Orin Kan: Ìdè Ìfẹ́
(“Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.” (Hos. 11:4))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Ìtànna t’o bo ‘gbẹ l’asọ
T’o tutu yọyọ bẹ
Gba doje ba kan, a si ku,
A subu a si rọ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Tori Ọlọrun f’araiye
To f’ọmọ Rẹ fun wa
Oun f’ide ifẹ rẹ fa wa
O si gbọkan wa la
2. Ọlọrun sọ ara rẹ di
Eniyan bi awa
Oun f’ide ifẹ rẹ fa wa
O si ra wa pada
3. Lori igi agbelebu
Lọmọ Ọlọrun ku
Oun f’ide ifẹ rẹ fa wa
O fẹjẹ rẹ s’etutu
4. Ọm’ Ọlọrun s’ọjọ mẹta
Ninu iho ilẹ
Oun f’ide ifẹ rẹ fa wa
O gba ‘gbara lọwọ ‘kus
5. Iku ko lagbara lori rẹ
‘Sa oku ko nipa
Oun f’ide ifẹ rẹ fa wa
O sọ wa d’ọmọ rẹ
6. Ati fun wa lorukọ kan
To bori gbogb’ orukọ
Oun f’ide ifẹ rẹ fa wa
O fun wa nisẹgun
7. Ma sai gba ‘pe ifẹ loni
Nipa did’ ọmọ Ọlọrun
T’oroun fide ifẹ fa ọ
Mase ja ‘de ifẹ na
Comments
Post a Comment