Orin Kan: Ìgbesoke Mbẹ
(“Nigbati ipa-ọna rẹ ba lọ sisalẹ, nigbana ni iwọ o wipe, igbesoke mbẹ! Ọlọrun yio si gba onirẹlẹ la.” (Job. 22:29))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Apata aiyeraiye
Se ibi isadi mi
Jẹ ki omi on ẹjẹ
T’o san lati iha rẹ
Se iwosan f’ẹsẹ mi
Ko si sọ mi di mimọ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Gbati ọna rẹ ba lọ lẹ
T’ireti si pin fun ọ
‘Gbana iwọ yo wipe
Ireti si mbẹ fun mi
Igbesoke mbẹ fun mi
‘Tor’ oun yo gbonirẹlẹ la
2. Awọn to nfi omije
Fun irugbin wọn lọwọ
Pẹlu ‘gbagbọ wọn wipe
Ireti si mbẹ fun mi
Igbesoke mbẹ fun mi
‘Tor’ oun yo gbonirẹlẹ la
3. Awọn to nfẹkun rin lọ
Pẹlu ‘rugbin wọn lọwọ
Pẹl’ ayọ ‘wọn na wipe
Ireti si mbẹ fun mi
Igbesoke mbẹ fun mi
‘Tor’ oun yo gbonirẹlẹ la
4. B’emi tilẹ darugbo
T’ewu tibo ori mi
S’bẹ ‘gbagbọ mi le pe
Ireti si mbẹ fun mi
Igbesoke mbẹ fun mi
‘Tor’ oun yo gbonirẹlẹ la
5. Bi ẹkun pẹ d’alẹ kan
‘Gbọn ayọ mbọ l’owurọ
Nitori emi mọ pe
Ireti si mbẹ fun mi
Igbesoke mbẹ fun mi
‘Tor’ oun yo gbonirẹlẹ la
6. Bi iran na tilẹ pẹ
Sibẹ em’o duro de
‘Tori oun ti wipe
Ireti si mbẹ fun mi
Igbesoke mbẹ fun mi
‘Tor’ oun yo gbonirẹlẹ la
7. Oluwa Ọlọrun mi
Mase gbagbe ọrọ rẹ
‘Nu eyiti gbagbọ mi wa
Pe ‘reti si mbẹ fun mi
Igbesoke mbẹ fun mi
‘Tor’ oun yo gbonirẹlẹ la
Comments
Post a Comment