Orin Kan: O Rọrun Fun Ibakasiẹ Lati Wọ Oju Abẹrẹ
(“O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ oju abẹrẹ ju fun ọlọrọ lati wọ ijọba Ọlọrun lọ” (Mar. 10:25))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara, sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi, mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“’Wọ Jesu t’a ti nreti
Lati gba wa lọw’ ẹsẹ
‘Gbawo ni ‘gbala yo de
Ti ao da ide ẹsẹ”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Gba Jesu wa ni aiye
P’ẹlawọn ‘mọ-ẹhin rẹ
Ọmọkunrin kan tọ wa
Lati ber’ ohunkan lọwọ rẹ
2. ‘Gba to de ọdọ Jesu
O sọ p’ol’kọni rere
Ohun rere ki lem’ o se
Kinle niye ainipẹkun
3. Jesu si fun l’esi pe
Ẹni rere kan ko si
Bikos’ ẹnikan soso
Ẹni na si l’ Ọlọrun
4. ‘Gbọn bi ‘wọ ba fẹ niye
‘Wọ nilati p’ofin mọ
Base kọ sinu ‘we ofin
Gẹgẹ bi ‘wọ tise ka
5. ‘Gbọn ‘dọkunrin nab ere
Lọwọ Jesu ewo n’nu wọn
‘Tori on fẹ wọ bi ‘ye
‘Yeraiye lẹhin aiye yi
6. Jesu dahun pe ma jale
Ma pania, ma jẹr’ eke
‘Wọ mase se pansaga
Bọwọ fun baba on ‘ya rẹ
7. Jesu tun fi kun wipe
‘Wọ ko gbọdọ rẹ ni jẹ
Fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ
B’ara rẹ f’aladugbo rẹ
8. ‘Gbọn o da Jesu lohun pe
Gbogb’ eyi loun tin se
Lati ‘gba t’oun ti wa lewe
Kinni oun to k’oun ku
9. Jesu wò ó nifẹ rẹ
O wi pe b’oun ba fẹ pe
Ko lọ ta gbogb’ ohun to ni
Ko fi tọrẹ fun talaka
10. Bi iwọ ba se eleyi
‘Wọ yon i ‘sura l’ọrun
Si wa gb’ agbelebu rẹ
Ko si ma tọ mi lẹhin
11. ‘Gbọn ‘gbat’ ọdọkunrin na gbọ
Idahun ti Jesu fun
O jade lọ nibanujẹ
‘Tor’ oun lọrọ pupọ
12. ‘Gba to lọ tan Jesu sọ
F’awọn ‘mọ-ẹhin rẹ pe yo ti
Soro to fun awọn to
gbẹkẹl’ ọrọ lat’ wọ ‘jọb’ ọrun
13. O rọrun fun ‘bakasiẹ
Lati w’oju abẹrẹ
Ju fun awọn ọlọrọ
Lati wọ ‘jọba ọrun
14. Eyi y’awọn ‘mọ-ẹhin lẹnu
Gidigan ‘tor’na wọn wipe
Njẹ ta ha ni o le la
Ninu aiye ta wa yi?
15. Jesu si dahun wipe
Enia leyi soro fun
‘Gbọn kise fun Ọlọrun
Ohun gbogbo ni sise f’ Ọlọrun
16. Lati wọ ‘le ologo
To sura rẹ jọ sọrun
Gb’ agbelebu rẹ si ma
Tọ Jesu ‘lugbala lẹhin
Comments
Post a Comment