Orin Kan: Ìtàn Obinrin Ọlọla Sunemu ati Woli Elisa
(“O si di ọjọ kan, nibiti Elisa
si kọja si Sunemu, nibiti obinrin ọlọla kan wa; on si rọ ọ lati jẹ ounjẹ. O si
se, nigbakugba ti o ba nkọja lọ, on a ya si ibẹ lati jẹ ounjẹ.” (2
A. Ọba. 4:8))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
N go mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Alafia fun ‘le yi
At’ awọn ti ngbe ‘nu rẹ
K’ Alafia Ọlọrun
B’ẹni Alafia gbe
Ègbè
Jẹki ẹmi sọkalẹ
K’ Ibukun na ba le wa!
Ọm’ Alafia gb’ ade rẹ
Ẹkun-rẹrẹ or-ọfẹ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. O si se b’woli Elisa
Ti nkọja ni Sunemu
O pada ‘binrin ọlọla kan
Nile ẹnito nwọ si
Ègbè
Ohun kan yi dami loju
P’ẹnit’ o bẹrẹ ‘sẹ rere
Ninu yin yo se asepe
Gbogbo ‘sẹ rere to bẹrẹ
2. Elisa bere lọwọ
Obinrin ọlọla Sunemu
Ohun to nfẹ k’oun se
F’oun fun gbogbo ‘tọju rẹ
Ègbè
3. ‘Gbọn obinrin na sọ pe
Ki woli ma se yọnu
‘Gbọon woli na mọ wipe
Oun s’alain’ ohun kan
Ègbè
4. O kọju si ‘ransẹ rẹ
O bi ‘pe ki la ba se
Fun obinrin ọlọla yi
Fun gbogbo itọju rẹ
Ègbè
5. Gehasi si dahun pe
Ohun kan ti obinrin yi
Npongbẹ fun na ni ọmọ
‘Tor’ oun at’ ọkọ rẹ darugbo
Ègbè
6. Gba t’Elisa gbọ eleyi
O ransẹ p’obinrin na
O wi fun pe Jehofa
Yo fun lọmọ lamọdun
Ègbè
7. Nigbat’ ọdun si yipo
Obinrin ọlọla yi
Sibi ọmọkunrin kan
Gẹgẹbi ọrọ Elisa
Ègbè
8. ‘Gbọn gba t’ọmọ na dagba
L’ọjọ afiyesi kan
Ori fifọ gb’ ọmọ na
To bẹ t’ọmọ na fi ku
Ègbè
9. ‘Binrin ọlọla Sunem’ yi
Tẹ ‘mọ na sori ‘busun
Eniyan Ọlọrun na
‘Gbat’ oun lọ ba n Karmeli
Ègbè
10. ‘Gbat’ o d’ọdọ Elisa
Oun dahun p’ Alafia
‘Tor’ o mọ daju wipe
Jehofa yo se ti ẹ lasepe
Ègbè
11. Ọlọrun to bẹr’ ohun rere
Nin’ aiye obinrin na
D’ ẹmi ọmọ na pada
Oun si d’alaye ọkan
Ègbè
12. Iwọ na fi gbagbọ rẹ
Sinu Jesu Oluwa
Ohun gbogbo to nse tirẹ
L’Oun yio se lasepe
Ègbè

Comments
Post a Comment