Orin Kan: Ẹnyin Baba
(“Ati ẹnyin baba, ẹ mase mu awọn ọmọ nyin binu: sugbọn ẹ mã tọ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa” (Efesu 6:4))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Jesu ọrọ Rẹ ye
O si ntọ isisẹ wa
Ẹnit’o ba gba gbọ
Y’o layọ on ‘mọlẹ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Ẹnyin baba ‘wọn ọmọ
Ẹri p’ ẹnkọ ‘wọn ‘mọ yin
Bi ati ngbadura
Ati l’ọr’ Ọlọrun
2. Ẹnyin baba ‘wọn ọmọ
Ẹ m’awọn ‘mọ yin dagba
Ni inu igbagbọ
To mbẹ ‘nu Jesu Kristi
3. Ẹnyin baba ‘wọn ọmọ
Bẹ ti mb’ awọn ‘mọ yin lo
Ẹ ma mu wọn binu
K’ọkan wọn ma ba rẹwẹsi
4. Ẹnyin baba ‘wọn ọmọ
Ẹ tẹra m’eyi n’sise
Ẹ ma tọ ‘wọn ‘mọ yin
L’ẹkọ ati ‘kilọ Oluwa
5. Ẹnyin baba ‘wọn ọmọ
Pẹl’ ọgbọn ni ki ẹ fi
Ma b’awọn ọmọ nyin gbe
Ninu aiye t’ a wa
6. Ẹnyin baba ‘wọn ọmọ
Ẹ ma wo Jesu Kristi
Kiwa atise yin
Ko j’alairiwisi
7. Ẹnyin baba ‘wọn ọmọ
Ẹ jẹ apẹrẹ rere
Fun awọn ọmọ yin
Bi Jesu t’ jẹ si yin
Comments
Post a Comment