Orin Kan: Ikore Pọ, Sugbọn Awọn Alagbase Ko To Nkan
(“Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ pe, lotọ ni ikore pọ, sugbọn awọn alagbase ko to nkan” (Matt. 9:37))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Bibeli Mimọ tọrun
Ọwọn isura temi
‘Wọ ti nwi bi mot i ri
‘Wọ ti nsọ bi mo ti wa”
Ẹniti o Kọrin Yi: John Burton
Orin Titun na Nìyí
1. Jesu sọ pe ‘kore pọ
‘Gbọn ‘wọn ‘lagbase o to nkan
F’eyi ẹ b’Oluwa ‘kore
Ko ran awọn alagbase wa
2. Mo nran yin b’ọd-agutan
Si arin awọn ikoko
‘Torina ẹgbọn bi ejo
Bi adaba ẹ ni wa tutu
3. Nile kile tẹ ba wọ
Ẹ wip’alafia fun ‘le yi
Alafia yin yo ba le
‘Wọn ọmọ Alafia ibẹ
4. Lẹhin na ẹ ba wọn sọ
Ọrọ ijọba Ọlọrun
Ẹ bẹrẹ latibi tẹ wa
Lọs’ orilẹ ede aiye
5. Gbogb’ ẹni to ba gbagbọ
T’a ba baptis’ rẹ yo la
‘Gbọn awọn ti ko gbagbọ
Ẹbi wọn wa lori wọn
6. Ẹ kọ orilẹ-ede gbogbo
Lati kiyes’ ohun gbogbo
Ti mot i pa li asẹ
Fun ẹnyin iransẹ mi
Comments
Post a Comment