Orin Kan: Nigbagbogbo, Ẹ Ma Ranti Eleyi
(“Bẹ pẹlu ẹnyin ipẹrẹ, ẹ tẹriba fun awọn agba. Ani, gbogbo nyin, ẹ ma tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ ara nyin lo asọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọ agberaga, sugbọn o nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ”.” (1 Peteru 5:5))
Emmanuel Rotimi and His Parents
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Bibeli mimọ t’ọrun
Ọwọn isura temi
‘Wọ ti nwi bi mo ti ri
‘Wọ ti nsọ bi mo ti wa”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. Bẹ gẹ ‘yin ‘pẹrẹ at’ ọmọde
Ẹ ma tẹriba f’awọn
Obi nyin at’ oluwa yin
At’ awọn agba arin nyin
2. Bọwọ fun baba on ‘ya rẹ
Eyi lofin akọkọ
To ni ileri ninu
‘Torina b’ọwọ f’obi rẹ
3. Bo ba fẹ ko dara fun ọ
To si nfẹ ẹmi gigun
O ni lati bọwọ fun
Awọn obi to bi ọ
4. Awọn ‘leri meji yi
L’Oluwa Ọlọrun se
Pẹl’ ofin yi f’ọmọde
To ba bọwọ f’obi rẹ
5. Ohun to dara to si tọ
F’ẹnyin ọmọ n’nu Oluwa
Ni lati ma gbọ t’awọn
Obi nyin nin’ Oluwa
6. Ohun to yẹ to si dara
Ni pe ki gbogbo nyin ma
Tẹriba fun ara nyin
Kẹ fi ‘rẹlẹ ‘wọ ‘ra yin lasọ
7. Ẹ ma rant’ eyi wipe
Ọlọrun kọju ja si
Gbogb’ awọn agberaga
‘Gbọn o f’ore-ọfẹ f’onirẹlẹ
Comments
Post a Comment