikẹni ko
Tan nyin jẹ ẹnyin ara
Ẹ m’ọyi p’ẹgbẹ buburu
Ma mba ‘wa rere jẹ
2. Amnon’ jẹ ọkan lara awọn
Ọmọkunrin Dafid’
Oun l’aburo obinrin kan
Ti o njẹ Tamari
3. Amnoni si nifẹkufẹ
Si Tamar’ aburo rẹ
Ifẹ gbigbona to ni si
Mu ko bẹrẹ aisan
4. ‘Gbọn Amnoni ni ọrẹ kan
Ti orukọ rẹ njẹ
Jonadabu ọmọ Simea
To j’ ẹgbọn fun Dafid’
5. Alarekereke enia
Ma ni Jonadabu jẹ
‘Gba t’oun gbọ pe Amnon saisan
Oun si ‘wọle lọ ki
6. Oun bere lọwọ Amnoni
Iru aisan to nse
Amnoni si salaye fun
P’oun nifẹ Tamari
7. Jonadabu kọ lohun ti
O le se lati le
F’arakereke dubulẹ
Ti Tamar’ ‘buro rẹ
8. Amnon’ mu ọgbọn buburu
Ti Jonadab’ kọ lo
Oun fi ipa b’aburo rẹ
Tamari lajọse
9. Ẹgbẹ buburu ti oun
Amnoni lọ dapọ mọ
Lo ba iwa rere rẹ jẹ
Ninu ‘dile ọba
10. Jinna ara mi jinna si
Ẹgbẹ ibi gbogbo
Biwọ ba fẹ niwa rere
Jinna s’ẹgbẹ ibi
Comments
Post a Comment