Orin Kan: Ó Sì Bá Wọn Se Ìpinnu
(“Ìjọba ọrun sa dabi ọkọnrin kan ti ise bale ile, ti o jade ni kutukutu owurọ lati pe awọn alagbase sinu ọgba ajara rẹ” (Matt. 20:1))
Ọrọ Àsọsíwájú Lati Ọwọ Onkọrin yi:
Ngo mọ àwọn àmìn orin ti inu iwe daradara,
sugbọn pẹlu awọn orin ti a ma nkọ nigbati mo wa lakọrin ati ninu ijọ gan bayi,
mo ko orin titun yi jade. Bi o ba ti mọ orin to mbẹ nisale yi, ajẹ wipe o ti
dara niyẹn darapọ mọ mi ki a jijọ kọ orin yi si Oluwa.
Ohùn Orin Inú Ìwe to yẹ ki a mọ Niyi
“Sa gbẹkẹle l’ọjọjọ
Gbẹkẹle l’arin ‘danwo
Bi ‘gbagbọ tilẹ kere
Gbẹkẹle Jesu nikan
Ègbè
Gbẹkẹle ni ‘gbagbogbo
Gbẹkẹle lojojumọ,
Gbẹkẹle lọnakọna
Gbẹkẹle Jesu nikan”
Ẹniti o Kọrin Yi:
Orin Titun na Nìyí
1. ‘Jọba ọrun sa dabi
Ọkunrin bale ‘le kan
To jade l’owurọ kutu
Lọ pe awọn
alagbase
Ègbè
‘Tor’ọpọ enia la pe
Sugbọn di ẹ la o ri yan
Lar’ awọn enia di ẹ na
Jesu jẹ ki njẹ ọkan
2. ‘Gbato de arin ọja
O ri awọn alagbase
T’ wọn duro nsọri-sọri
‘Wọn nret’ ẹni t’ yo pe wọn
Ègbè
3. O pe awọn alakọkọ
O si bawọn se ‘pinnu
Iye owo t’ yo fun wọn
‘Gba wọn ba pari ‘sẹ lalẹ
Ègbè
4. ‘Gba to ri pe ‘sẹ si pọ
Lati se nin’ ọgba ‘jara rẹ
To si nfẹ ki isẹ na
Le pari ni ọjọ na
Ègbè
5. Niwọn wakati kẹta
Lẹhin eyi o tun jade
O tun ri awọn miran
Ti wọn ko ri isẹ se
Ègbè
6. O p’awọn alagbase yi
O sọ fun wọn ki wọn lọ
Si n’ọgba ajara rẹ
Lati lọ se ‘sẹ nibẹ
Ègbè
7. Bẹ pẹlu ni ounse
‘Gbat’ o di wakat’ ‘kẹfa
Ikẹsan ati ‘kọkanla
O p’awọn ‘lagbase titun
Ègbè
8. Nigbat’ o d’oju alẹ
Oluwa ọgba ajara
P’awọn alagbase wọnni
O f’owo isẹ wọn fun wọn
Ègbè
9. ‘Gbat’ o ba d’opin ọjọ
‘Gbati a ba pe wa jọ
Lati gbere isẹ wa
Oluwa jọ kami yẹ
Comments
Post a Comment